Celebrities 2022 greetings: Wo bí àwọn gbajúmọ̀ tí ẹ̀ fẹ́ràn yìí ṣe tẹ̀ẹ́ wọ́nú ọdún 2022 àtí ohun t'Ọ́lọ́hun gbé wọn borí

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Ọpọlọpọ awọn gbajumọ lagbo orin, adẹrinpoṣonu ati fiimu lo ti n fi ẹmi imoore wọn han fun Ọlọrun atawọn ololufẹ wọn.
Wọn o ṣe eyi lasan, ọpọ wọn lo tu aṣiri ohun toju wọn ri lọdun to kọja gẹgẹ bi idi ti wọn fi n dupẹ.
Diẹ lara awọn to n ki awọn ololufẹ wọn ku ọdun niyi pẹlu oniruuru fọto ti wọn fi bẹrẹ ọdun tuntun ati ọrọ ti wọn fi ranṣẹ si awọn ololufẹ wọn.
Queen Salawa Abeni
Gbajugbaja agba olorin obinrin Queen Salawa Abeni fi fidio sita lati dupẹ lọwọ Ọlọrun ati to fi ki awọn ololufẹ rẹ.
O dupẹ lọwọ awọn eeyan fun atilẹyin wọn la ọdun 2021 ja to si gbadura pe Ọlọrun yoo maa bukun fun wọn.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 1
Woli Agba Ayo Ajewole

Oríṣun àwòrán, Ayo Ajewole
Gbajugbaja apanilẹrin ni Ayo Ajewole ti ọ̀pọ mọ si Woli Agba. Oun naa fi akanṣe fọto ikini ku ọdun tuntun sita lati ki gbogbo awọn ololufẹ rẹ.
O n dupẹ pe ati oun ati awọn ololufẹ rẹ jọ la ọdun 2021 ja wọ ọdun 2022 to si gbadura pe ọdun 2022 yoo mu ọpọ sii wa.
Funke Akindele
Gbajugbaja oṣere ti ọpọ mọ si Funke Akindele ki awọn ololufẹ rẹ pẹlu aworan ati ọrọ ikini ku ọdun tuntun to kọ soju opo rẹ.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 2
ItelediIcon, Mercy Aigbe, Mustapha Solagbade, Ella Kwam 1
-Awọn ọlọjọ ibi ọjọ ọdun tuntun

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Bi ọpọlọpọ awọn gbajumọ oṣere ṣe n ki awọn ololufẹ wọn ku ọdun tuntun lawọn wọnyii naa n gba ara ọtọ ikini lọtun losi toripe wọn n ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi.
Mercy Aigbe to fi fidio anura idupẹ rẹ soju opo rẹ kọ ọrọ le e lori pe niwoyi ọdun to kọja oun n la ipenija nla kọja to dẹru ba ẹmi oun. "Mo sunkun lai le dakẹ, mo bi Ọlọ́run lẹjọ ti mo si n bere pe o ṣe le jẹ emi.
Mercy Aigbe ni ninu gbogbo ẹ, oun ṣa n sọ fun ara oun pe ọmọ majẹmu ni oun. Torinaa ninu gbogbo ipenija rẹ, o tẹsiwaju lati maa yin Ọlrun logo ati gbigba adura lai ṣaarẹ ati awẹ ati itọrẹ aanu.
"Lalẹ ọjọ kan mo sọ fun Ọlọrun pe to ba mu mi bori laalaa yii to fun mi ni ẹri lori rẹ maa yira nilẹ niwaju pẹpẹ Oluwa, maa fi sita loju opo ayelujara mi ki gbogbo aye le mọ pe Ọlọrun ologo ati alaanu ni ẹ".
O ni bi oun ṣe tẹsiwaju, ri si de, Ọlọrun ṣe e o si lọ san ẹjẹ rẹ niwaju Ọlọrun.
Eyi waye ni deede ọjọ kini oṣu kinni ọdun 2022 to tun jẹ ọjọ ibi rẹ ati ọjọ ibi fun awọn akẹgbẹ rẹ ọkunrin meji: Itele ati Mustapha Solagbade to fi mọ iyawo tuntun ti gbajugbaja olorin Kwam 1 ṣẹ fẹ, Emmanuella.
Adeyinka Alaṣeyori (Oniduro Mi)

Oríṣun àwòrán, Adeyinka Aleseyori
Gbajugbaja olorin ẹmi ni Adeyinka Alaṣeyori toun naa ṣẹṣẹ di gbajumọ lọdun to kogba wọ́le lọ yii. Lati igba naa lawọn eeyan ti n tẹle e.
Alaṣeyori fi fidio orin ikini wọ inu ọdun tuntun ti oun ati ẹgbẹ olorin rẹ fi gbe Ọlọrun ga si oju opo rẹ lati fi ki gbogbo eniyan ku ọdun tuntun.
Lekan Kingkong (Agba Inaki)
Ọrọ iṣiti ati adura fun ọdun tuntun latẹnu adẹrinpoṣonu Agba Inaki.
Jaiye Kuti
Ṣe ni gbajugbaja oṣerebinrin Jaiye Kuti tadi reke wọ inu ọdun tuntun to ni ki awọn ololufẹ rẹ tun ṣe ju bi wọn ti ṣe lọdun to kọja lọ.
















