Aláàfin ìlú Oyo ti bímọ okùnrin tuntun lẹ́ni odún 81

Oríṣun àwòrán, Alimat Bamgbopa
Alaafin ilu Oyo, Ọba Lamidi Olayiwola Adeyemi kẹta ti bi ọmọ okunrin tuntun.
Ọmọ tuntun ọhun ni iyawo kabiesi to kere ju, Olori Damilola Adeyemi bi fun un.
Ninu ọrọ ti Olori naa fi soju opo Instagram rẹ lo ti ki ara rẹ ku oriire, to si kọ akọle kan sibẹ pe "Mo ki ara mi ku ori ire, ọmọ ọba ti de."
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
Ọkan lara awọn ọmọ Alaafin, Bunmi Labiyi fi idi ọrọ naa mulẹ fun BBC Yoruba ni aarọ yii ninu ifọrọwerọ kan.
O sọ pe ounjẹ gidi ti Alaafin n jẹ ati awọn ere idaraya to ma n ṣe ṣeeṣe ko jẹ ohun to ṣi n fun baba ni okun bi ọdọmọde.
Bunmi ni "Baba mi ki n ṣaye bi awọn eeyan mii ṣe ma n ṣe aye wọn. Kii jẹ ijẹkujẹ."

Oríṣun àwòrán, Alimat Bamgbopa
Bunmi tẹ siwaju pe Alaafin mọ irufẹ ounjẹ to yẹ ko jẹ ati iru ounjẹ ti ko yẹ ko jẹ, koda o ni Kabiesi kii mu ẹlẹrindodo "Coca Cola."
Bakan naa, o fi hande pe onimọ nipa ounjẹ jijẹ ni Kabiesi to si maa n kilọ fun awọn eeyan nipa iru awọn akanpọ ounjẹ ti wọn n jẹ.
Ọmọ Ọba ṣalaye pe "Baba mi jẹ ẹni to mọ nipa ounjẹ gidi. Kii sọ pe nitori o jẹ Ọba Alaye ko wa maa jẹ ijẹkujẹ ki wọn eeyan le ri pe Alaafin lo n jẹun. Boya idi niyẹn ti Baba ṣi fi ni okun."
O pari ọrọ rẹ pe Kabiesi fẹran ere idaraya to bẹ to fi jẹ pe o loju ọdọmọde to lee figa gbaga pẹlu Alaafin ti wọn ba bẹrẹ si n rin papọ.













