Wo àwọn ìpínlẹ̀ tí aráàlú ti fẹ̀sùn aṣemáṣe lẹ́nu iṣẹ́ kan ọlọ́pàá jùlọ ní Naijiria

Awọn ọlọpaa to n mu oluwọde niluu Eko

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Apapọ igba 1,234 lawọn araalu fẹsun aṣemaṣe lẹnu iṣẹ kan awọn ọlọpaa kaakiri Naijiria lọdun 2023.

Ọrọ yii lo jẹyọ ninu atẹjade kan ti ajọ to n ri si aṣemaṣe awọn ọlọpaa lẹnu iṣẹ, Nigeria Police Force's Complaint Response Unit, fi lede.

Ajọ naa ni ida 42% ẹsun ti wọn fi kan awọn ọlọpaa lo waye niluu Abuja ati ipinlẹ Eko.

Gẹgẹ bii ohun ti wọn sọ, igba 276 ni araalu fi ẹjọ ọlọpaa sun nipinlẹ Eko nigba ti wọn fi ẹjọ ọlọpaa sun nigba 252 nipinlẹ.

Wo awọn ipinlẹ to ku ati iye igba ti araalu fi ẹjọ ọlọpaa sun

Ọlọpaa to n ba araalu sọrọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

  • Rivers - Araalu fi ẹjọ ọlọpaa sun nigba 96
  • Delta - Araalu fi ẹjọ ọlọpaa sun nigba 67
  • Abia - Araalu fi ẹjọ ọlọpaa sun nigba 60
  • Imo - Araalu fi ẹjọ ọlọpaa sun nigba 50
  • Edo - Araalu fi ẹjọ ọlọpaa sun nigba 47
  • Enugu - Araalu fi ẹjọ ọlọpaa sun nigba 45
  • Ogun - Araalu fi ẹjọ ọlọpaa sun nigba 36
  • Oyo - Araalu fi ẹjọ ọlọpaa sun nigba 31
  • Anambra - Araalu fi ẹjọ ọlọpaa sun nigba 31
  • Akwa Ibom - Araalu fi ẹjọ ọlọpaa sun nigba 25
  • Kaduna - Araalu fi ẹjọ ọlọpaa sun nigba 24
  • Nasarawa - Araalu fi ẹjọ ọlọpaa sun nigba 21
  • Kogi - Araalu fi ẹjọ ọlọpaa sun nigba 20
  • Kano - Araalu fi ẹjọ ọlọpaa sun nigba 17
  • Cross River - Araalu fi ẹjọ ọlọpaa sun nigba 15
  • Ondo - Araalu fi ẹjọ ọlọpaa sun nigba 13
  • Bayelsa - Araalu fi ẹjọ ọlọpaa sun nigba mejila
  • Ebonyi - Araalu fi ẹjọ ọlọpaa sun nigba mẹwaa
  • Osun - Araalu fi ẹjọ ọlọpaa sun nigba mẹwaa
  • Benue - Araalu fi ẹjọ ọlọpaa sun nigba mẹsan an
  • Kwara - Araalu fi ẹjọ ọlọpaa sun nigba mẹjọ
  • Plateau - Araalu fi ẹjọ ọlọpaa sun nigba mẹjọ
  • Adamawa - Araalu fi ẹjọ ọlọpaa sun nigba mẹfa
  • Niger - Araalu fi ẹjọ ọlọpaa sun nigba marun un
  • Bauchi - Araalu fi ẹjọ ọlọpaa sun nigba marun un
  • Ekiti - Araalu fi ẹjọ ọlọpaa sun nigba meji
  • Jigawa - Araalu fi ẹjọ ọlọpaa sun nigba meji
  • Katsina - Araalu fi ẹjọ ọlọpaa sun nigba meji
  • Kebbi - Araalu fi ẹjọ ọlọpaa sun nigba meji
  • Sokoto - Araalu fi ẹjọ ọlọpaa sun nigba meji
  • Zamfara - Araalu fi ẹjọ ọlọpaa sun nigba kan ṣoṣo

Atẹjade ọhun tun fi han pe ọkunrin ni ida 84% awọn to fi ẹsun kan ọlọpaa nigba to ida awọn obinrin to fi ẹsun kan ọlọpaa jẹ ida 13% amọ ida mẹta ko sọ boya ọkunrin tabi obinrin lawọn.

Lara awọn ẹsun ti wọn fi kan ọlọpaa ni aṣilo ipo, idẹyẹsi awọn obinrin, gbigba owo lọwọ araalu lọna aitọ ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Wayi o, ẹka Complaint Response Unit ileeeṣẹ ọlọpaa ti sọ pe oun ko ni fi ọwọ yẹpẹrẹ mu gbogbo ẹsun ti araalu a fi kan awọn ọlọpaa.