Lágbo tíátà lọ́sẹ̀ yìí, Femi Adebayo di àgbà àáfà òníláwàní, Iyabo Ojo fi sìgá dárà, Allwell Ademola di ọmọdé padà, tí Wazo si bímọ tuntun.

femi adebayo

Oríṣun àwòrán, femi adebayo

Yoruba ni oju to ba dilẹ, ohun ni rorẹ n sọ. Bẹẹ lọrọ ri pẹlu awọn oṣere tiata lasiko igbele Coronavirus yii, ti ọpọ wọn ko ri oko ere tiata lọ.

Ni ọsẹ yii, oniruuru àrà ni awọn gbajumọ oṣere tiata ọhun da loju opo Instagram koowa wọn, koda, ọpọ wọn lo pa ni lẹrin, ta si mu diẹ ninu rẹ wa fun yín.

Awọn awada ori ayelujara ti ọpọ oṣere tiata ṣe lọsẹ yii :

Femi Adebayo di agba aafa onilawani:

femi adebayo

Oríṣun àwòrán, femi adebayo

Femi Adebayo, ti awọn eeyan kan tun n pe ni Jelili oniso, lo di agba aafa musulumi loju opo Instagram rẹ lọsẹ yii, bo si ṣe n ṣe waasi, naa lo n da orin waka lati kilọ iwa.

Femi, ẹni to daju pe o n sin agba aafa kan jẹ ni, lo wọ agbada buluu gbagẹrẹ, to si we lawani sori, nigba ti obinrin kan, ti oun naa jẹ osere tiata rẹ, ṣe bii dadani fun.

Wazo bi ọmọkunrin tuntun:

Wazo

Oríṣun àwòrán, others

Gbajugbaja oṣere tiata lọkunrin kan, Owokoniran Razak, ti ọpọ eeyan mọ si Wazo, ni ọba oke fi ọmọkunrin lanti lanti ta lọrẹ ni aarin ọsẹ yii, ti awọn akẹẹgbẹ rẹ si n ki ku oriire.

Wazo funra rẹ si lo kede ayọ ọmọ tuntun ọhun loju opo Instagram rẹ @wazothefirst, to si fi fọto ọmọ tuntun naa sibẹ pẹlu.

Iyabo Ojo fi siga dara:

Lizzy anjorin

Oríṣun àwòrán, others

Ẹrin arintakiti ni loju opo Instagram pẹlu fidio kan ti Iyabo Ojo ṣe, to fi n sin awọn janduku jẹ.

Iyabo, lo wọ aṣọ bii ọmọ ìsọta, to si kẹ ohun rẹ, o n sọrọ bii janduku, to si n fa siga.

Allwell Ademola di ọmọde pada:

Allwell

Oríṣun àwòrán, others

Ara ọwọ awọn oṣere tiata to dilẹ, ti sọ awọn gbajugbaja oṣere tiata kan, ninu eyi taa ti ri Allwell Ademola di ọmọde pada.

Oṣere tiata lobinrin naa lo ṣe amulo ẹrọ igbalode kan lati sọ ara rẹ di ọmọde pada, ẹni tí ko ba si wo daadaa, ko ni mọ pe oun ni, nitori isọrọ ati oju rẹ to jọ ti ọmọde

Lizzy Anjorin ati Kemi Korede ṣe afihan fọto igba ewe wọn :

Lizzy anjorin

Oríṣun àwòrán, others

Ọkan lara igbesẹ idanilaraya to n waye lati ọdọ awọn oṣere tiata ni afihan fọto igba kekere ọpọ wọn.

Ninu ọpọ fọto naa la ti mọ bi diẹ lara awọn oṣere tiata naa ṣe ri ni ọdọ, ọpọ wọn si ni ko ni omi lara nigba naa, yatọ si bi wọn ṣe ri bayii.

Koda, awọn fọto igba ewe wọn yii si lo jẹ kí araye mọ pe ọmọ dudu ni wọn amọ ti ọpọ wọn ti di oyinbo bayii.