Ǹjẹ́ Améríkà lẹ́tọ̀ọ́ láti kọlu Naijiria lórí ẹ̀sùn tó ń gbé síta pé àwọn kan ń gbogun ti Krìstẹ́nì níbẹ̀?

Oríṣun àwòrán, AFP via Getty Images
Ọpọ ibeere lo ti n ja kiri lori pe n jẹ orilẹede Amẹrika ni agbara lati kọlu orilẹede Naijiria gẹgẹ bii Aarẹ Donald Trump ṣe sọ ṣaaju.
Aarẹ Trump ni oun ṣetan lati gbe igbesẹ yii ti orilẹede Naijiri aba kuna lati fopin si bi iṣẹlẹ iṣekupani awọn kristẹni ṣe wọpọ lorilẹede Naijiria.
Bo ti lẹ jẹ pe ijọba orilẹede Naijiria ti fọhun sita lori ọrọ naa, ti wọn si jẹ ko di mimọ ọrọ ko ri bẹ ati awọn eeyan Naijiria ti n gbe papọ pẹlu ifẹ fun igba pipẹ.
Ofin orilẹede Amẹrika, ori kẹjọ ni ile igbimọ aṣofin Amẹrika ni agbara lati kede ogun, kọ lẹta Margue ati Reprisal, ki wọn si tun ṣe ofin to da lori igbigba ilẹ ati omi.
Gẹgẹ bii United Nations Charter se ṣalaye, igbimọ to n risi eto aabo le jiroro lori igbesẹ ti wọn yoo gbe lati fi da alaafia pada si orilẹede kankan ti alaafia ba jina si.
Isọri 39 ti Charter sọ pe "igbimọ aabo yoo se iwadii nipa iṣoro to n da alaafia orilẹede laamu, ti wọn yoo si jiroro lati wa ọna abayọ ni ilana ti ofin agbaye gbe kalẹ.
Ajọ UN ko fọwọ si ilu agbara ati ohun ija lori orilẹede mii ayafi to ba jẹ fun idabobo ilu.
Ipade yoo waye laipẹ laaarin Tinubu ati Trump- Oludaramọran Aarẹ Tinubu
Ọkan lara oludamọran pataki fun Aarẹ Bola Tinubu, Dainel Bawa ti ni ipade nla yoo waye laipẹ laaarin Aarẹ orilẹede Naijiria, Bola Tinubu ati Aarẹ orilẹede Amẹrika, Donald Trump.
Bawa ni ohun kana lo jẹ awọn aarẹ mejeeji logun, iyiun kikoju iṣoro eto aabo ati eyikeyi iwa to tẹ ẹtọ ọmọniyan mọlẹ lawujọ.
Ninu ọrọ to gbe soju opo ayelujara X, Bawa tẹnumọ pe ọpọ igba ni Aarẹ Trump ti ṣe iranlọwọ fun orilẹede Naijiria nipa bibọwọlu ohun ija fun tita wa si Naijiria, ti Aarẹ Tinubu si lo anfani naa lati koju iwa igbesunami.
"Ọpọ ẹri wa pe Aarẹ Tinubu lo anfani to ri gba lati ọwọ orilẹede Amẹrika fi koju iṣoro eto aabo.
"Nipa pe awọn Kristẹni ni awọn agbebọn n kọlu lorilẹede Naijiria yoo jẹ ohun ti awọn olori mejeeji yoo ma sọrọ nipa laipẹ yii boy ani ile ijọba Naijiria tabi ti orilẹede Amẹrika, White House."
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Trump lérí láti kógun wọ Nàìjíríà lórí ẹ̀sùn tó ń gbé síta pé àwọn kan ń gbogun ti Krìstẹ́nì níbẹ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Aarẹ Amẹrika, Donald Trump ti leri lati ko ogun wọ Nàìjíríà lat fina mọ awọn agbesunmọni to ni wọn on doju kọ awọn Kristẹni nibẹ, gẹgẹ egbi atẹjade kan to fi sita loju opo ayelujara.
Trump tun fẹsun kan ijọba Naijiria pe wọn faye gba iṣekupani awọn Kristẹni.
Ninu ọrọ to gbe sita soju opo ikanni Truth rẹ lọjọ Satide, Trump ni ileeṣẹ ologun Amẹrika le wọle si Naijiria pẹlu awọn ọmọ ologun lati kọlu awọn to pe ni alakakiti agbesunmọmi alakatakiti ẹsin islam to ni wọn n ṣekupa awọn Kristẹni ni Naijiria.
Bakan naa lo tun leri oun yoo dawọ gbogbo iranwọ ti Amẹrika nnfi ṣọwọ si Naijiria duro..
Ijọba Naijiria ti fesi si iẹsun ti Trump fi kan an naa, to sì tọka i toksii gẹgẹ eg bi iroyin ẹlẹjẹ ati ahesọ ọrọ ti ko l'ẹsẹ nlẹ rara.
Trump tẹsiwaju ninu atẹjade naa pe oun ti paṣẹ fun awọn ẹka ologun ilẹ Amẹrika lati bẹrẹ igbesẹ tako orilẹede Naijiria- "bi ijọba Naijiiia ba tun daba to ba faye gba iṣekupani awọn Kristẹni,".
Ni Ọjọ Ẹti, Trump gbe soju opo ayelujara pe "ọpọ ọmọ lẹyin Kristi ni wọn padanu ẹmi wọn ni Naijiria, to si jẹ awọn agbebọn Islam lo wa nidi rẹ," lai pese ẹri kankan.
Awọn oloṣelu Amẹrika kan lo kọkọ gbe ọrọ naa jade lati fẹsun kan ijọba Amẹrika.
Bakan naa ni oṣu kẹwaa, Sẹnetọ Ted Cruz ati Riley Moore fẹsun kan ijọba Naijiria pe wọn lọwọ ninu bi awọn agbebọn se n ṣekupa awọn kristẹni lorilẹede Naijiria.
Kí ló túmọ̀ sí bí Trump ṣe kéde Nàìjíríà gẹ́gẹ́ bíi orílẹ̀ èdè tí ọ̀pọ̀ Krìstẹ́nì ti ń pàdánù ẹ̀mí?

Oríṣun àwòrán, EPA
Aarẹ orilẹede Amẹrika, Donald Trump ti kede sita pe oun yoo ka orilẹede Naijiria mọ awọn orilẹede to n kọ oun lominu nitori ẹsun pe ọpọ kristẹni n padanu ẹmi wọn.
Ninu atẹjade to gbe soju opo Truth Social platform, Trump ni eyi jẹ igbesẹ kekere ti oun ni lati kọkọ gbe.
"Awọn Kristẹni n koju ọpọ idunkoko ni Naijiria," o sọ . " Ọpọ Kristẹni lo n padanu ẹmi wọn, to si jẹ pe eyi n waye lati ọwọ awọn ajijagbara ẹsin Islam. Idi ree ti mo fi kede Naijiria gẹgẹ orilẹede to n kọmilonu."
Ni afikun, Trump ni oun ti palaṣẹ fun awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin Amẹrika, Riley Moore ati Tom Cole lati bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ yii, ki wọn si wa fun oun ni abọ iwadii wọn.
Ni ibẹẹrẹ oṣu yii, Sẹnẹtọ Amẹrika kan fẹsun kan orilẹede Naijiria pe ọpọ Kristẹni n padanu ẹmi sọwọ awọn agbebọn lorilẹede Naijiria, ẹsun ti ijọba Naijiria wọgile.
Ki ni eyi tumọ si?
Iroyin to n tẹ wa lọwọ lati orilẹede Amẹrika ṣalaye pe orilẹede ti ijọba Amẹrika ba ka gẹgẹ orilẹede 'Country of concern' lo tumọ si pe ko faye gba ẹsin kan lorilẹede naa, eyi to tapa si ofin International Religious Freedom Act (IRFA), ti ọdun 1998.
Bakan naa ni o ṣeese ki orilẹede naa koju awọn ijiya to ni ṣe pẹlu eto ọrọ aje lasiko ti Amẹrika ka wọn orilẹede 'Country of concern'.
Ninu ifọrọwerọ pẹlu BBC, onimọ nipa eto aabo Afrika, Bulama Bukarti ni ijiya mẹta ni orilẹede Naijiria le koju lati ọwọ Amẹrika.
O ṣalaye wọn;
Orilẹede Amẹrika yoo fopin si tita ohun ija fun orilẹede Naijiria.
Bulama Bukarti ni "ti wọn ba le fi di iṣẹlẹ yii mulẹ, Amẹrika ati awọn alabaṣepọ rẹ yoo fopin si tita ohun ija fun Naijiria ".
Eyi ko yọ awọn ohun ija bii ọkọ ofurufu ati ohun ti awọn ologun nilo lati fi koju awọn eto aabo to mẹhẹ.
Eto ọrọ aje
Onimọ nipa eto aabo ni ọna miiran ti orilẹede Amẹrika fi le fi iya jẹ Naijiria ni ki wọn tun fopin si ajọsepọ wọn lori ọrọ aje.
O ni, "Wọn ko ni ra epo rọbi mọ lọwọ Naijiria, wọn ko si ni ta ọja mọ fun orilẹede Naijiria,"
Naijiria jẹ orilẹede kan to n pa owo wọle latari bi o ṣe n ta epo rọbi fun awọn orilẹede lagbaye, to si tun jẹ orilẹede to n ko ọpọ ẹru wọle lati awọn orilẹede agbaye.
Ni ọdun 2021, ijọba Amẹrika yọ orukọ Naijiria kuro ninu awọn orilẹede 'Country of concern'.
Ijọba orilẹede Naijiria fesi si ẹsun Donald Trump
Ijọba orilẹede Naijiria ti sọrọ lori ọrọ ti Aarẹ orilẹede Amẹrika, Donald Trump sọ nipa eto aabo orilẹede Naijiria, to si ni oun fi orilẹede Naijiria sinu orukọ awọn orilẹede 'Country of concern'
Ninu atẹjade to fi lede, agbẹnusọ fun ajọ to n risi eto iroyin lorilẹede Naijiria, Kimiebi Imomotimi Ebienfa, anipr ni orilẹede Naijiria dupẹ lọwọ agbaye bi wọn se da si eto aabo to mẹhẹ ṣugbọn o ṣe koko ki agbaye mọ pe ọrọ naa ko ri bi awọn kan ṣe gbe sita.
"Ọpo Ọmọ orilẹede Naijiria lo ti n gbe papọ fun ọpọ ọdun ọdun, ti wọn si n jọsin papọ pẹlu alaafia.
"Labẹ idari Aarẹ Bola Ahmed Tinubu, Naijiria tunbọ gbajumọ kikoju eto aabo to mẹhẹ, ati lati mu ajọsepọ dan mọran ati dida bobo ẹmi ati dukia araalu orilẹede Naijiria.
Ebienfa ni Naijiria yoo ba awọn ijọba Amẹrika sọrọ lori ọrọ naa ati lati je ki wọn ni oye nipa ohun to n sẹlẹ lorilẹede Naijiria.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2















