Mo bá àwọn tí ọ̀rọ̀ kàn kẹ́dùn, Kwara ló so gúúsù mọ́ àríwá- Saraki

Oríṣun àwòrán, @Others
Bẹrẹ lati ibi iroyin iku Ọgagun Musa Uba, olori ogun ti awọn agbebọn pa laipẹ yii ni Borno, debi awọn akẹkọọbinrin mẹẹẹdọgbọn ti wọn ji gbe ni Kebbi ati ipaniyan to tun ṣẹṣẹ ṣẹlẹ ni ṣọọṣi CAC ni Kwara, awọn ọmọ Naijiria ti n sọ ẹdun ọkan wọn lori bi eto aabo ṣe n buru si i lorilẹede yii.
Bakan naa ni wọn n fi ẹdun ọkan wọn han lorii bi nnkan ṣe n bajẹ lọ labẹ iṣakoso Aarẹ Bola Tinubu, ti ko si jọ pe igbesẹ akin kankan n waye nipa rẹ.
Lara awọn eekan ọmọ Naijiria to ti fi ẹdun ọkan wọn han nipa bi awọn agbebọn ṣe pa eeyan mẹta ni ṣọọṣi Eruku, ipinlẹ Kwara, ni olori ile igbimọ aṣofin nigba kan, Bukola Saraki, Folarin Falana (Falz to jẹ ọmọ Amofin agba Femi Falana), Debo Adedayo (Mr Macaroni) ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Eyi ni diẹ lara ero awọn eeyan to ti sọrọ nipa ohun to n ṣẹlẹ
Bukola Saraki: Kwara ló so àwọn ilù míràn mọ́ ara wọn ní Naijiria
"Mo gbọ iroyin ibanujẹ to sọ nipa awọn agbesunmọmi to kọlu ilu Eruku, niluu abinibi mi ti i ṣe ipinlẹ Kwara.
"Wọn ṣe awọn eeyan kan leṣe, wọn si ji awọn mi-in lọ. Iroyin ibanujẹ to ti da omi alaafia ilu ru ni.
Mo ba awọn tọrọ naa kan kẹdun, mo si pe ijọba apapọ lati tubọ so okun aabo le ni Eruku ati gbogbo Kwara, kawọn ti wọn ji gbe le pada sọdọ awọn eeyan wọn.
Ilu to so ọpọ ilu mọra wọn ni Kwara, ilu to so apa Guusu mọ Ariwa ni.
"K'Ọlọrun jẹ ki alaafia wa niluu wa, ko si ran wa lọwọ lati ṣẹgun awọn to n gbogun ti Naijiria"
Kí Tinubu kọ̀wé fipò sílẹ̀- Falz
Ninu ọrọ tirẹ, Folarin Falana tawọn eeyan mọ si Falz, sọ pe ohun to yẹ fun Aarẹ Bola Tinubu bayii ni lati kọwe fi ipo to wa naa silẹ.
Falz to jẹ olorin sufee- taka ati ajafẹtọọ ọmọniyan, sọ eyi si oju opo X rẹ l'Ọjọru.
Ọ ni Aarẹ Tinubu ti fi ojuṣe rẹ akọkọ silẹ lai ṣe, eyi ti i ṣe riri si aabo ẹmi ati dukia awọn to n ṣelu le lori.
Falz beere awọn ibeere to da oju rẹ kọ Tinubu, o ni:
"Eeyan meloo ni wọn gbọdọ ji gbe ki wọn tun pa wọn nipa oro? Ẹmi meloo lo ku ti o tun fẹẹ fi ṣofo, iran ọjọ iwaju meloo lo tun fẹẹ parẹ nitori aikunju oṣuwọn ati ai gbe igbesẹ rẹ?
"Gbogbo igba ni o n jẹ ko ye wa pe ko wu ọ lati da aabo bo ẹmi ati dukia awọn eeyan, pẹlu bi o ṣe maa n ṣe bii pe ọrọ wa kan ọ tẹlẹ. KỌWE FIPO SILẸ BAYII!"
Debo Adedayo (Mr Macaroni)
Ajafẹtọọ ọmọniyan to tun jẹ oṣere tiata ni Debo Adedayo, Mr Macaroni ni awọn eeyan mọ ọdọkunrin naa si.
Ero Macaroni ko yatọ si fi Falz, oun naa pe fun ikọwe fiṣẹ silẹ Aarẹ Tinubu ni.
Ọmọkunrin yii sọ loju opo X rẹ, pe wọn pa olori ogun, wọn ji akẹkọọ rẹpẹtẹ ko lọ, wọn tun digun ja ṣọọṣi, sibẹ, bii pe ko si iṣoro ni loju Aarẹ.
Mr Macaroni ni ki Tinubu kuku fipo aarẹ silẹ, gẹgẹ bi Aarẹ funra rẹ ṣe ni ki Jonathan fipo silẹ lasiko ti awọn agbebọn n ṣọṣẹ nigba ijọba rẹ.
Iyabo Ojo
Gbajugbaja oṣere tiata nni, Iyabo Ojo naa wa lara awọn eeyan to ti fi ẹdun ọkan wọn han lori ipaniyan ati ijinigbe to waye ni Kwara.
"O to gẹẹ! A n pe fun igbesẹ kia lori ikọlu, ijinigbe ati igbesunmọmi to n ṣẹlẹ ni Naijiria.
"Ikọlu to ṣẹlẹ ni CAC Eruku, ipinlẹ Kwara, ati ijinigbe to ṣẹlẹ ni Kebbi n ran wa leti iṣẹlẹ ibanujẹ ti wọn fi ji awọn ọmọbinrin Chibok gbe. O yẹ ka tete moju to o fun ayipada"
Funke Akindele
Bakan naa ni Funke Akindele ti oun naa jẹ oṣere tiata to si tun du ipo Igbakeji gomina ninu ẹgbẹ oṣelu PDP ni 2023, da si ọrọ yii.
Funke tawon eeyan tun mọ si Jennifer, kọ ọ soju opo ayelujara tirẹ pe:
"Bi mo ṣe ji ni mo ri fidio awọn eeyan ti wọn n ṣe ikọlu si ninu ṣọọṣi ni Kwara. Eyi ba ni lọkan jẹ. Mo sunkun nigba ti mo ri iya agba ti ko le rin daadaa to n sare ko le ri aabo.''
David Adeleke (Davido)
Olorin sufee-taka to gbajumọ nni, David Adeleke (Davido) fi ero ọkan rẹ soju opo ayelujara pẹlu ọrọ yii:
"Ọkan mi lọ sọdọ awọn ọdọbinrin ti wọn ji gbe ni Kebbi ati awọn ẹbi wọn, ko si idile to yẹ ki iru inira yii kan.
"Bakan naa ni inu mi bajẹ pupọ fun ikọlu ibanujẹ to waye ni ṣọọṣi Kwara. Mo gbadura fun awọn idile to padanu eeyan wọn ati gbogbo ẹni ti iṣẹlẹ yii kan. Iwa ipanle ko yẹ ko di aṣa wa"
Pasito Matthew Ashimolowo
Ni ti Pasitọ Matthew Ashimolowo ti ijọ KICC, ninu fidio kan to fi lede, o yanna-na awọn iṣẹlẹ ipaniyan to ti ṣẹlẹ si awọn Kristẹni lorilẹede yii.
Ashimolowo ni oun ko ni i sọ pe ipanirun (genocide) lo n ṣẹlẹ ni Naijiria, ṣugbọn gbogbo awọn Kristẹni ti wọn ti pa nitori pe wọn jẹ Kristẹni, awọn ti wọn ti pa nitori pe wọn jinhinrere ati bẹẹ bẹẹ lọ, to fun olóye lati mọ ohun to n ṣẹlẹ boya ipanirun ni tabi bẹẹ kọ.
Ero araalu Naijiria lori awọn rogbodiyan yii ko ti i duro,bẹẹ ni afikun iroyin yii n tẹsiwaju pẹlu, a o maa fi kun un bo ba ṣe n lọ.














