Kí ni kókó ohun tí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Boko Haram àti ISWAP ń jà fún tí igba èèyàn ṣe tẹ́rí gbaṣọ́?

Awọn ọmọ ogun Boko Haram ati ISWAP ti wọn asọ ologun alawọ eweko duro ni ori asalẹ kan, maa woju ara wọn. Ọkọ akẹru kan wa nibẹ ati ọkọ ijagun kan naa duro. awọn mejeeji yii ni wọn kun ni ọda idamọ ologun tii se awọ eweko

Oríṣun àwòrán, HQ Nigerian Army

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ko din ni igba eeyan to ti padanu ẹmi wọn ni iha Ariwa Naijiria lẹyin ija to waye laarin awọn ọmọ ẹgbẹ agbesunmọmi lori ala ilẹ.

Ija ọhun lo waye laarin awọn agbesunmọmi Boko Haram ati alatako wọn, Islamic State West Africa Province (ISWAP) ni agbegbe Dogon Chiku, Lake Chad, to wa ni aala orilẹede Naijiria, Niger, Chad ati Cameroon.

Agbegbe eti omi Chad yii lo jẹ agbegbe kan ti awọn ọmọ ẹgbẹ agbesunmọmi ti n ṣọṣẹ, ti wọn si maa n gba owo ori lọwọ awọn apẹja, awọn to n ko igi atawọn darandaran.

ISWAP padanu awọn ọmọ ogun to pọ julọ nigba ti Boko Haram gbẹsẹle ọpọlọpọ ọkọ oju omi ti wọn n lo nibẹ

Ija tuntun to waye laarin wọn yii lo jẹ ara eyii to maa n waye laarin wọn tẹlẹ lori ala ilẹ ati ipo agbara laarin ara wọn.

Iroyin ni ISWAP lo padanu awọn ọmọ ogun to pọ julọ nigba ti Boko Haram gbẹsẹle ọpọlọpọ ọkọ oju omi ti wọn n lo nibẹ.

Babakura Kolo, to jẹ ọkan lara awọn fijilante agbegbe ọhun sọ fun ileeṣẹ iroyin AFP pe "Nigba ti a bẹrẹ si n ka awọn to ku, nnkan bii igba awọn ọmọ ẹgbẹ agbesunmọmi ISWAP lo ba ija naa lọ.

"Lootọ ni a mọ pe wọn n ba ara wọn ja o si jẹ iroyin ayọ fun wa."

Awọn agbegbe ti ọmọ ogun Naijiria kọlu

Oríṣun àwòrán, HQ Nigerian Army

Ẹgbẹ wo ni ISWAP?

ISWAP ni igun agbesunmọmi to yapa kuro lara Boko Haram, ti wọn si darapọ mọ ẹgbẹ alakakiti ẹsin Islami State IS lọdun 2016.

Lati asiko ti wọn ti pinya ni oniruru ija ti maa n waye laarin ẹgbẹ mejeji, paapaa lagbegbe Lake Chad.

Yatọ si ISWAP, awọn ọmọ ẹgbẹ agbesunmi miran tun ti yapa lati ara Boko Haram lẹyin ede aiyede nipa adari to maa waye laarin wọn.

Awọn ọmọ ogun Naijiria

Oríṣun àwòrán, HQ Nigerian Army

Ileeṣẹ ọmọ ogun Naijiria kọlu ibuba awọn agbesunmi kaakiri ariwa

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ẹwẹ, ileeṣẹ ọmọ ogun Naijiria ti bẹrẹ ikọlu lemọlemọ si ibuba awọn agbesunmọmi ni ariwa Naijiria.

Awọn ikọlu wọn yii lo n waye lẹyin ti Aarẹ Ilẹ Amẹrika, Donald Trump dunkoko pe oun yoo kogun wọn Naijiria ti ijọba apapọ ko ba fopin si bi awọn alakatakiti ẹsin Islam ṣe n gbẹmi awọn Kristẹmi.

Iroyin ni lati oju ofurufu ni ileeṣe ọmọ ogun ti n ju ado oloro si awọn agbesunmi ni ipinlẹ bii Kwara, Borno, Katsina, atawọn ipinlẹ mii ni ariwa Naijiria.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọmọ ogun ofurufu ni Naijiria, ọgagun Ehimen Ejodame sọ pe awọn ju ado oloro si ibuba awọn agbesunmọmi naa, to fi mọ awọn ibi ti wọn n ko ounjẹ atawọn ohun ija oloro si.

O ni awọn kọlu agbegbe Shuwaram ati Mallam Fatori lẹyin ti wọn ti ri awọn agbesunmọmi naa ti wọn n ko ara wọn jọ lori alupupu.

O pari ọrọ rẹ pe ikọlu naa jẹ ara afojusun ileeṣẹ ọhun lati ri daju pe igbesunmọmi di ohun igbagbe ni Naijiria.

Wayi o, Aarẹ Trump ti ni oun ti paṣẹ fun ẹka to n ri si ọrọ ogun orilẹede Amẹrika lati maa mura ikọlu rẹ si Naijiria ti ijọba Naijiria ba tẹsiwaju lati maa kawọ gbera lori bi wọn ṣe n fẹmi awọn ọmọlẹyin Kristi ṣofo.

Àkọlé fídíò, Àbùdá mẹ́ta ni mo fi hàn yín, àmọ́ mẹ́rin ni mí, èyí tí mo bá fẹ́, ni máà lò

Iléeṣẹ́ ológun dóòlà èèyàn 86 lọ́wọ́ ajínigbé, mú afurasí agbésùnmọ̀mí 29 ní Borno

Ileeṣẹ ologun ti inagijẹ wọn n jẹ Operation Hadin Kai (OPHK) lẹkun ila oorun ariwa ti doola eeyan mẹrindinlaadọrun un lọwọ ajinigbe, wọn si tun fọwọ ofin mu afurasi agbesunmọmi mọkandinlọgbọn nipinlẹ Borno.

Alukoro fun ileeṣẹ ologun, Ọgagun Lt. Col. Sani Uba, lo fọrọ yii lede loju opo X rẹ lonii ọjọ kẹwaa oṣu Kọkanla.

Ọgagun Uba ṣalaye pe ikọ OPHk doju ija kọ Boko Haram ati ISWAP lọjọ kẹsan an oṣu Kọkanla ni Dutse Kura, lẹyin ti wọn gbọ pe awọn agbesunmọmi n ji awọn araalu ati ọkọ gbe lopopona Buratai-Kamuya.

Ibọn AK-47 meji, ọkọ akero mẹta, awọn ọmogun, awọn agbesunmọmi atawọn araalu tawọn ologun doola lọwọ ajinigbe

Oríṣun àwòrán, Nigerian Army/X

''Awọn ọmogun le awọn agbesunmọmi lọ sọna Mangari, wọn si doju ija kọ awọn agbesunmọmi naa ti wọn fi fẹsẹ fẹẹ.

Lẹyin tawọn ọmogun wa ibuba awọn agbesunmi ọhun ni wọn ṣawari ibi ti wọn n saa si mọkanla nibi ti wọn ti doola eeyan mẹrindinlaadọrun un tawọn obinrin ati ọmọde wa ninu wọn.

A gba ibọn AK-47 kan, ọta mẹtalelaadọrin, ọkọ marun un, alupupu marun un, kẹkẹ mẹjọ ati kẹkẹ ẹlẹsẹ mẹta meji lọwọ awọn agbesunmọmi naa.

Awọn ọmogun tun ba ibuba awọn agbesunmọmi naa jẹ,'' Ọgagun Uba ṣalaye.

''Ko si ọmogun to farapa ninu ikọlu ti wọn ṣe sawọn agbesunmọmi''

Ẹwẹ, awọn ọmogun Naijiria tun mu awọn agbesunmọmi mọkandinlọgbọn ni Magada.

Awọn nnkan ti wọn ri gba lọwọ wọn gẹgẹ bi agbẹnusọ ileeṣẹ ologun ṣe ṣalaye ni ọkọ ''pickup'' meji, kẹkẹ ẹlẹsẹ mẹta ti epo bẹntiroolu wa ninu rẹ kan, jẹrika epo bẹntiroolu bii ẹgbẹrun kan, jẹrika ọiili ẹnjini ọkọ mẹrin, taya ọkọ nla tuntun meji, oogun lilo ati ọpọlọpọ ounjẹ.

Ọgagun Uba ko ṣai fidi rẹ mulẹ pe ko si ọmogun kankan to fara kaaṣa ninu ikọlu ti wọn ṣe sawọn agbesunmọmi naa.

Awọn lọgalọga ileeṣẹ ologun ti wa gboṣuba rabandẹ fawọn ọmogun Operatio Hadin Kai fun iṣẹ takuntakun ti wọn ṣe ati aṣeyọri wọn.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post