Kókó ìpàdé Nuhu Ribadu pẹ̀lú aṣòfin Amẹrika tó ní àwọ́n alákatakítí ẹ̀sìn ń ṣekúpa Kristẹ́nì ní Naijiria

Nuhu Ribadu wọ aṣọ olomi aro pẹlu file, nigba ti Sẹnẹtọ Riley Moore wọ kootu dudu ati ẹwu funfun

Oríṣun àwòrán, Nuhu Ribadu/X/Rep. Riley Moore/X

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Aṣofin orilẹede Amerika to sọ pe iṣekupani awọn kristẹni n ṣẹlẹ ni Naijiria, Sẹnẹtọ Riley Moore, ti ṣepade pọ pẹlu awọn aṣoju orilẹede Naijiria ti oludamọran Aarẹ lori ọrọ aabo, Nuhu Ribadu ko wọn sodi.

Aṣofin Moore fidi rẹ mulẹ pe oun ṣe ifọrọwerọ pẹlu Ribadu gẹgẹ bii aṣoju Aarẹ Bola Tinubu niluu Washington D.C. l'Amẹrika.

Ọgbẹni Moore sọ pe ipade oun pẹlu Ribadu da lori iṣekupani awọn kristẹni ati ọṣẹ tawọn agbesunmọmi n ṣe ni Naijiria.

Moore ni oun ti sọrọ pẹlu Ribadu lori ọna lati fopin si iṣekupani awọn alaiṣẹ to n waye loorekoore ni Naijiria.

Aṣofin naa sọ pe awọn aṣoju ijọba orilẹede Naijiria sọ nipa awọn nnkan to n kọ ijọba Naijiria lominu lori ọrọ awọn agbesunmọmi ati bi Amẹrika ṣe le ṣeranwọn lati daabo bawọn awujọ tawọn agbesunmọmi yii n ṣekọlu si ni Naijiria.

Moore ṣalaye pe Amẹrika ṣetan lati fọwọ sowọ pọ pẹlu Naijiria, o ni oun sọ fun awọn aṣoju ijọba Naijiria wi pe Amẹrika ko ni gba ki wọn maa ṣeku pa awọn kristẹni lọ ni Naijiria.

Ọrọ ti Moore sọ yii wa ni ibamu pẹlu nnkan ti Aarẹ Donald Trump naa ti sọ tẹlẹ nipa Naijiria.

O ni oun yoo maa tẹsiwaju lati maa wo nnkan to n ṣẹlẹ ni Naijiria, oun yoo si ri pe Naijiria ṣe ohun to yẹ lati fopin si awọn agbesinmọmi to n ṣe ikọlu sawọn eeyan ni Naijiria.

Lati oṣu Kẹsan an ọdun yii ni ọkan-o-jọkan awọn oloṣelu ti n sọ pe awọn alakatakiti ẹsin islam n ṣekọlu sawọn kristẹni ni Naijiria.

Ọrọ yii jade ninu iṣẹ iwadii Mike Arnold, oniroyin CNN, Van Jomes, Sẹnẹtọ Moore, Sẹnẹtọ Ted Cruz atawọn olorin ẹsin mii naa ti n sọrọ yii bakan naa.

Sẹnẹtọ Cruz to n ṣoju ipinlẹ Texas ti ṣagbatẹru aba kan loṣu Kẹsan an eyi to pe ni ''ába lati ṣe ẹsin to wu eeyan ni Naijiria ti ọdun 2025.''

Aba yii ni o fi fẹsun kan ijọba Naijiria pe wọn n faye awọn alakatakiti ẹsin islam lati maa ṣekọlu sawọn kristẹni.

Sẹnẹtọ Moore naa ti sọ tẹlẹ pe wọn n ṣekupa awọn kristẹni nitori wọn n ṣe

esin to wu wọn.

Moore si kọwe si akọwe ijọba awọn ipinlẹ l'Amẹrika, Marco Rubio, wi pe ko gbe igbesẹ lori ọrọ naa kiakia.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post