"Mo ní ìjàmbá ọkọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ọlọ́pàá, n kò le rìn mọ́, mo ná N25m ẹ̀yáwó báńkì lórí àárẹ̀, iléeṣẹ́ ọlọ́pàá kò yà sí mi, ìran mi kò lè ṣe iṣẹ́ ọlọ́pàá mọ́"

Àkọlé fídíò, Ọlọ́pàá tó wà lórí àárẹ̀
"Mo ní ìjàmbá ọkọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ọlọ́pàá, n kò le rìn mọ́, mo ná N25m ẹ̀yáwó báńkì lórí àárẹ̀, iléeṣẹ́ ọlọ́pàá kò yà sí mi, ìran mi kò lè ṣe iṣẹ́ ọlọ́pàá mọ́"

Ọdún 1986 ni ọ̀gbẹ́ni Adegbehin Adetarami darapọ̀ mọ́ iṣẹ́ ọlọ́pàá pẹ̀lú ìrètí láti ṣiṣẹ́ sin àti dá ààbò bo orílẹ̀ èdè bàbá rẹ̀.

Ó ṣiṣẹ́ sin orílẹ̀ èdè bàbá rẹ̀ títí tó fi gòkè wọ ipò adarí ìpínlẹ̀ èyí tí a mọ̀ sí Commandant.

Ọdún 2021 ló yẹ kó fẹ́yìntì lẹ́nu iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọmọ ọ̀dọ̀ rere ṣùgbọ́n ìṣẹ̀lẹ̀ ńlá kan ṣẹlẹ̀ si tó da ìrìnàjò rẹ̀ rú.

Adetarami bá ìjàmbá ọkọ̀ pàdé lọ́dún 2017 nígbà tó ń ṣe ìrìnàjò lọ sí ìlu Abuja láti lọ kópa níbi ìpàdé kan tí ọ̀gá àgbà iléeṣẹ́ ọlọ́pàá nígbà náà, Ibrahim Idris Kpotum pè.

Kpotum pe ìpàdé pẹ̀lú gbogbo àwọn olórí àwọn iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ ní èyí tí Adetarami náà yóò sì kópa níbẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀gá àgbà iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ti ìpínlẹ̀ Akwa Ibom ìgbà náà.

Adegbehin Adetarami wọ asọ isẹ ọlọpa ninu aworan meji,o si de fila alawọ ewe ati alarabara ninu ikọọkan aworan naa.

Oríṣun àwòrán, Adegbehin Adetarami

Láti ìgbà náà sì ni Adetarami ti ń kojú ìpèníjà kan sí òmíràn lórí ìlera, tó sì jẹ́ pé orí ibùsùn kan ló wà báyìí níbi tó ti ń jẹ, mù, tó sì jẹ́ pé ibẹ̀ náà ló ti ń ṣe ìgbọ̀nsẹ̀.

Adetarami sọ fún BBC pé bíi oṣù mẹ́rin ni òun lò ní ilé ìwòsàn nígbà tí ìjàmbá náà wáyé, tí òun sì ná tó owó tó lé ní mílíọ̀n mẹ́sàn-án náírà láti fi ṣe ìtọ́jú ara òun.

Ó ní iléeṣẹ́ ọlọ́pàá kò ṣe ìrànwọ́ kankan tàbí fún òun lówó láti fi ṣe ìtọ́jú ara òun lórí ìjàmbá náà.

Ó ṣàlàyé pé lẹ́yìn oṣù mẹ́rin ni ilé ìwòsàn dá òun sílẹ̀ láti máa lọ sílé nítorí kò sí owó lọ́wọ́ òun mọ́ àmọ́ òun ní àlááfíà díẹ̀ nítorí òun ṣì lè rìn, tí òun sì ń wa ọkọ̀.

Ó sọ pé ilé ìwòsàn náà sọ fún òun láti máa wá fún àyẹ̀wò lóòrè kóòrè èyí tí òun ń lọ títí di ọdún 2020 kí àìsàn covid 19 tó gbòde.

Ọdún mẹ́rin ni Adetarami tún lò sí i lẹ́nu iṣẹ́ ọlọ́pàá kó tó di pé ó fẹ́yìntì lọ́dún 2021.

Adegbehin Adetarami wọ asọ ọlọpaa, o n gba ami ẹyẹ lọwọ ọkunrin kan to wọ asọ kootu dudu, to si n bọ ọ lọwọ nigba to n gbe ami ẹyẹ naa fun. Bakan naa, awọn osisẹ ọlọpaa meji miran, ti wọn wọ asọ ọlọpaa naa wa nibẹ pẹlu.

Oríṣun àwòrán, Adegbehin Adetarami

'Àwọn ọmọ mi kò lè lọ sílé ẹ̀kọ́ mọ́, gbèsè tó lé ní mílíọ̀nù márùndínlọ́gbọ̀n náírà ni mo jẹ àwọn ilé ìfowópamọ́'

Adetarami ní ọ̀pọ̀ ìlàkàkà ní òun là kọjá nídìí iṣẹ́ ọlọ́pàá, bó ṣe jẹ́ pé ojú ọgbẹ́ ìbọn wà lára òun lásìkò tí òun lọ kojú àwọn adigunjalè nígbà tí òun ṣì wà lẹ́nu iṣẹ́.

Ó ní òun sọ fún iléeṣẹ́ ọlọ́pàá nípa àìlera òun ṣùgbọ́n wọn kò yà sí òun.

Ó fi kun pé owó tí òun ń gbà gẹ́gẹ́ bí owó ìfẹ̀yìntí pẹ̀lú ipò supiritẹndẹẹti ọlọ́pàá ló jẹ́ N47,900 tí kò sì ran nǹkankan lórí àìsàn tó ń ṣe òun.

Ó sọ pé gbogbo àjẹmọ́nú tí wọ́n fùn òun nígbà tí òun fẹ̀yìntì kò pé mílíọ̀nù mẹ́ta náírà tó sì jẹ́ pé orí àìsàn náà ni òun na sí.

Adetarami wá ń rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Nàìjíríà àti àjọ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ àwọn ọlọ́pàá láti jọ̀ ọ́ jàre bu ojú àánú wo òun kí òun má bà á àìsàn náà lọ.

Ó ní òun kò rí owó san owó ilé ẹ̀kọ́ àwọn ọmọ òun san mọ́, tí gbèsè tí òun jẹ́ àwọn ilé ìfowópamọ́ sì ti lé ní mílíọ̀nù márùndínlọ́gbọ̀n tí òun kò sì ní ọ̀nà kankan láti fi san wọ́n padà.

Ó ń rọ ìjọba láti ran òun lọ́wọ́ kí òun má kù ú sórí àìsàn náà.

BBC News Yorùbá kàn sí àjọ tó ń rí sí ìgbáyégbádùn àwọn ọlọ́pàá ṣùgbọ́n wọn kò fèsì sí ìbéèrè wa.