Agba Inaki sọ pé làásìgbò to ń wáyé ní South Africa pẹ̀lú àwọn ẹ̀yà mìí kò tó bí wọ́n ṣe ń pariwo rẹ̀

Agba Inaki

Oríṣun àwòrán, Lekan King-kong/Instagram

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ilumọọka adẹrinposonu nni, Olalekan Olaleye, ti ọpọ eeyan mọ si Agba Inaki ti salaye pe, ọmọ lile ni oun ni kekere, ti oun si korira ki ẹnikẹni pa oun lẹnu mọ.Agba Inaki, lasiko to n kopa lori eto kan lori ikanni BBC Yoruba tun sisọ loju rẹ pe, ọmọ bibi ilu Ogbomoso ni oun, ti ẹru kankan kii si ba oun.

Skip Facebook post

Content is not available

View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.

End of Facebook post

"Ọmọ ti yoo ba jẹ Asamu, kekere ni yoo ti maa jẹ ẹnu samusamu, lati kekere ni mo ti nifẹ ede Yoruba, mo maa n beere ibeere pupọ, ti sisọ ati kika ede Yoruba si jẹ irọrun fun mi."

Adẹrinposonu naa, to kẹẹkọọ nipa akoso okoowo nile ẹkọ fasiti aladani kan nilu Oyo tun ni, wọn le oun kuro nile ẹkọ fasiti kan Ilorin, ki oun to gba ile ẹkọ fasiti aladani lọ.

" Ọga agba nile ẹkọ Fasiti Ilorin nigba naa, Ọjọgbọn Abdulraman Oloyede lo paṣẹ pe a ko gbọdọ lọ sibi apejẹ mọ bii akẹkọọ.

Emi ati awọn ọrẹ mi ko gba, a gba ile ijo lọ, ti ọwọ si tẹ wa, eyi to mu ki wọn le wa kuro nile ẹkọ fasiti naa, lati fi wa jofin fawọn akẹkọọ yoku."

" Aye su mi, ọna mi daru, mo sọkun, ọkan mi poruru, mo ro pe ohun gbogbo ti tan fun mi. Ṣugbon iya mi duro ti mi, mo lọ sile ẹkọ fasiti miran to jẹ aladani, mo kawe, mo si pinnu lati ṣe aṣeyọri nibẹ, eyi to see ṣe.

Agba Inaki wa n rọ awon eeyan to ni iru ipenija bayii, tabi ti wọn wa ni ikorita 'ko ye mi mọ', pe ki wọn ṣe suuru, ki wọn si gba pe ti ẹmi ba wa, ireti n bẹ."

Nigba to n salaye ohun to gbe de orile-ede south Africa to tẹdo si bayii, agba Inaki ṣalaye pe "Bi mo ṣe pari ẹkọ Fasiti, ti mo lọ sinru ilu ni iya mi ku, ba si ṣe sin oku tan, ti mo pari agunbanirọ, ni mo tẹle ọrẹ mi lọ si orílẹ̀ ede south Africa, lati pa ironu rẹ"

"A bẹrẹ si ran aṣọ ta, sugbọn a ti pa iṣẹ naa ti bayii, ta si tun mu orin kikọ ni ibaada, ede Yoruba ni emi n lo, ti awọn eeyan si tun maa n gbadun mi."

Agba Inaki ni ko rọrun rara nigba ti oun kọkọ de South Africa sugbọn oun dupẹ pe oun ri ọna abayọ bayii.

" Mo n ṣe Alakoso eto ayẹyẹ taa mọ si MC, mo tun n kopa ninu okoowo epo robi, mo tun n da oko ọgbin alada nla ni Naijiria ti ẹgbọn mi n ba mi mojuto, mo n ṣe ere tiata, ti mo si tun maa n sọrọ iwuri nibi agbekalẹ eto."

Agba Inaki wa gba awọn eeyan to ba n gbero lati rinrin ajo kuro ni Naijiria lọ soke nimọran pe, ki wọn ni ara wọn na, ki wọn to sọ pe awọn ni eeyan, tabi gbara le ẹnikẹni fun iranwọ loke okun.

" Mo n rọ awọn eeyan wa lati mọ riri ohun ti awọn ara oke okun ba fi ransẹ si wọn nile nitori ko rọrun rara fun ara oke okun naa lati to tu owo jọ, to si rọ awọn to wa loke okun pẹlu lati fi ẹsọ ṣe.

Àkọlé fídíò, Yollywood: Sinimá Ajé Ọjà tún so Fathia àti Saheed Balogun pọ̀ nínú Sinimá

Nigba to n sọrọ lori ibi ti imisi ti n wa nipa awọn fidio to maa n fi si ori ayelujara, agba Inaki ni iriri ti oun ba ri ni awujọ ni oun maa n fi ṣe ọrọ isiti, ti awọn eeyan si maa n fi fidio ransẹ si oun nigba miran.

Agba Inaki to ni oun ko tii ṣe igbeyawo tun sọ pe, Kristẹni pọnbele ni oun amọ oun kan maa n fi ẹsẹ ifa ṣe ẹfẹ ni.

"Mo ti kopa ninu awọn ọpọ sinima, ti mo si tun n ṣiṣẹ takuntakun bayii ninu isẹ tiata, ti mo si ti n po sinima kan pọ, ti ko ni pe jade sita bayii."

Nigba to n sọrọ lori ajọṣepọ ti ko dan mọran, to maa n waye laarin awọn ọmọ Naijiria ati awọn ọmọ ilẹ South Africa, agba Inaki ni aimọkan lo n ba awọn ọmọ ilẹ South Africa naa ja, ti wọn ṣe n kọju ija si awọn alejo.

O fikun pe aawọ laarin awọn ọmọ Naijiria ati awọn ọmọ South Africa ko le to bi wọn ṣe n pariwo rẹ nitori ko fi bẹẹ tan kaakiri, koda, o ni laasigbo naa ko de ibiti oun wa ri.

Lori ajakale arun Coronavirus ati ọrọ aje agbaye to dagun eyi ti ko yọ South Africa to wa silẹ, agba Inaki ni ijọba ilẹ naa ti ṣeto owo iranwọ fun awọn olokoowo alabọde lati se gbera sọ, bẹẹ lo ni ko fẹẹ si alaini ti kó ri ọwọ ijọba nibẹ.

Nigba to wa n sọrọ lori ilana ti ijọba Naijiria n lo lati pin owo iranwọ fun igbele Coronavirus, eyi to ni ko de ọpọ ibi to yẹ ko de, agba Inaki ni "ijọba ko pese ohun elo igbaye-gbadun fun araalu lati ibẹrẹ pẹpẹ, lo mu ko nira fun wọn lati lee ṣe awari araalu to nilo iranwọ."

O wa rọ ijọba lati mu ipese awọn ohun elo amayedẹrun fun araalu nibaada, ko si pese iṣẹ fun awọn ọdọ, eyi ti yoo mu ko rọrun fun wọn lati tete yanju isoro lasiko to ba de.

Mercy Aigbe kò mọ ọ̀dá owó, ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tuntun ló fà yọ lásìkò Coronavirus

Oṣere Mercy Aigbe

Oríṣun àwòrán, Instagram/Mercy Aigbe

Wọn ni ohun to kọju si ẹnikan, ẹyin lo kọ si ẹlomiran bii ilu gangan, bẹẹ lọrọ ri pẹlu gbajumọ oṣere tiata, Mercy Aigbe, ti dukia rẹ tun lekan si.

Idi ni pe bi ọpọ eeyan ṣe n pariwo pe ilu le, ko si owo lode lasiko Coronavirus yii, ti ọpọ awọn oṣere tiata ko si ri iṣẹ ṣe, eyi ko kan Aigbe nitori o ṣẹṣẹ ra ọkọ ayọkẹlẹ tuntun kan ni.

Mercy ni "lẹyin ọpọ arọwa pupọ, ọlọla julọ lobinrin ti dara pọ mọ awọn isọri eeyan to n lo ọkọ ayọkẹlẹ ọbọkun ọlọyẹ Benz."

Fọto rẹ ati ọkọ ayọkẹlẹ pupa naa si lo gbe soju opo Instagram rẹ ọhun, ti ọpọ awọn ololufẹ ati akẹẹgbẹ rẹ ninu iṣẹ tiata si n ki ku oriire ọkọ ayọkẹlẹ tuntun naa.