Wo iye owó tó san fún Hajj 2026 bí àjọ Alálàájì ṣe kéde àdínkù owó ìrìnàjò sí Mecca

Aworan awọn eeyan ni Kaaba, Saudi Arabia

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Aworan awọn eeyan ni Kaaba
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Lẹyin oṣu kan ti ijọba apapọ Naijiria pe fun adinku owo ti awọn eeyan n san fun lilọ si Mecca lati Naijiria, ajọ NAHCON to n ri si irinajo lọ si Saudi Arabia ti mu adinku ba owo naa bayii.

Atẹjade kan ti wọn ti kede adinku naa, ṣalaye pe igbesẹ yii waye lẹyin ti Igbakeji Aarẹ, Kashim Shettima, pe fun adinku owo Hajj lati owo to le N8.7m ti awọn arinrinajo lati apa Guusu n san tẹlẹ, ati 8m ti awọn eeyan apa Ariwa n san.

NAHCON tun kede pe adinku naa yoo mu ki owo ti iye rẹ to N792,943.83, kuro lara iye ti wọn yoo san fun irinajo Hajj ni 2026.

Wọn ni eyi yoo si tun ni i ṣe pẹlu asiko ti wọn ba n gbera lati ilẹ yii lọ si Saudi.

Apa kan atẹjade naa ka pe:

"Adinku to pọ ju waye fun awọn arinrinajo lati apa Guusu, nibi ti a ti din owo naa ku pẹlu N792,943.83.

"Owo ti wọn yoo san bayii ni N7,991,141.76, dipo N8,784,085.59 ti wọn n san tẹlẹ.

"Awọn arinrinajo lati apa Ariwa, yoo ri adinku N760,915.83, ninu owo ti wọn n san tẹlẹ, owo ti wọn yoo san bayii ni N7,696,769.76.

Fun Borno ati Adamawa ti owo wọn kere ju ni Naijiria, iye tuntun ti wọn yoo san bayii ni N7,579,020.96.

Eyi din wọn ni N748,104.63."

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Gbèdéke ọjọ́ tí anfaani yii yoo kasẹ nilẹ

Bi NAHCON ṣe wi, o ṣe pataki fun awọn arinrinjo to fẹ jẹ anfaani adinku yii lati sanwo Hajj wọn o pẹ ju, ọjọ karun-un, oṣu Kejila ọdun 2025 yii.

"Ọjọ yii ṣe pataki pupọ lati le pari awọn eto gbogbo, ka si tun le fi asiko naa gba aaye silẹ fun awọn Alaalaji to fẹ lọ ni 2026."

Lẹyin ọjọ karun-un oṣu Kejila ọdun 2025, ko ni i si anfaani lati sanwo Hajj fun 2026 mọ bi NAHCON ṣe kede.

Ireti wa pe gbogbo Musulumi ilẹ Naijiria to fẹ ṣe Haji ni 2026 ni yoo tẹwọgba adinku yii, eyi ti yoo mu irinajo naa rọrun fun wọn ju bo ṣe wa tẹlẹ lọ.

Kí ló ṣẹlẹ̀ ṣáájú?

Ninu oṣu Kẹwaa ni Aarẹ Bola Tinubu, paṣẹ pe ki ajọ NAHCON din owo ti awọn arinrinajo yoo san fun Hajj 2026 ku.

Ikede naa waye lẹyin ti NAHCON kede owo ti awọn arinriajo yoo san fun iṣẹ Haji lọdun to n bọ.

Igbakeji olori oṣiṣẹ nileeṣẹ aarẹ, Ibrahim Hadeija, lo kede nigba naa pe Aarẹ Tinubu ti paṣẹ pe ki NAHCON wa ọna ti yoo fi ja owo Mecca naa walẹ.

Iye ti NAHCON kede nigba naa ni:

"Maiduguri-Yola (Yobe, Borno, Adamawa, Taraba) yoo san N8,318,336.67.

"Awọn ipinilẹ Ariwa yoo san N8,244,813.67, nigba ti awọn ti Guusu yoo san N8,561,013.67."

Ọgbẹni Hadeija sọ pe Tinubu sọ pe bi owo naa ba ṣe dinku si ni yoo jẹ ki ọpọ Musulumi le ṣe Hajj.

Àdínkù bá iye èèyàn tí yóò ṣe Hajj ní Naijiria

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Tẹ o ba gbagbe, ninu oṣu Kẹwaa ọdun 2025 yii ni ijọba Saudi kede pe adinku yoo ba iye ọmọ Naijria ti yoo ṣe Hajj ni 2026.

Alaye ti NAHCON ṣe nigba naa ni pe adinku ba iye eeyan ti yoo wọ Saudi fun Hajj lọdun to n bọ lati dena ohun to ṣẹlẹ ni 2025.

Ohun to ṣẹlẹ bi wọn ṣe wi ni pe awọn arinrinajo Naijiria ko ba ijọba rin lọ si Saudi bi wọn ṣe fi aaye pupọ silẹ fun wọn to.

NAHCON sọ pe aaye ti iye rẹ jẹ 52,544 ni wọn fi silẹ fawọn ọmọ Naijiria fun iṣẹ Hajj ọdun 2025, ti yoo ba ijọba ipinlẹ wọn lọ.

O ni ṣugbọn iyalenu lo jẹ, pe eeyan 41,218 pere lo ba ijọba ipinlẹ wọn lọ si Saudi. Awọn alalaaji ẹgbẹrun mejidinlogun (18,000) si ba ileeṣẹ aladaani rin irinajo naa bi NAHCON ṣe sọ.

Eyi lo mu apapọ arinrinajo lọ si Saudi ni 2025 jẹ 59,128, ti aaye 35,872 si wa nilẹ lai jẹ pe ẹnikẹni lo o, bi ileeṣẹ to n pin in fun Hajj ati Umrah ṣe pin in.

Ṣugbọn ni bayii ti adinku ti ba iye owo ti awọn arinrinajo yoo san fun Hajj, ireti wa pe awọn Musulumi to n gbero lati lọ si Mecca lọdun to n bọ yoo lo anfaani naa.