Ọkọ̀ àwọn tó lọ ṣe Umrah ní Saudi Arabia laná, èèyàn 46 jáde láyé

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọmọ orilẹede India marundinlaadọta ti wọn jẹ olujọsin ni wọn ti jade laye bayii lẹyin ti ọkọ bọọsi ti wọn wa ninu rẹ lana niluu Medina, lorilẹede Saudi Arabia.
Kọmiṣọna ọlọpaa ilu Hyderabad, VC Sajjanar sọ fun awọn akọroyin pe eeyan eeyan mẹrindinlaadọta lo wa ninu ọkọ naa amọ ẹnikan pere lo moribọ, ẹni naa si ti wa nile iwosan bayii fun itọju pajawiri.
Pupọ ninu awọn to ba iṣẹlẹ naa lọ lo wa lati Hyderabad to wa ni ila oorun ipinlẹ Telangana, ni India.
Ilu Mecca lawọn olujọsin naa ti n ririnajo lọ si ilu Medina ki iṣẹlẹ ọhun to waye.
Eto isin Umrah ni awọn eeyan naa lọ ṣe ni Saudi Arabia ki wọn to ṣalabapade iku ojiji ọhun.
VC Sajjanar sọ pe ọkọ agbepo bẹntiro nla kan wa lara ohun to ṣokunfa ijamba naa amọ ko mẹnuba ẹkunrẹrẹ.
Olootu ijọba orilẹede India, Narendra Modi ti ba awọn mọlẹbi awọn ti ọrọ naa kan kẹdun.
O sọ loju opo X rẹ pe iṣẹlẹ naa ba oun ninu jẹ gidi, ijọba India ati Saudi Arabia si ti n jiroro lori rẹ.
O ni "Ọọfisi wa ni Riyadh ati Jeddah ti n pese gbogbo iranlọwọ to yẹ."
Asaduddin Owaisi, to n ṣoju Hyderabad ninu igbimọ ijọba India sọ fun ileeṣẹ iroyin ANI pe oun ti ke si ijọba India ko ṣe iranlọwọ bi wọn yoo ṣe ko oku awọn eeyan naa wa sile.
Gẹgẹ bii ohun ti Sajjanar sọ, awọn mẹrinlelaadọta lo rinrinajo kuro ni Hyderabad lọ si Jeddah lọjọ kẹsan an, oṣu kọkanla, ọdun 2025 yii.
Ninu wọn, eeyan mẹrin duro ni Mecca nigba ti awọn mẹrin wọ ọkọ ayọkẹlẹ lọ si Medica, ti awọn mẹrindinlaadọta si wọ ọkọ akero bọọsi.
Mohammed Tehseen to jẹ olugbe ilu Hyderabad, sọ fun ileeṣẹ iroyin ANI pe mọlẹbi oun meje lo wa ninu bọọsi to jona ọhun.















