Ìyà tí mọ́ àwa olólùfẹ́ Arsenal lára ni mo ṣe kọ Ewúrẹ́ sára aṣọ mi – Agba Inaki

Àkọlé fídíò, Ìyà tí mọ́ àwa olólùfẹ́ Arsenal lára ni mo ṣe kọ Ewúrẹ́ sára aṣọ mi – Agba Inaki
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Eekan lara awọn sọrọsọrọ lori ayelujara ni Lekan Ọlalẹyẹ ti inagijẹ rẹ n jẹ Lekan Kingkong tabi Agba Inaki.

Ọpọ lo mọ Lekan Agba Inaki gẹgẹ bi i ololufẹ ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal eyi to si maa fi n ṣe ọpọlọpọ fọnran ayelujara pẹlu yala nigba ti nnkan n dun fun ẹgbẹ agbabọọlu naa tabi igba ti nnkan lọ jaijai fun wọn.

Ninu ifọrọwerọ yii pẹlu BBC News Yoruba lori ifẹ rẹ fun ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal, paapaa julọ lawọn saa ti nnkan dorikodo fun ẹgbẹ agbabọọlu naa ti wọn si n ti inu ijakulẹ kan bọ si omiran, Lekan Kingkong ṣalaye pe 'Ìya ti mọ awa Arsenal lara, ẹ o ri nnkan ti mo maa n kọ si ẹyin aṣọ ere idaraya mi, Ewurẹ ni. Itumọ rẹ ni pe Ewurẹ jẹ ẹran ile...'

O ni oun nigbagbọ pe o loju ẹgbẹ agbabọọlu to le gbena woju ikọ Arsenal lọwọ yii ati pe idaniloju wa pe wọn yoo gba ife ẹyẹ kan gboogi ni saa yii.

Ìròyìn tí ayélujára ń gbé nípa ìkọlù àwọn àjèjì ní South Africa le ju bó ṣe rí gan - Agba inaki

Aworan Agba Inaki ni papa iṣire Emirate lasiko to lọ wo ifẹsẹwọnsẹ Arsenal kan.

Oríṣun àwòrán, Screenshot/lekan_kingkong

Gẹgẹbi ẹni to gbe lorilẹede South Africa fun ọpọlọpọ ọdun, BBC News Yoruba bi i leere boya oun pẹlu foju wina idẹyẹsi awọn ọmọ Naijiria to waye lawọn asiko kan lorilẹede South Africa, Agba Inaki ṣalaye pe oun ko le sọ pe eyi ko waye si awọn kan nibẹ ṣugbọn oun ko fi igba kankan doju kọ irufẹ idẹyẹsi bẹẹ.

Bakan naa lo fi kun un pe iroyin okeere ton lekan ju ọkan lọ lọpọ igba ni iroyin ti awọn eeyan maa n gbe nipa idẹyẹsi awọn ajeji lorilẹede South Africa.

Agba Inaki ni oun 'le sọ pe ko le to bi ayelujara ṣe maa n gbe e bi i wi pe gbogbo wa ni wọn ti pa sibẹ'.