Àwọn àǹfààní tó wà nínú ata jíjẹ fún àgọ́ ara

Jijẹ ata jẹ nnkan to ti wa lati ọjọ pipẹ koda a ko ro pe eeyan kan wa ti wọn ko ki n jẹ ata ni ojumọ kan.
Ọpọ nnkan ni awọn eeyan maa n fi ata ṣe, koda a ma fi sinu nnkan mimu .
Koda lasiko igbele ajakalẹ arun covid-19, awọn kan ni ata jijẹ n gbe ogun ti kokoro naa.
Ṣugbọn n jẹ ata jijẹ n se saara loore , se n da bobo wa lọwọ asian, ati pe se o le se akoba fun wa?
Anfaani jijẹ ata
Ọkan ninu ata to wọ pọ ni a n pe ata bawa. Oriṣii iwadii fi han pe irufẹ ata yii ko ni ipalara kankan fun agọ ara.
Capsaicin ni eroja to wa ninu ata, eroja Capsaicin maa n mu ara ya gaga.
Awọn oluwadii ni capsaicin to wa ninu ata tun le jẹ ki ẹmi eeyan gun.
Ni ọdun 2019, iwadii kan fidi rẹ mulẹ pe eeyan to ba jẹ ata ni ẹmẹẹrin lọsẹ yoo ni ẹmi gungun ju eeyan ti ko jẹ rara lọ.
Ni ọdun 2015, awọn oluwadii ni China ṣe iwadii lori jijẹ ata , ti wọn si ri pe ọpọ eeyan to n jẹ ata ni oorekoore ni wọn ni ẹmi gungun.
Ẹwẹ, jijẹ ata pupo tun le ṣe akoba fun ilera, o si le ma daabo bo eeyan lọwọ asian.
Ọjọgbọn QI ni aisan ko ri aye de si lara eeyan to ba n jẹ ata nitori eronja Capsaicin.
"Awọn eronja to wa ninu ounjẹ to ba ni ata bii capsaicin maa n mu ayipada to dara de ba ara, eyi to ṣafihan ninu iwadii wa."
Ọpọ iwadii tun ti se afihan pe eroja capsacin yii tun maa n fun eeyan ni okun ati agbara, ti ko si ni jẹ ki ebi maa pa eeyan.
Zumin Shi, Ọjọgbọn ni fasiti Qatar ni ata jijẹ ko kii jẹ ki eeyan sanra ju, o si tun maa n dẹkun ifunpa giga.
Awọn kẹmika to wa ninu ata

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn kẹmika to wa ninu ata lo n fun ni un adun, ti ko si lewu fun awọn eeyan, Duane Mellor, olukọ ni ile ẹkọ Aston Medical ni UK ṣalaye.
"Ọpọ awọn nnkan to wa ninu ounjẹ ti a n gbadun lo wa nibẹ lati daabo bo awọn ohun ọgbin yii lọwọ awọn kokoro."
O ni fun apẹẹrẹ, awọn eroja bii polyphenois to wa ninu ọpọ ohun ọgbin lo ni ipa to n ko.
Njẹ ẹni to ba ni arun ọgbẹ-inu le maa jẹ ata?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ariyanjiyan wa lori bo ya eeyan to ba ni arun ọgbẹ inu le maa jẹ ata lai sewu.
Amọ, Dokita Solomon Nwafuru, ti ṣalaye wi pe jijẹ ata gan an maa n ṣe oogun ọgbẹ inu.
Dokita Nwafuru ni ''ti o ba jẹ ata, yoo lọ soju egbo to wa ninu ikun rẹ, yoo si bẹrẹ sii dun iru ẹni bẹẹ.
Iru ẹni bẹẹ le sọ pe ata toun jẹ n dakun ọgbẹ inu to mu oun, amọ, ko ri bẹẹ.
Idi ni pe oju ọgbẹ naa yoo bẹrẹ sii san lẹyin irora ti ata jijẹ ba mu wa ba lọ tan
Ṣugbọn ọgbẹ inu maa n buru sii kete ti ẹni to ba mu ba ti dẹkun ata jijẹ nitori irora to n mu un wa.''
Dokita Nwafuru ṣalaye wi pe nnkan meji lo maa n fa ọgbẹ inu.
Akọkọ ni awọn kokoro aifojuri eyi ti ọti amuju maa n ṣokunfa rẹ.
Dokita Nwafuru ni siga mimu, ebi, jijẹ ounjẹ inu agolo ni gbogbo igba ati lilo oogun ara riro ni gbogbo igba ni nnkan keji to maa n fa ọgbẹ inu.
O ni ata maa n pa awọn kokoro aifojuri ri to maa n fa ọgbẹ inu.
Dokita Nwaguru tun ni ata maa n pese kẹmika kan ninu ara eyi to maa n jẹ ki egbo ọgbẹ inu san.
Dokita Nwafuru ni ata jẹ ọkan lara awọn nnkan to ṣe pataki julọ ti Eledua da sori ilẹ aye.















