Wo ohun tí orílẹ̀èdè China pinnu láti ṣe bí orílẹ̀èdè kankan bá da ètò ìdàgbàsókè tó ń wáyé ní Nàìjíríà rú

Aarẹ Bola Tinubu wọ aṣọ buba olomi aro o bọwọ pẹlu Aarẹ Xi Jinping ti China to wọ kootu alawọ dudu.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 8

Orilẹede China ti kede atilẹyin rẹ fun Naijiria lẹyin ti Aarẹ Donald Trump sọ pe Amẹrika yoo kogun ja Naijiria ti ijọba Aarẹ Bola Tinubu ba kuna lati fopin si iṣekupani awọn kristẹni.

Ninu atẹjade kan ti ijọba China fi sita ni o ti ṣalaye pe oun wa lẹyin ijọba Tinubu papaa julọ lori awọn ọkan o jọkan eto idagbasoke ti ijọba rẹ n ṣe ni Naijiria.

China tun kilọ pe ki orilẹde ilẹ okeere kankan ma dasi iṣejọba orilẹede Naijiria.

Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ijọba ileeṣẹ ijọba China to n ri si ọrọ ilẹ okeere, Mao Ning, lo fidi ọrọ yii mulẹ fawọn akọroyin lonii ọjọ Iṣẹgun niluu Beijing.

Ning ṣalaye pe ''Orilẹede China gẹgẹ bi alabaṣiṣẹpọ Naijiria tako igbesẹ awọn orilẹede alagbara lagbaaye lati lo ọrọ ẹsin tabi ẹtọ ọmọniyan dasi iṣejọba orilẹede Naijiria; tabi lati ko ọmogun lọ sibẹ.''

Lopin ọsẹ to kọja ni Amérika dunkoko wi pe o ṣee ṣe koun ko ọmogun oun lo koju awọn awọn alakatakiti ẹsin to n ṣeku pawọn kristẹni ni Naijiria.

Aarẹ Trump kede wi pe oun yoo kawọn ọmogun Amerika lọ ja ni Naijiria, bi iṣekupani awọn kristẹni ko ba dawo duro ni Naijiria.

Trump sọ pe nnkan to n ṣẹlẹ ni Naijiria n kọ oun lominu nitori awọn eeyan kan to n ṣeku pawọn kristẹni.

Amọ, ileeṣẹ ijọba to n ri si ọrọ ilẹ okeere ni Naijiria ti sọ ọ di mimọ pe nnkan to n ṣẹlẹ ni Naijiria yatọ sawọn ẹsun ti Trump ka silẹ.

Amẹrika tun sọ pe oun yoo dawọ gbogbo iranwọ toun n ṣe fun Naijiria duro, ti iṣekupani awọn kristẹni ba tẹsiwaju.

'Tinubu kò gbọdọ̀ tọwọ́ òṣèlú bọ ọ̀rọ̀ Trump, ó ní láti ṣàlàyé ìgbésẹ̀ rẹ̀ lórí ètò ààbò látìgbà tó ti di ààrẹ'

Ààrẹ Tinubu wọ agbádá wà ní apá òsì, àwọn ọmọ ogun tó wà lórí ọkọ̀ wá ní apá ọ̀tún

Oríṣun àwòrán, Getty Images/Facebook

Láti bíi ọ̀sẹ̀ díẹ̀ sẹ́yìn ni onírúurú ìròyìn ti ń jà lórí ayélujára lẹ́yìn tí ààrẹ Amẹ́ríkà, Donald Trump kéde ṣe kéde pé pípa àwọn Kristẹni ń wáyé lọ́pọ̀lọpọ̀ ní Nàìjíríà àti pé ìjọba kò yà sí ọ̀rọ̀ náà.

Lẹ́yìn náà ló kéde pé Amẹ́ríkà máa ṣe ìkọlù sí Nàìjíríà tí ìjọba kò bá tètè wá wọ̀rọ̀kọ̀ fi ṣàdá lórí àwọn ẹ̀sùn náà.

Ìkéde Trump yìí ti ń fa onírúurú awuyewuye pàápàá láàárín àwọn ẹlẹ́sìn mùsùlùmí àti kristẹni.

Ẹgbẹ́ tó ń jà fún ẹ̀tọ́ àwọn mùsùlùmí ní Nàìjíríà ìyẹn Muslim Rights Concern, MURIC sọ pé ọ̀rọ̀ ìpànìyàn tó ń lọ ní Nàìjíríà gba sùúrù àti ìfarabalẹ̀ gidi.

Boko Haram, ISIS àti ISWAP ni a fẹ́ kí ẹ báwa kojú - MURIC fèsì fún Trump

Ọmọ ogun tó gbé ìbọn dání nínú igbó

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Adarí ẹgbẹ́ MURIC, Ọ̀jọ̀gbọ́n Ishaq Akintola nínú àtẹ̀jáde kan tó fi léde lọ́jọ́ Àìkú, ọjọ́ Kejì, oṣù Kọkànlá, ọdún 2025 sọ pé kò bá sàn kí ìjọba Amẹ́ríkà dojú ìjà tó fẹ́ gbé kó Nàìjíríà kojú àwọn ẹgbẹ́ agbéṣùmọ̀mí bíi Boko Haram, ISIS àti ISWAP.

Ó ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀ máa ṣàfihàn pé kìí ṣe pé Trump kàn fẹ́ ṣe ìkọlù sáwọn mùsùlùmí àti mọ́ṣálámí tí wọn kò mọwọ́ mẹsẹ̀ lórí àwọn ìkọlù tó ń wáyé náà.

"Àwọn agbéṣùmọ̀mí kìí ṣe ara wa. Àwọn ìlànà àti ìṣe wọn lòdì sí òfin ẹ̀sìn Islam. A bu ẹnu àtẹ́ lu ìwà ìgbéṣùmọ̀mí, a ò sì ní ní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn tí wọ́n kàn máa ń pa èèyàn lọ́nà àìtọ́.

"A ò lọ́wọ́ nínú jíjí èèyàn gbé láti fi gba owó lọ́nà àìtọ́. Àjòjì ni wọ́n jẹ́ nínú Islam."

Akintola ní àwọn ọmọ Nàìjíríà nílò láti ṣe sùúrù lórí ọ̀rọ̀ tí Trump sọ àti pé kò sí ìdí táwọn mùsùlùmí tó jẹ́ alálàáfíà àtàwọn ọmọ Nàìjíríà míì nílò láti fi máa bẹ̀rù.

"Ó máa dára kí ìjọba Amẹ́ríkà gbé ojú ìjà ko àwọn agbéṣùmọ̀mí bíi Boko Haram, ISIS, Àti ISWAP tí wọ́n ti ń pa àwọn mùsùlùmí àti kristẹni láti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn báyìí.

"Àwọn agbébọn tí wọ́n ti ń jí èèyàn gbé láti gba owó jẹ́ àwọn tó yọ kó wà lára àwọn tí wọ́n máa ṣèkọlù sí. A máa kan sáárá sí Amẹ́ríkà àti Trump tó bá jẹ́ pé àfojúsùn wọn lèyìí."

Ó wòye pé ìjọba Nàìjíríà ti ń gbìyànjú láti kojú àwọn ọ̀daràn náà láti ọdún pípẹ́, táwọn ọmọ ogun Nàìjíírà sì ti wà nínú igbó láti kojú àwọn ọ̀bàyéjẹ́ náà.

"Inú ìjọba àtàwọn èèyàn Nàìjíríà máa dùn ti Amẹ́ríkà bá le báwa kojú àwọn ọ̀daràn yìí. A nílò irú ìrànwọ́ yìí, tó sì máa jẹ́ ohun ìdùnnú tí gbogbo àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Boko Haram, ISIS àti ISWAP bá di ohun ìgbàgbé ní orílẹ̀ ède yìí.

"Àmọ́ ó máa dàbí pé wọ́n kàn mọ̀ọ́mọ̀ kọlu àwọn mùsùlùmí tàbí ìtẹ̀síwájú ìpolongo ẹ̀sìn kristẹni ti sẹ́ńtúrì kọkàndínlógún tí wọ́n bá kàn ṣe ìkọlù sáwọn mùsùlùmí àti mọ́ṣáláṣí tàbí tí wọ́n bà ṣe ìkọlù sáwọn olórí ẹ̀sìn Islam."

Ọ̀jọ̀gbọ́n Akintola tún rọ àwọn mùsùlùmí àtàwọn ọmọ Nàìjíríà míì láti má gba èrò títako Trump àti Amẹ́ríkà láàyè nínú ọkàn wọn lórí ìdúnkokò yìí, bó ṣe ní kí àwọn èèyàn máa bá iṣẹ́ wọn lọ láì sí ìbẹ̀rù kankan pé gbogbo àgbáyé ló ń rí ohun tó ń ṣẹlẹ̀.

"A ò fẹ́ ìgbédìde ẹgbẹ́ kankan látọ̀dọ̀ àwọn ẹgbẹ́ Islam kankan láti dìde tako ìdúnkokò Trump nítorí àwọn ọmọ Nàìjíríà tí kò ṣẹ̀ ni wọ́n máa padà ṣe ìkọlù bẹ́ẹ̀ sí, tó fi mọ́ àwọn mùsùlùmí.

"Àwọn ọ̀dọ́ mùsùlùmí ní ẹkùn gúúsù àti àríwá kò gbọdọ̀ dìde láti ṣe ìwọ́de lórí ìdúnkokò Trump. A nílò láti gba ìjọba Nàìjíríà láàyè láti yanjú ọ̀rọ̀ náà pẹ̀lú ìlànà tó yẹ."

Bákan náà ni wọ́n gba ìjọba Nàìjíríà lámọ̀ràn láti ní ìjíròrò tó yẹ pẹ̀lú ìjọba Amẹ́ríkà, kí wọ́n sì sri dájú pé àwọn náà kò dúnkokò padà sí Amẹ́ríkà.

Ó fi kun pé MURIC kò ní yẹ̀bá nínú ẹ̀jẹ́ wọn pé ìjíròrò ni àwọn yóò máa ní dípò ìwà jàgídíjàgan, tí wọ́n sì rọ gbogbo àwọn mùsùlùmí láti gba ìfẹ́ àti àlááfíà láàyè ní agbègbè wọn.

'Ṣé ìpàdé pẹ̀lú Trump ní kíákíá, àsìkò à ń gọ sí abẹ́ ìka kan kọ́ léyìí'

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí ọ̀nà tí ìjọba Nàìjíríà le gbà láti paná ẹ̀sùn tí ìjọba Amẹ́ríkà fi ń kan Nàìjíríà yìí, Festus Adedayo, onímọ̀ nípa ètò òṣèlú Nàìjíríà sọ pé ààrẹ Tinubu kò gbọdọ̀ tí ọwọ́ òṣèlú bọ ọ̀rọ̀ náà.

Adedayo ní Tinubu gbọdọ̀ kọ́kọ́ ṣe ìpàdé pẹ̀lú ààrẹ Amẹ́ríkà kó sì ṣe àfihàn àwọn ìgbésẹ̀ tí ìjọba rẹ̀ ti gbé láti ìgbà tó ti gba ipò ààrẹ Nàìjíríà pẹ̀lú àwọn ẹ̀rí tó fìdí múlẹ̀.

Ó wòye pé àsìkò yìí kìí ṣe ìgbà láti máa gọ sí abẹ́ ìka kan rárá, tó sì nílò láti fojú àwọn tó ń ṣe àtìlẹyì fáwọn agbéṣùmọ̀mí léde.

"Tinubu kò gbọdọ̀ gbìyànjú láti ṣọ́ra jù nítorí àti rí ìyànsípò padà lọ́dún 2027, àsìkò láti fi han gbogbo ayé pàápàá Amẹ́ríkà rèé, àwọn ìgbésẹ̀ tó ti ń gbé láti kojú ìṣòro ètò ààbò láti ìgbà tó ti gba àkóso ìjọba Nàìjíríà láti oṣù mọ́kàndínlọ́gbọ̀n sẹ́yìn, kìí ṣe àsìkò àti máa díbọ́n rárá.

"Gbogbo ayé ló mọ̀ pé àwọn alágbára tó wà nípò tó ga ló ń ṣe agbátẹrù àti àtìlẹyìn fáwọn Boko Haram ní Nàìjíríà, ó gbọ́dọ̀ ṣetán láti ṣàfihàn wọn kódà kó jẹ́ àwọn tó wà nínú ìṣèjọba rẹ̀."

Ó ní òun ní ìgbàgbọ́ pé àwọn kan nínú àwọn aṣòfin Nàìjíríà àtàwọn ọ̀gá lẹ́nu iṣẹ́ ológun ni ọwọ́ wọn kò mọ́ lórí ọ̀rọ̀ Boko Haram tí ààrẹ sì gbọdọ̀ le fojú wọn hàn fún aráyé.

Bákan náà ló ní àwọn èèyàn náà gbọdọ̀ fojú winá òfin, kó tó di pé ó máa wá kojú àwọn agbéṣùmọ̀mí pẹ̀lú ọwọ́ líle tí Amẹ́ríkà náà sì máa fojú rí gbogbo rẹ̀.

Ó fi kun pé àwọn ọmọ Nàìjíríà gbọdọ̀ tò lẹ́yìn ààrẹ lásìkò yìí lòdì sí nǹkan tí Trump ń sọ nítorí àsìkò tó lágbára ni Nàìjíríà ń kojú báyìí.

"Trump kìí ṣe ọ̀rẹ́ àwọn Kristẹni, ojú ayé lásán láti fa ọkàn àwọn ọmọlẹ́yìn Kristẹni mọ́ra àti láti tún máa pariwo orúkọ rẹ̀ lásán ló ń ṣe."

Dẹ́kun ìhàlẹ̀ láti kọlu Nàìjíríà, ọ̀nà ìrànlọ́wọ́ lórí ètò ààbò la fẹ́ - Rabiu Kwakwanso fohùn ránṣẹ́ sí Ààrẹ Trump

Aworan Donald Trump ati Rabiu Kwankwaso, gomina ipinlẹ Kano nigba kan ri

Oríṣun àwòrán, Getty Images/Kano State Govt

Oludije fun ipo aarẹ labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu New Nigeria Peoples Party (NNPP) ni ọdun 2023, Rabiu Kwankwaso ni ohun to yẹ ki orilẹede Amẹrika ṣe dipo idun koko mọ ijọba Naijiria ni ki wọn pese iranlọwọ lati gbe ogun tie to aabo to mẹhẹ.

"Amẹrika ni lati ran Naijiria lọwọ pẹlu pipese imọ ẹrọ lati gbe ogun tie to aabo to mẹhẹ, ko ki n ṣe pe ki wọn ma dun koko pe awọn yoo kọlu orilẹede wa," Kwankwaso, gomina nigba kan ri nipinlẹ Kano, sọ eyi loju opo ayelujara X.

Ọrọ yii jẹyọ lẹyin ọrọ ti Aarẹ orilẹede Amẹrika, Donald Trump sọ pe ijọba orilẹede Naijiria faye gba ki awọn agbebọn ma ṣekupa awọn Kristẹni lorilẹede Naijiria.

Trump, sọ loju opo ayelujara X lọjọ Ẹti, "Kristẹni n koju ikọlu lorilẹede Naijiria. Ọpọ awọn kristẹni ni wọn n ṣekupa. Awọn agbebọn musulumi lo wa nidi iṣekupani yii".

Ni ojọ Ṣatide, Aarẹ Amẹrika tun dunkoko pe oun yoo ran awọn ologun Amẹrika wa si orilẹede Naijiria ti ijọba ba kuna lati gbe igbesẹ to yẹ ki wọn gbe tako awọn agbebọn.

Ṣugbọn ninu alaye rẹ, Kwankwaso gbagbọ pe ijiroro yoo ṣe ọpọ anfani lori ọrọ yii, ati pe eto aabo to mẹhẹ jẹ ohun to n ṣe ọpọ akoba fun gbogbo ẹlẹsin boya musulumu abi kristẹni, ẹgbẹ oṣelu ati awọn ẹya.

"O se koko ka jẹ ko di mimọ pe orilẹede wa jẹ orilẹede olominira nibi ti ọpọ eeyan ibẹ ti n koju ọpọ ikọlu.

"Ikọlu ti a n koju ki n ṣe ti ẹlẹyamẹya, ẹṣin tabi ẹgbẹ oṣelu," agbaọjẹ ẹgbẹ oṣelu NNPP ṣalaye.

"Ijọba Naijiria ni lati yan awọn eeyan kan lati lọ ba orilẹede Amẹrika sọrọ. Asiko ti a way ii ni o yẹ ki gbogbo wa ṣe ara wa ni ọkan."

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post