Seyi Makinde: Ìjọba Oyo kò fi ti NURTW ṣe, wọ́n ṣe ìfilọ́lẹ̀ olùdarí ìbùdókọ́ tuntun

Oríṣun àwòrán, Tribune
Adari ẹgbẹ awakọ ero NURTW ipinlẹ Oyo ti ijọba ti fofin de, Alhaji Abideen Olajide ti fesi si ifilọlẹ awọn adari ibudoko lati ọwọ ijọba ipinlẹ Oyo.
Abideen ti ọpọ eeyan mọ si Ejiogbe sọ fun ileeṣẹ BBC Yoruba ninu ifọrọwerọ pe ohun ko ni nkankan sọ nipa igbesẹ yi yatọ si eleyi ti awọn agba ẹgbẹ NURTW ni Abuja ba sọ.
Ni ọjọ Aje ni ijọba ipinlẹ Oyo ṣe ifilọlẹ awọn adari ibudo iwọkọ ti yoo ma ṣe akoso gbigba owo si apo ijọba lawọn ibudoko kaakiri ipinlẹ naa. Fun idi eyi, ọwọ ijọba ipinlẹ Oyo ni owo ti wọn ba gba yoo maa lọ bayii.
Ṣaaju ifilọlẹ yi, Ejiogbe ati awọn ọmọ gbẹ rẹ kan ti fohun silẹ ninu fọnran fidio kan pe awọn yoo da wahala silẹ ti ijọba ba tẹsiwaju pẹlu igbesẹ yi lọjọ Aje.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Alhaji Mukaila Lamidi ti awọn eeyan mọ si Auxilliary naa da si ọrọ yi ninu fidio ti ẹ na totini kawọn eeyan sowọ pọ pẹlu ijọba.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Ninu atẹjade tawọn naa fi sita ni idahun si fidio yi, ileeṣẹ ọlọpaa ni Oyo fi ikilọ sita pe ki awọn ọmọ ẹgbẹ naa ti ọwọ ọmọ wọn baṣọ ti wọn ko ba fẹ jẹ iyan wọn niṣu.
Ẹwẹ ifilọlọlẹ awọn adari tuntun yi ti waye gẹgẹ bi ohun ta ri ka ninu iwe iroyin Tribune to fi Ibadan ṣe ibujoko.
Gẹgẹ bi wọn ṣe sọ,Kọmisana fun ohun amayederun ati irinna ni Oyo, Raphael Afonja lo ṣe ifilọlẹ yi.
Yatọ si awọn adari ti wọn yan ati igbakeji wọn fun ibudokọ kọọkan, ijọba tun fi alaga ẹgbẹ awakọ ero tẹlẹ ri ni Ibadan Alahaji Lamidi Mukaila Auxiliary jẹ alaga igbimọ ti yoo ma ṣe akoso awọn adari wọn yi.













