Èyí ni owó orí 50 tí ìjọba Tinubu ní kí aráàlú má san mọ́ láti ọdún 2026.

Aworan ọwọ to ko owo orilẹede Naijiria dani

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Owo Naijiria
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

O ti ṣe diẹ ti ijọba apapọ Naijiria ti n kede pe atunṣe yoo ba ilana owo ori sisan lorilẹde yii, eyi ti yoo yọ awọn eeyan kan kuro, ti wọn ko ni i sanwo ori mọ rara.

Bakan naa ni adinku yoo de ba owo ori fun awọn ẹka olokoowo ti ọja tabi iṣẹ ti wọn n ṣe ko to nnkan .

Apapọ owo ori naa to jẹ aadọta (50) ni ijọba sọ pe yoo gbera sọ lọjọ kin-in-ni, oṣu Kin-in-ni ọdun 2026.

Èyi ni awọn owo ori ti atunṣe iranwọ ba naa gẹgẹ bi Alaga to n ri si atunṣe owo ori nileeṣẹ Aarẹ, Taiwo Oyedele, ṣe fi sita lọjọ Aje ana.

𝐏𝐞𝐫𝐬𝐨𝐧𝐚𝐥 𝐈𝐧𝐜𝐨𝐦𝐞 𝐓𝐚𝐱/ 𝐏𝐀𝐘𝐄

1. Owo ori yii wa fun awọn oṣiṣẹ ijọba to n gba owo oṣu to kere ju, ati awọn ti ko tiẹ gba to bẹẹ rara. Ṣugbọn labẹ atunṣe yii,ijọba ti yọ wọn kuro labẹ owo ori sisan patapata. Awọn eeyan ti owo to n wọle fun wọn lọdun to miliọnu kan ati ẹgbẹrun lọna igba naira (₦1,200,000) ko ni i sanwo ori mọ. Awọn ti wọn n gba to ogun miliọnu lọdun yoo ni adinku owo ori sisan. Bi wọn ba fun ọ ni ẹbun, o ko ni i sanwo ori lori rẹ ti o ba lọ gba a.

Àwọn èyi tí ìjọba yóò fara gbá kí owó orí tí aráàlú yóò san lè dínkù

  • * Pension contribution- Owo ifẹyinti ti wọn n yọ lara oṣiṣẹ lasiko to ṣi wa lẹnu iṣẹ.
  • * NHIS health contributions- Owo ilera
  • * National Housing Fund contributions- Ẹdawo ileegbe
  • * Interests paid on home ownership loan- Èlé owo ori ile ti yoo di tẹni.
  • *Owo madandofo ọlọdọọdun
  • Owo ifẹyinti ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Àwọn miran ni:

  • Bi o ba ta awọn nnkan kan to jẹ dukia rẹ, ijọba ko ni i yọ owo ori lori rẹ
  • Bi o ba ta ile rẹ, ijọba ko ni I gba owo ori lori dukia naa.
  • Awọn nnkan elo rẹ to to miliọnu marun-un naira.
  • Bi o ba ta mọto meji ti o n lo lọdun meji.
  • Bi o ba ri ere lori ipin idokowo to wa laaarin ₦150m / ₦10m
  • Bi o ba ko owo naa le ori okoowo miran pada, ijọba ko ni i yọ owo ori .

Awọn olokoowo kekere

Aworan awọn ohun jije.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Awon ohun jije

Ijọba n mu adinku ba owo ori sisan fun awọn olokoowo ati ileeṣẹ kereje lati le jẹ ki iṣẹ pọ fawọn eeyan lati ṣe.

Ileeṣẹ kekere towo to n wọle fun wọn to ₦100m — ko ni i sanwo ori ti a mọ si CIT.

*Awọn agbanisiṣẹ to ba gba oṣiṣẹ tuntun ti wọn ko si da wọn silẹ fun ọdun mẹta yoo ni adinku ninu owo ori ti wọn n san.

*Awọn ileeṣẹ to n ri si eto ọgbin ko ni i sanwo ori fun ọdun marun-un.

*Awọn ileeṣẹ kekere ko ni i sanwo idagbasoke.

Ko ni i si owo ori ọja (VAT) sisan lori awọn nnkan amayedẹrun yii:

*Awọn ounjẹ

  • . Owo ile

* Owo ileewe

*Ilera

*Oogun

* Epo bẹntiroolu, Disu ati awọn elo to n lo oorun( solar) . Ajilẹ, eso gbingbin, awọn ẹranko ti a n sin.

*Awọn irinṣẹ fun awọn ti ẹya ara penija, fun apẹẹrẹ, aga ijokoo awọn eeyan ti ko le rin (wheelchairs).

*Ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Àwọn miran tun ni

Ọkọ ero ajọwọ, ọna ti a jọ n rin.

*Nnkan elo itọju ọmọde.

Awọn nnkan eelo fun aanu alaini

*Idigo (sanitary pads) tawọn obinrin fi n ṣe nnkan oṣu.

Bi o ba fi owo ranṣẹ ti ko to ẹgbẹrun mẹwaa naira, wọn ko ni i yọ owo ori lapo rẹ.

Fifi owo ranṣẹ lati banki to jẹ oriṣi kan naa ni wọn sira wọn.

Owo oṣu sisan ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ṣaa, o di oṣu Kin-in-ni ọdun 2026 ki awọn anfaani yii too maa waye fun awọn ọmọ Naijiria bi ijọba apapọ ṣe kede.