Oluwo: Àwọn ìjòyè àti aráàlú ọba tí Oluwo gbá l'étí ṣèwọ́de

Ami idanimọ ijọba Osun ati Oluwo

Oríṣun àwòrán, Osun Govt/Oluwo

Ijọba ipinlẹ Oṣun ti dasi ọrọ ija to waye laarin Oluwo ti Iwo, Ọba Abduraheed Adewale Akanbi, ati Agbowu tilu Ọgbaagbaa, Ọba Dikrullai Olaleke Akinropo lopin l'ọsẹ to kọja.

Komisana fun eto iroyin nipinlẹ Osun, Arabinrin Funke Egbemode sọ fun BBC Yoruba pe "gomina ti fi aṣẹ fun igbimọ lọba-lọba lati yanju ọrọ naa nilana aṣa."

Egbemode sọ pe "nkan ti ko ṣe e gbọ l'eti ni pe ọba meji woju ara wọn nibiti awọn eniayn miran wa."

"Gomina ti da si, a si ti ba awọn to yẹ sọrọ, to fi mọ awọn to fi ẹhonu wa si ọọfisi gomina. A ko si ni i jẹ ki iru iṣẹlẹ naa o waye mọ."

Lori ẹsun ti Oluwo fi kan awọn ọba mẹjọ ti ọrọ tun kan pe wọn n ta ilẹ ilu wọn lọna ti ko tọ ọ, Egbemode sọ pe gbogbo ẹhonu Oluwo, ati tawọn ọba yooku ni ijọba yoo gbọ.

Àkọlé fídíò, Kò sí ǹkan tó ń jẹ́ ọ̀rọ̀ ìgbàgbọ́ tàbí ìmọ̀le nínú àgbékalẹ̀ Amotekun - Alake ti Egba

Ṣugbọn ṣa, lori bi awọn kan ṣe n fẹ ki ijọba o sọ pe ki Ọba Abdulrasheed Akanbi o kuro lori oye fun igba diẹ, Arabinrin Egbemode sọ pe ijọba ko ni i sọ nkan ti yoo ṣe, ki wahala miran ma ba a tun bẹrẹ.

Awọn Oloye ati diẹ lara awọn olugbe ilu Ọgbaagba ṣe iwọde lati fi ẹhonu wọn han lori bi Oluwo ti Iwo, Ọba Abduraheed Akanbi ṣe gba ọba ilu wọn, Agbowu tilu Ọgbaagbaa, Ọba Dikrullai Olaleke Akinropo, Ọlabiran Kẹta l'eti nita gbangba.

Owurọ ọjọ Aje ni awọn ara ilu ati ijoye lati ijoba ibile Iwo, Ayedire, Ola oluwa se iwọde lọ si ọdọ gomina ati agbẹnusọ ile igbimọ aṣofin.

Àkọlé fídíò, '500 level'' ni mo wà nígbà tí mo di adélé Ọba'

Awọn olufẹhonuhan naa gbe oriṣiriṣi akọle dani, ninu iwọde naa to waye nilu Oṣogbo ti wọn si n ke si ijọba lati sọ pe ki Oluwo lọ rọọkun nile na.

Opin ọsẹ to kọja ni a gbe iroyin jade pe ija waye laarin Oluwo ati Ọba ilu Ọgbaagba lasiko ti wọn n ṣe ipade alaafia pẹlu igbakeji ọga agba ọlọpaa nilu Osogbo lori ọrọ to ni ṣe pẹlu ilẹ.

Oluwo fi ẹsun kan awọn ọba mẹjọ kan to wa labẹ rẹ pe wọn n ta ilẹ ilu wọn lọna aitọ.

Lasiko to n ṣalaye ohun to bi ija agba meji to waye lọjọ Ẹti laarin rẹ ati Agbowu tilu Ọgbaagbaa, Ọba Dikrullai Olaleke Akinropo, Ọlabiran Kẹta, Oluwo sọ pe lootọ ni ọga ọlọpa pe awọn si ipade alaafia, amọ se ni Agbowu n da ọrọ mọ oun lẹnu, to si n pe oun ni orukọ buruku, ti ko se gbọ seti.

Awọn olufẹhonu han

Oríṣun àwòrán, Ayobami agboola

Oluwo salaye loju opo Instagram rẹ pe se ni Agbowu na ọpa asẹ rẹ si oun, to si fẹ kii bọ oun loju, ti oun si fi tipa kọ igbesẹ naa, eyi ti ara Agbowu ko gba rara.

Awọn olufẹhonu han

Oríṣun àwòrán, Ayobami agboola