Mo ṣetán láti jápa tí orílẹ́èdè ilẹ̀ òkèèrè kan bá fún mi ní 'asylum' - Hauwa Lawal
Gbajugbaja sọrọsọrọ ori ayelujara, Hauwa Lawal, ti sọ pe oun ṣetan lati japa lọ soke okun ti orilẹede ilẹ okeere kan ba le fun oun ni ''asylum.''
Nigba to n sọrọ ninu ifọrọwanilẹnu kan to ṣe pẹlu BBC Yoruba, Hauwa ni loootọ loun fi n ṣere ninu fidio kan toun gbe jade wi pe kawọn eeyan boun buwọlu fọọmu ṣiṣe atipo nilẹ okeere foun.
Amọ, Hauwa sọ fun BBC Yoruba wi pe oun ti ṣetan bayii lati fi Naijiria silẹ toun ba ri anfaani tori orilẹede Naijiria ko rọrun rara fawọn ọdọ bii toun.
''Fidio asylum ti mo ṣe, mo kan fi n ṣere ni, amọ, Naijiria yii ko rọrun fun awa ọdọ.
Iṣẹ gidi wa lasiko tawọn obi mi wa ni ọdọ gẹgẹ bii temi, wọn si maa n rowo diẹdiẹ nigba naa.
Ṣugbọn nisinyin, ti o ko ba ni miliọnu kan si meji, eeyan o le gba ile ni igboro.
Naijiria ti le ju, ti wọn ba fun mi ni asylum, mo maa lọ o,'' Hawa lo sọ bẹẹ.
Hauwa ni awọn eeyan ro pe ọmọ Hausa ni mi, amọ, ọmọ Yoruba pọnbele ni mi.
Abeokuta ni ilu baba mi, eeyan ti kii fẹ lati jade si ni mi pẹlu.
Ṣugbọn nitori fidio ti mo maa n ṣe, awọn eeyan maa n ro pe mo maa n jade ni gbogbo igba.''
Hauwa ni nitori awọn eeyan n fẹran fidio toun n gbe sita lo fun oun ni igboya lati maa ṣe e lọ.
Ọdun marun mi o ṣe fi oju mi han lori ayelujara - Hauwa
Hauwa ni ''fun bi ọdọ marun mi o ṣe fi oju han rara, bo tilẹ jẹ pe emi ni mo n gbe awọn fidio naa sita.
Ọdun 2023 ni mo kọkọ fi oju ara mi han lori ayelujara, eyi lo jẹ ki ọpọ eeyan maa ro pe mo ṣẹṣẹ bẹrẹ iṣẹ yii ni.''
Hauwa ni lati igba toun ti wa ni kekere loun ti maa n kọ itan.
Sọrọsọrọ ori ayelujara naa ni kii ṣe gbogbo igba lowo fi maa n wọle pẹlu iru iṣẹ toun n ṣe.
O ni ifẹ toun ni si iṣẹ naa lo jẹ koun tẹra mọ ọn.
Hauwa ni oun ti maa n fi aṣọ bori koun to bẹrẹ si ni ṣe fidio ori ayelujara.
Ọdọbinrin naa sọ pe sikaafu toun n we ti di ara ''brand'' oun bayii.
Hauwa wa rọ awọn ọdọbinrin lati ni iṣẹ ti wọn n ṣe, ki wọn si ni owo ti wọn ki wọn le da duro.






