Ìyàwó: Ọkọ mi kúndùn ìbálòpọ̀ kọjá sísọ lẹ́yìn ìgbeyàwó ogun ọdún

Obinrin to n ro pe ọkọ̀ oun n yan ale

Oríṣun àwòrán, Karen Charmaine Chanakira

Awuyewuye n waye pe, boya awọn kan wa to kundun ibalopọ kọja bo ṣeyẹ. Ọpọlọpọ kii ti lẹ gbagbọ pe, iru awọn eniyan bẹ ẹ wa, ṣugbọn obinrin kan re e ti aṣiri ọkọ rẹ tu si lọwọ lẹyin igbeyawo ogun ọdun.

Bi iṣẹlẹ naa ṣe lọ niyi:

"Mo maa n ro wi pe igbeyawo mi ko ni abuku kankan, nitori pe emi ati ọkọ mi ti mọ ara wa fun ọpọlọpọ ọdun, ka to gbe ara wa ni iyawo. A si ti di tọkọtaya fun bi ogun ọdun, bẹẹ la ti bimọ.

Àkọlé fídíò, Ọdún tó súnmọ́ ìdìbò ni 2022, wọ́n ó ni ta ẹ̀jẹ̀ wa sílẹ̀

Oniṣowo nla ni ọkọ mi, o si maa n rinrinajo loorekoore nitori iṣẹ rẹ. Eyi mu ko jẹ pe emi nikan ni mo n mojuto awọn ọmọ wa, ṣugbọn o maa n wa si ile ni gbogbo opin ọsẹ.

Inu rẹ si maa n dun to ba ti pada sile. Eyi ko tilẹ jẹ ki n fura pe nkankan ṣajoji ninu igbeyawo wa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ṣugbọn l'ọjọ kan, mo n wa nkankan to gbe mi de ọọfisi rẹ to wa ninu ile wa. Mo ṣakiyesi pe, kọmputa agbeletan rẹ wa ni ṣiṣi silẹ, mi o kọkọ fẹ ẹ wo, nitori kii ṣe aṣa mi lati maa sọ ọkọ mi.

Obinrin to n fi ibanujẹ wo kọmputa agbeletan ọkọ rẹ

Oríṣun àwòrán, Karen Charmaine Chanakira

Amọ, atẹranṣẹ ori ẹrọ ayelujara rẹ wa ni ṣiṣi silẹ, ọkan lara rẹ fa oju mi mọra; mo ri pe o ti sanwo ile itura kan silẹ nilu London. Ile itura kẹ?

Mo n gbaradi lati rinrinajo igbafẹ pẹlu awọn ọrẹ mi l'asiko naa, ọjọ to si fẹ ẹ lọ sile itura naa jẹ ọjọ keji ọjọ ti mo fẹ rinrinajo. Eyi tubọ jẹ ki ara o maa fu mi.

Mo ro o titi, ko kuro l'ọkan mi titi ti mo fi beere lọwọ rẹ laarin oru. Ṣugbọn, ko fun mi ni esi kankan fun bi i ọgbọn iṣẹju. Lo ba dahun pe, oun ṣẹmi, ki n dariji oun.

Dariji kẹ? Niṣe ni mo fi ibinu kuro ninu yara ibusun wa, ti mo si lọ si yara igbalejo.

Takọ-tabo lori ibusun

Oríṣun àwòrán, Karen Charmaine Chanakira

Ko pẹ pupọ lo wa a ba mi, to si bẹrẹ si ni bẹbẹ pe ki n dariji oun.

O jẹwọ pe, oun maa n lọ si awọn ile ijo ti awọn eniyan ti maa n bọ ara wọn si ihoho, ti oun si pade ọmọbinrin onijo kan nibẹ.

Ati pe awọn ti di ọrẹ, eyi si lo mu ki oun gba yara nile itura, ki ọrẹ awọn le ba a gbooro si.

Àkọlé fídíò, Ayàwòrán Obama: Ọ̀pọ̀ ìgbà ni èmi àti ìyá mi pa èbi mọ́nú kí n tó jẹ́ èèyàn

Nkankan sọ fun mi pe wọn ti ni ibalopọ, ṣugbọn ko jẹwọ.

Mo lọ si rinajo mi, pẹlu igbagbọ pe nkan kekere ti a o le yanju ni. Mi o sọ fun ẹnikẹni, bo tilẹ jẹ wipe awọn ọrẹ mi ṣakiyesi pe inu mi ko dun.

Mo bẹrẹ si ni ba a fa wahala ninu ile titi to fi jẹwọ fun mi ni ọjọ kan lẹyin ọsẹ mẹta pe, lootọ ni oun ati obinrin naa ti n ni ibalopọ lati bi oṣu diẹ.

Niṣe ni mo la ẹnu silẹ, ti mi o le pade, nitori pe mi o gbagbọ pe ọkọ mi le ṣe iru nkan bẹ ẹ.

Àkọlé fídíò, Damilọla pàdánù ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ nítorí ilà kíkọ

Bawo lo ṣe ṣe e ti mi o mọ?

Kia ni mo bẹrẹ si ni yẹ awọn atẹranṣẹ rẹ wo, mo si ri aridaju pe, wọn ti n fẹ ara wọn ṣaaju asiko to sọ fun mi pe awọn bẹrẹ, Wọn ti lọ si ile itura laimọye igba, wọn si ti jọ rinrinajo afẹ lọpọlọpọ igba pẹlu.

A ṣe ọkọ mi ti n ba awọn aṣẹwo lopọ lati igba ta a ti ṣegbeyawo. Ninu ijẹwọ rẹ lo tun ti sọ fun mi pe, oun maa n wo ọpọlọpọ fidio ibalopọ fun ọpọlọpọ wakati.

Ati pe gbogbo igba ti oun ba lọ si irinajo l'oun maa n lọ si awọn ile igbafẹ ti awọn eniyan ti maa n jo ni ihoho tabi ṣe afihan fiimu onihoho.

Oṣere ibalopọ

Oríṣun àwòrán, Karen Charmaine Chanakira

Ọrọ naa da ipaya ati iporuru ọkan si mi lara. O si tun jẹ nkan itiju, ti ko ṣe e sọ fun ẹnikẹni.

Aa ti gbọ pe ọkọ mi n lọ sile aṣẹwo? Mo ro nkan ti awọn eniyan yoo sọ nipa mi, to fi mọ iru oju ti wọn yoo fi wo ọkọ mi.

Erongba mi ni pe, awọn eniyan yoo wo o pe mi o ki n ṣe obinrin rere lo mu ki ọkọ mi gbe igbesẹ bẹ ẹ.

Mo si tun wo pe boya mi o rẹwa to l'obinrin ni, nitori pe mo sanra diẹ, a bi mo ti n darugbo ni.

Obinrin to n ṣe itọju ara rẹ

Oríṣun àwòrán, Karen Charmaine Chanakira

Kia ni mo bẹrẹ si ni t'ọju tọte, mo si n tun ara ṣe ju ti tẹlẹ lọ. Bakan naa ni mo ra awọn aṣọ tuntun, mo n ṣe irun ori mi deede.

Ṣugbọn mo tun gbagbọ pe, nkan ko lọ deede pẹlu ọkọ mi. Boya aisan kan n ṣe - dajudaju, o nilo iranlọwọ.

Ile iwosan fi idi rẹ mulẹ pe, ọkọ mi ni irufẹ aida kan - o kundun ibalopọ ju bo ṣe yẹ lọ.

Igba ti a to o bẹrẹ si ni lọ fun idanilẹkọ igbeyawo, ni imọlẹ to o tan si aye ọkọ mi. Oun paapa sọ pe, inu okunkun birimu ni oun wa lasiko ti o n la nkan naa kọja.

Àkọlé fídíò, 'Oúnjẹ ibìkan jẹ́ èèwọ̀ ibòmíì ni ọ̀rọ̀ ọmú ńlá'

Amọ, o ṣeni laanu pe, mi o le sọ ọrọ naa fun ẹnikẹni. Aṣiri nla ti maa gbe wọ koto ni.

Nibayii, a ti n fi inu han ara a wa, a si n ba ara wa jiroro.

Ṣe mo le dariji ṣa? Mi o lero pe mo le dariji lailai, nitori pe nkan to ṣe naa dun mi gan an ni.

Àkọlé fídíò, Odindi ọjọ́ kan ni mo fi wà ní ìhòhò ní Libya tí gbogbo èrò n fi ọwọ́ pa mí lára

Mo ṣi nifẹ rẹ, oun naa si n sọ fun mi ni gbogbo igba pe oun nifẹ mi.

Awọn ọmọ wa paapa ko gbọ nkankan nipa ọrọ na, nitori pe mi o fẹ ki wọn maa fi oju buruku wo baba wọn.