Ilé ẹjọ́ sọ Nnamdi Kanu sí ẹ̀wọ̀n gbére

Nanmdi Kanu ati agbejọro rẹ nile ẹjọ
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ile ẹjọ giga ilu Abuja ti sọ olori ẹgbẹ ajijagbara fun ominira ilẹ Biafra, Nnamdi Kanu si ẹwọn gbere.

Idajọ yii lo n waye lẹyin ọdun mẹwaa ti wọn kọkọ fi ṣikun ofin mu u.

Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, adajọ Omotoso sọ pe Kanu ko kabamọ ohun to ṣe ni gbogbo asiko ti igbẹjọ rẹ n lọ lọwọ bẹẹni ko tuuba.

O ni Kanu ṣe oniruru igbohunsafẹfẹ lawọn ọdun kan sẹyin lasiko to n pe fun ominira ilẹ Biafra, ati pe awọn igbohunsafẹfẹ ọhun lo ṣokunfa oniruru ifẹmiṣofo to waye ni ila oorun Naijiria nibi ti ọpọ agbofinro ti sọ ẹmi wọn nu.

Idajọ yii lo waye lẹyin ti ile ẹjọ naa ni Kanu jẹbi ẹgbogbo ẹsun meje ti wọn fi kan an, eyii to ni ṣe pẹlu igbesunmọmi.

Ọdun 2009 ni irawọ Kanu kọkọ tan kalẹ ni Naijiria lẹyin to bẹrẹ igbohunsafẹfẹ lori ẹrọ aṣọrọmagbesi Radio Biafra.

Ori redio naa lo ti n pe fun ominira ilẹ Biafra lati ilu London pe ki ẹya Igbo yapa kuro lara Naijiria.

Ilé ẹjọ́ ní Nnamdi Kanu jẹ̀bi ẹ̀sùn ìgbésùnmọ̀mí oníkókó méje tí wọ́n fi kàn án

Nnamdi Kanu wọ aṣọ funfun nile ẹjọ pẹlu awọn alabaṣiṣẹpọ rẹ

Adajọ James Omotosho ti ile ẹjọ giga apapọ ilu Abuja ti fidi rẹ mulẹ pe olori ẹgbẹ IPOB to n jija gbara fun orilẹede Biafra, Nnamdi Kanu, jẹbi ẹsun igbesunmọmi onikoko meje ti wọn fi kan an.

Adajọ Omotosho ni Kanu ti hu oriṣiiriṣii iwa ipa eyi to ti ṣakoba fawọn eeyan rẹ to loun n ja fun un.

Lasiko to n ka idajọ naa ni adajọ sọ pe ki olori ẹgbẹ IPOB jade nile ẹjọ bi o ṣe n ka idajọ rẹ.

Oni ogunjọ oṣu Kọkanla ọdun 2025 yii ni Adajọ Omotosho fi idajọ Kanu si eyi to le jasi idajọ iku gẹgẹ bi iwe ofin Naijiria ṣe sọ.

Adajọ Omotosho bẹrẹ sii jokoo lori igbẹjọ Kanu lati oṣu Kẹta ọdun yii, lẹyin ti Kanu fẹsun kan Adajọ Binta Nyako to n ṣakoso igbẹjọ naa tẹlẹ pe o n figba kan bọkan ninu.

Lati igba naa ni Adajọ Ọmọtosho ko ti fi igbẹjọ naa falẹ rara titi ti oni ọjọ idajọ.

Bi ọrọ ṣe bẹyin yọ nibi igbẹjọ Nnamdi Kanu l'Abuja

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Nigba ti ile ẹjọ beere lọwọ Kanu pe ki lo ni lati sọ ni olori IPOB sọ pe ki lo de ti wọn fi ju oun satimọle lai ṣẹ.

Kanu sọ pe ki wọn fun oun ni beeli.

''Nnkan ti mo n beere ni pe ki wọn jẹ ki n gbe ẹjọ yii lọ si ile ẹjọ kotẹmilọrun.

Bawo ni mo ṣe maa wa lahamọ lori ofin ti ko si ninu ofin Naijiria?

Mo fẹ ki wọn fun mi ni beeli,'' Kanu lo sọ bẹẹ.

Amọ, adajọ fesi wi pe ko tọna lati gbe ẹjọ naa lọ si ile ẹjọ kotẹmilọprun lọwọ yii.

Nigba ti adajọ fẹ bẹrẹ sii maa ka idajọ rẹ ni Kanu sọ fun adajọ pe ko fi han ninu ofin nibi ti oun ti ṣẹ.

Bi adajọ ti fẹ sọrọ ni Kanu pariwo mọ ọn pe ko fi ofin to fẹ lo fun idajọ rẹ han oun.

Nigba ti Kanu ko jẹ ji adajọ sọrọ ni adajọ paṣẹ wi pe ko jade kuro ninu ile ẹjọ.

Kanu ko dakẹ ariwo, bo tilẹ jẹ pe adajọ ti paṣẹ pe ko jade kuro nile ẹjọ.

Bakan naa ni ko tun jẹ kawọn ẹṣọ alaabo fọwọ kan an.

Adajọ ni Kanu lẹtọọ lati pe ẹjọ kotẹmilọrun lẹyin idajọ oun, amọ, Kanu si n sọrọ lọ.

O ni adajọ ko mọ ofin, ati pe ofuutu-fẹẹtẹ ni idajọ ti ile ẹjọ fẹ gbe kalẹ.

Adajọ Omotosho fidi rẹ mulẹ pe o wa ninu ofin wi pe bi afurasi ko ba huwa bii Omoluabi, adajọ lagbara lati le e jade ti yoo fi ka idajọ rẹ.

Ìdájọ́ olórí ẹgbẹ́ IPOB Nnamdi Kanu ti bẹ̀rẹ̀ nílé ẹjọ́

Nnamdi Kanu wọ aṣo funfun nile ẹjọ pẹlu iwe lọwọ rẹ

Ile ẹjọ ti bẹrẹ idajọ olori ẹgbẹ ajijagbara fun orilẹede Biafra, Nnamdi Kanu, niluu Abuja.

Ile ẹjọ ti sun idajọ naa siwaju fun igba meloo kan ṣaaju ọjọ oni.

Ẹsun wo ni wọn fi kan Nnamdi Kanu?

Ẹsun meje ọtọọtọ ni Kanu n kawọ pọnyin rojọ rẹ niwaju ile ẹjọ giga ilu Abuja bayii.

Awọn ẹsun naa da lori igbesunmọmi ati wiwa ninu ẹgbẹ agbesunmọmi.

Ọdun 2015 ni awọn agbofinro Naijiria kọkọ fi ṣikun ofin mu Kanu, ọdun naa si ni igbẹjọ rẹ bẹrẹ.

Nigba ti yoo di ọdun2017, ile ẹjọ fun un ni beeli nitori ilera rẹ ṣugbọn o na papa bora lẹyin ti awọn ọmọ ogun ya bo ile rẹ niluu Umuahia, ipinlẹ Abia.

Lọdun 2021, wọn tun fi ṣikun ofin mu un lorilẹede Kenya ti wọn si gbe e wa si Naijiria pẹlu ṣẹkẹṣẹkẹ lati wa tẹsiwaju igbẹjọ rẹ.

Lati ọdun naa ni Kanu ti tẹsiwaju igbẹjọ rẹ.