Àwọn ewu mẹ́fà tó wà nínú mímu sìgá olóoru oníbátìrì Vape

Ọkunrin to wọ aṣọ dudu ati funfun to n mu siga

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ajọ WHO ti fi atẹjade kan lede to ṣafihan pe eeyan to le ni ọgọrun-un miliọnu kaakiri agbaye lo n mu siga to n lo ina ilẹtiriki ti miliọnu marundinlogun ninu wọn si jẹ ọmọde.

Ohun to jani laya julọ ninu atẹjade naa ni pe ewu nla lo wa ninu siga ọhun latari pe awọn to n polowo rẹ n polongo rẹ bii pe ko ni ewu kankan ninu amọ wọn n ṣakoba fun awọn eeyan atawọn ọmọde nipa fifa eroja nicotine sinu.

Adari ajọ WHO, Tedros Adhanom Ghebreyesus ti fẹun kan awọn ileeṣẹ to n ṣe siga pe wọn n mọọmọ n fa oju awọn ọmọde mọra lati maa fa siga.

Ghebreyesus ni awọn ileeṣẹ naa yoo ṣakoba fun igbiyanju WHO lati mu oju awọn ọdọ kuro lara oogun nicotine.

Gbogbo igba lawọn ileeṣẹ eto ilera maa n kilọ lodi si siga mimu amọ ọpọ awọn eeyan lo gbagbọ pe ko si ewu ninu mimu siga to n lo ina elẹtiriki.

"O pe mi lati mu siga ju vaping lọ"

Ọdọkunrin kan to maa n mu siga mejeji sọ ninu ifọrọwerọ pẹlu BBC pe o san fun oun lati mu siga.

O ni mimu siga ti wọn ṣa ina sori rẹ maa n tu oun lara ju siga to n o ina tabi batiri lọ.

Ẹlomiran to ba wa sọrọ sọ pe siga to n lo batiri ma n mu ko rọrun fun oun lati mu siga loorekoore ati ni gbogbo asiko to ba n wu oun lati mu.

Ki ni iyatọ laarin siga mejeji yii?

Ọkunrin to n mu siga niwaju ẹrọ ayarabiiaṣa

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Dokita Abdullahi Kabir Sulaiman ati Auwalu Fatihu Abubukar ti wọn jẹ onimọ nipa eto ilera nileewosan Mallam Aminu Kano niluu Kano sọ iyatọ lara awọn siga mejeji.

Iyatọ akọkọ ni bi wọn ṣe n mu awọn siga naa; siga aye atijọ nilo ki wọn ṣa ina si ori rẹ lati fa ewe to wa ninu rẹ amọ siga to n lo batiri yii, awọn kẹmika lo wa ninu rẹ to n jẹ ko yọ eefin.

Auwal ni iye iwọn nicotine to wa ninu siga to n lo ẹletiriki pọ ju eyi to wa ninu siga kejilọ, lo mu ki irufẹ siga naa lewu fun agọ ara.

Auwal sọ siwaju si pe awọn kẹmika mii to wa ninu siga oni batiri tun pọ ju siga aye atijọ lọ.

Awọn ewu wo lo wa ninu mimu siga oni batiri?

Arun jẹjẹrẹ

Dokita Abdullahi sọ pe mimu siga yii le ṣokunfa arun jẹjẹrẹ ni ara ẹda. Irufẹ arun jẹjẹrẹ ti ẹni to ba n mu siga oni batiri yii le dojukọ ni jẹjẹrẹ inu ẹdọforo, ọkan, ifun ati ọpọlọ.

Arun ọkan

Dokita naa ni mimu irufẹ siga yii le ṣokunfa arun ọkan ti wọn n pe ni Pulsation.

Isọrọ naa tun le fa awọn arun mii bii tirẹ.

O le fa oju awọn ọmọde mọra

Dokita naa ni ti awọn ọmọde ba ri awọn agbalagba ti wọn n fa irufẹ siga yii o le fa oju wọn mọra lati tọ wo.

Awọn ewu mii to wa ninu mimu siga to n lo ina ilẹtiriki taboi natiri

  • O le ṣẹ oyun ninu alaboyun
  • O le jẹ ki alaboyun bi ọmọ ti ko pe
  • O le jẹ ki ọmọde tete maa gbagbe nnkan
  • O le ṣilẹkun fun iwa ọti amuju

Ọna lati daabo bo ọmọ rẹ lọwọ siga oni batiri mimu

  • Maa gba wọn nimọran lodi si siga mimu ki o si maa sọ ewu inu rẹ fun wọn
  • Ya wọn sọtọ kuro lara awọn ọrẹ to n mu siga
  • Ri daju pe awọn ọrẹ to yi wọn kan kii ṣe awọn to n mu siga