Alága NURTW gba ìdájọ́ ikú 'torí ẹ̀sùn pípa ọlọ́pàá

Oríṣun àwòrán, @LagosCReporters
Ile ẹjọ giga kan ni Ikeja, ipinlẹ Eko ti dajọ iku nipa yiyẹgi fun Saheed Arogundade to jẹ alaga ẹgbẹ awọn awakọ ibudo Boudary/Aiyetoro nipinl Eko.
Idajọ iku yii da lori ẹsun ti wọn fi kan an pe o pa ọlọpaa ẹni ọdun mejilelọgbọn, Gbenga Oladipupọ.
Nibi idajọ naa, adajọ fi ẹsẹ rẹ mulẹ pe olupẹjọ fi han gedegbe pe tayọ ṣiṣe iye meji pe Arogundade ṣekupa ọlọpaa naa.
Ki adajọ to da jọ rẹ nitori aabo ati lati ma gba idiwọ kankan laye, o kọkọ paṣẹ pe ki wọn ti gbogbo ilẹkun ile ẹjọ pa ki wọn si ko kọkọrọ fun un.
Lẹyin naa ni adajọ kede wi pe olujẹjọ, Saheed arogundade jẹbi ẹsun gbigbimọ ipaniyan ati ipaniyan. Nitori naa, ile ẹjọ da ẹjọ iku fun un pe ki wọn fun okun mọ ọ lọrun ki wọn si yẹgi fun un titi ẹmi yoo fi kuro lara rẹ.
Adajọ Akinlade kasẹ rẹ nilẹ pẹlu sisọ pe "ki ọlọrun ṣaanu fun ẹmi rẹ".
Bi Arogundade ṣe gbọ idajọ rẹ ni o ṣubu wọọ ninu koto ijẹjọ ti ariwo ẹkun si sọ lati ẹnu awọn mọlẹbi rẹ ninu ile ẹjọ.
Gẹgẹ bi alaye agbẹjọro fun olujẹjọ ori ọkada alupupu ni oloogbe wa ti awọn mẹrin kan ti ke e lọna, bi awọn mta ṣe di i mọlẹ ni olujẹjọ, Arogundade gun un lọbẹ lọpọlọpọ igba.
Ni ile iwosan ti wọn sare gbe e lọ lo ti gbẹmi mi.
Iroyin ti a gbọ fihan pe idi ti wọn fi pa Oladipupo ni wi pe o fi aaye gba awọn onikẹkẹ alupupu ni agbegbe Aiyetoro eyi to si n mu ifasyin ba owo to n wọle fun ẹgbẹ NURTW to wa nibẹ.
Ile iṣẹ iroyin NAN sọ pe eniyan mẹjọ lo ṣe ẹlẹri pe olujẹjọ lọwọ si ẹsun naa. Lara wọn ni onikẹkẹ alupupu to gbe e, Ismaila Lukman ati iya oloogbe, arabinrin Mojisọla Martins. Ọjọgbọn John Fafunwa to jẹ oludari agba ile iwosan ipinlẹ Eko. Olawale Akinola, ẹni to ṣe oju rẹ koro to fi mọ awọn ọlọpaa mẹrin.
Ni ti awọn mẹta to ku, ida lare ni wọn ri gba nitori adajọ ni ko si aridaju to fi han pe ọdaran niwọn tabi pe wọn wa nibi iṣẹlẹ














