Ooni of Ife: Ọ̀wọ́ Ọlọ́pàá ti tẹ arákùnrin tó fi tipá wọ ààfin Ọ̀ọni ilé ifẹ̀

Awoku ọkọ naa

Oríṣun àwòrán, Amiloaded media hub

Ni alẹ ọjọ Iṣẹgun ni awọn eeyan ilu Ile ifẹ ni awọn gbọ iro ibọn ni kikankikan ni ile Oodua tii ṣe aafin Ọọni ile ifẹ, Ọba Adeyẹye Ogunwusi eleyi to mu ki ọpọlọpọ awọn eeyan ilu iṣẹmabaye naa o maa ko aye soke lori alaafia Ọọni Adeyẹye Ogunwusi ni.

Iro ibọn naa ni wọn ni o dun fun iṣẹju diẹ ki o to dakẹ.

Nigba ti gbogbo rẹ yoo fi rọlẹ ni iroyin jade pe awọn eeyan mẹta kan gbiyanju lati fi ipa wọ aafin ninu ọkọ ayọkẹlẹ kan. Nigba ti wọn de iloro akọkọ ni aafin Ọọni ni awọn ẹṣọ beere ohun ti wọn wa ṣe ti meji ninu wọn si bẹ silẹ ninu mọto ti wọn si fi ẹsẹ fẹẹ.

Ẹni kẹta wọn to wa ọkọ naa ni wọn ni o fi ọkọ naa ja iloro kini ati ikeji pẹlu erongba lati wọ iloro kẹta nibi ti Kabiyesi arole Oodua, Ọọni Ogunwusi n gbe ṣugbọn awọn agbofinro to n ṣọ aafin naa ba ya boo.

Ọkan lara awọn iloro ti o kọlu

Oríṣun àwòrán, Amiloaded media hub

Gẹgẹ bi ọrọ ti alakoso ọrọ iroyin fun Ọọni, Kọmureedi Ọlafare ṣe ṣalaye fun BBC News Yoruba, Aja kan ti wọn ni arakunrin naa gbe sinu ọkọ ti o si tu silẹ ni awọn agbofinro n le kiri.

Iro ibọn ti wọn si n yin si aja naa nibi ti wọn ti n lee kiri lawọn araalu gbọ ti wọn si n lero pe boya awọn adigunjale lo wọ aafin.

Iwaju ọkọ naa

Oríṣun àwòrán, Amiloaded media hub

Arakunrin naa ni wọn ni o wa ni ahamọ awọn ọlọpaa bayii ti iroyin si n jẹ ko di mimọ pe o ti ba wọn lalejo ni ẹka ọtẹlẹmuyẹ ileeṣẹ ọlpaa ni Oṣogbo.

Ninu ọrọ to ba ileeṣẹ iroyin kan ni ilu Ọṣogbo sọ, alukoro fun ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ọṣun, ASP Yẹmisi Ọpalọla, salaye wi pe darukọ arakunrin naa gẹgẹ bi Daramọla Wasiu.

line

Ooni of Ife: Inú ayọ̀ àti ìdùnú ni èmì àtí Ọoni wa, ǹkankan kò ṣe ìgbéyàwó wa- Olorì Naomi

Naomi

Oríṣun àwòrán, INSTAGRAM

Àkọlé àwòrán, Ọdun 2018 ni Ooni ti Ile Ifẹ, Oba Adeyeye Ogunwusi gbe Olori Naomi Silekunola Ogunwusi ni iyawo.

Olori Naomi Silekunola Ogunwusi ti bu ẹnu atẹ lu iroyin ofege to sọ wi pe igbeyawo oun ati Ooni ti Ile Ifẹ, Oba Adeyeye Ogunwusi ti fori sanpọn.

Olori Naomi to ni ko si otitọ kankan ninu iroyin yin sọ loju ẹrọ ikansiraẹni Instagram rẹ pe oun ko ko kuro ni ile Ooni.

Olori ni ayọ ati idunnu ni oun ati Ooni fi n lo igbeyawo wọn lai si pe wọn ni ariyanjiyan kankan laarin wọn.

O fikun pe awọn ọta to fẹ ki igbeyawo awọn daru lo n gbe iroyin naa kaakiri wi pe igbeyawo naa ti fori sanpọn.

Amọ Olori ni okun to sọ igbeyawo awọn papọ le ju ohun ti ọta tabi awọn eni ibi le e ja lọ.

Bakan naa ni Olori ni arun Coronavirus ti ohun kọ oun lominu lo jẹ ki oun kurọ lori ẹrọ ayelujara fun igba diẹ lati le e gbadura nipa ohun to n sẹlẹ lagbaye.

Naomi

Oríṣun àwòrán, Instagram

Olori naa ni asiko arun Coronavirus yii pe fun ironujinlẹ, ti kii si ṣe fun afẹfẹ yẹyẹ nitori ọpọ ẹmi lagbaye lo n lọ si iṣẹlẹ yii.

Ọdun 2018 ni Ooni ti Ile Ifẹ, Oba Adeyeye Ogunwusi gbe Olori Naomi Silekunola Ogunwusi ni iyawo.

line

Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ 'ọba alayé' àti ọmọ rẹ̀ tó fi ipá bá ọmọ ọdún mẹ́rìnlá lòpọ̀ l'Ọ́ṣun

Ọwọ titẹ ọba alaye kan, Ọba David Ogungbemi ati ọmọ rẹ, Idowu, fun pe wọn fi ipa ba ọmọbinrin, ọmọ ọdun mẹrinla kan lopọ.

Ọba naa ni oriade ilu Iketewi, to wa ni ijọba ibilẹ Obokun, nipinlẹ Osun.

Obinrin to n bọ pata

Oríṣun àwòrán, María Conejo/BBC

A gbọ pe ọmọbinrin naa n gbe pẹlu aburo baba rẹ, Esther Ogungbemi, nilu Ilare, to wa ni ijọba ibilẹ naa.

Iroyin sọ pe ibalopọ tipa-tipa naa di oyun, eyi to mu ki baba rẹ lọ ọ fi ẹjọ sun ni agọ ọlọpaa.

Ṣugbọn nigba to n sọrọ, alukoro fun ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Osun, Opalola Yemisi, sọ fun BBC pe lootọ ni iṣẹlẹ naa waye, ṣugbọn ko si ẹni to jẹ ọba ninu awọn mejeeji ti wọn fi ẹsun kan.

"Ohun to han si ileeṣẹ ọlọpaa ni pe baba ati ọmọ ni wọn, awọn mejeeji lo si fi ipa ba ọmọ ọdun mẹrinla naa lopọ."

Bakan naa lo sọ pe ileeṣẹ ọlọpaa ti pari iwadii lori ọrọ wọn, wọn si ti gbe wọn lọ sile ẹjọ.

Àkàndá ẹ̀dá fipá lòpọ̀ pẹ̀lú ọmọ ọdún mẹ́rìnlá, tó sì di óyún

Aworan obinrin ti wọn fun l'ọrun

Oríṣun àwòrán, Others

Afurasi kan, Samuel Eze, to jẹ akanda ẹda, ti wọ panpẹ ọlọpaa lẹyin ti wọn fẹsun kan an pe, o fipa ba ọmọ ọdun mẹrinla kan lopọ, to si fun loyun ladugbo Oshodi nipinlẹ Eko.

Oyun naa ti pe oṣu marun un bayii.

Adari ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ si ọmọde ni ijọba ibilẹ Oshodi-Isolo, Ebenezer Omejalile ni, afurasi naa wa ni ahamọ ileeṣẹ ọlọpaa Akinpẹlu, ni Oshodi bayii.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O salaye wipe, Eze to n gbe adugbo Arowojọbẹ ni Oshodi, ran ọmọbinrin naa niṣẹ nitori pe o jẹ alaabọ ara nigba to fipa ba lo pọ.

Omejalile ni, ko tii pẹ ti baba ọmọ naa ku ati wipe iya rẹ ṣi wa ninu opo nigba ti afẹsunkan naa ki i mọlẹ.

Àkọlé fídíò, 'Àjẹ́, eégún, kí ni wọn ò pè mí tán tórí Vitiligo lára mi'

O ni nigba ti awọn fi ọrọ wa Eze lẹnu wọ, o ni ọmọ naa funra rẹ, lo gba fun oun.