2022 prophecies and church watch words: Oyedepo, Adeboye, Olukoya àtàwọn Pásítọ̀ míì tó ti sọ àsọtẹ́lẹ̀

Oríṣun àwòrán, OTHERS
To ba ku ọjọ perete ti ọdun to ba n kogba wọle lọ pari ni ọrọ sisọ asọtẹlẹ fun ọdun tuntun maa n mumu lookan aya awọn eeyan.
Iha meji lo saba maa n kọ, ti awọn to nigbagbọ ninu awọn asọtẹlẹ ati ti awọn to n tako awọn asọtẹlẹ ọhun pe irọ ni awọn Pasitọ to sọ wọn n pa.
Nibayii, fun ọpọlọpọ ijọ awọn Kristẹni, kete ti wọn ba ti ke "Hapi Nuu Yiaa" ni ago mejila oru ọjọ kinni oṣu kinni ọdun tuntun ti adari ijọ si ti sure fun wọn ni awọn ọrọ asọtẹlẹ maa n jade.
Igbesẹ ti pupọ awọn adari ijọ yii ṣalaye pe awọn gbe ṣaaju akoko ti wọn sọ asọtẹlẹ yii ni pe wọn ti ba Ọlọrun sọrọ ninu adura lati wo oju Ọlọrun fun igbesi aye awọn ọmọ ijọ wọn, ilu ti wọn wa, orilẹede ati agbaye lapapọ.
Eyii si ni ọpọlọpọ awọn mii maa n tako gidi ti ero wọn yoo maa jade lori ayelujara kii sii ṣe ni Naijiria nikan, iṣẹlẹ yii maa tan ka awọn orilẹede agbaye miiran tori fun apẹrẹ ni orilẹede Ghana, ijọba ṣẹṣẹ fi fofin de sisọ asọtẹlẹ ọdun tuntun ni ti Ọlọpaa Ghana si fi ikilọ jade fun awọn adari ẹsin.
Ẹwẹ, ko sofin to de eyi lorilẹede Naijirira o gẹgẹ bi ẹgbẹ awọn agbẹjọro kan ṣe fesi si ohun ti ijọba Ghana ṣe pe iru eyi ko le ṣẹlẹ lai lai ni Naijiria tori pe awọn to wa ni ijọba gaan n duro de asọtẹlẹ gẹgẹ bi wọn ṣe ṣapejuwe wọn pe onibara awọn adari ẹsin to n sọtẹlẹ ni ọpọ awọn to wa ni ijọba ati awọn oloṣelu.
Sibẹ sibẹ, awọn Pasitọ kan to jẹ ilumọọka ti sọ asọtẹlẹ ti wọn ba bọ latibi adura wọn pẹlu Ọlọrun gẹgẹ bi wọn ṣe sọ ọ fun ọdun 2022:
Redeem Church (Pasitọ Enoch Adejare Adeboye)

Oríṣun àwòrán, Rccg_pr
"A o ki n ṣe eyijẹ-eyiojẹ ninu asọtẹlẹ to ba wa latọdọ Ọlọrun. Emi o si ki n ṣe Wolii, Pasitọ ni mi ṣugbọn mo maa n gbọ latọdọ Ọlọrun lẹẹkọọkan".
Nigba ti o sunmọ ago kan oru lẹyin ti Pasitọ Adeboye dari awọn ọmọ ijọ rẹ, RCCG ninu akoko adura, ati pe gẹgẹ bi ireti ọpọ, o mẹnu ba ọrọ asọtẹlẹ amọ ko kan sọ ọ lasan, ṣe ni ti ọdun yii tun ba ohun aa ṣe si asọtẹlẹ to ba jẹ buburu eyii tii ṣe kiko ẹgbẹ aladura oni wakati mejilelaadọrin jọ.
"Mo nilo eeyan ẹgbẹrun kan pere lati darapọ pẹlu mi lati gba awẹ ati adura oni wakati mejilelaadọrin".
Pasitọ Adeboye ni ọrẹ oun kan lawọn jọ n sọrọ lori ki ni ọna abayọ si iṣoro Naijiria ti oun si sọ fun un ni iranti awọn asọtẹlẹ ọdun bii meji sẹyin pe ohun to yẹ ki Naijiria ṣe ni ko tọrọ aforijin lọdọ Ọlọrun amọ Naijiria ko ṣe e to si ni oun ko ni le s asọtẹlẹ mii nipa Naijiria toripe bi oun ba ni bayii lo yẹ ki Naijiria ṣe lati ri oju aanu Ọlọrun, awọn adari a ni ko di ibi ti wọn pe e si mu.
Adeboye ran awọn eeyan leti igba to sọtẹlẹ pe gbogbo agbaye yoo ṣe bii ọmọ tuntun to n bi gọọrọ to si ni ko tii gbẹ tan nilẹ loun ṣe ni adura lo yẹ ki Naijiria gba.
"Ọrẹ mi ọhun ba ni ṣe bi iwọ ni Pasitọ wa, jọwọ ba wa gbadura. Eyi lo bi ọrọ ẹgbẹ aladura eleeyan ẹgbẹrun kan ti Pasitọ naa fẹ ko jọ.
Asọtẹlẹ Pasitọ Adeboye fun 2022:
1. Yoo le ni iṣẹ akanṣe ida aadọsan ti ẹ bẹrẹ lọdun 2022 ti yoo yọri si rere.
2. Irawọ ara ọtọ aimọtẹlẹ ri yoo yọju lọdun yii.
3. Bo ti wu ki gbogbo nkan ri, yoo jẹ ọdun lilaluyọ jantirẹrẹ.
Ẹwẹ̀, fun Naijira, owe elede oyinbo kan ni Adeboye fi pa fun oye kikun: "ko si boo ṣe le se nkan jijẹ "Omlette" lai kọkọ fọ ẹyin" to si gbadura pe Ọlọrun yoo fun wọn ni itumọ rẹ.
Fun agbaye:
1. Ọrọ irinajo lọ soke okun yoo gba ọna mii yọ lọdun yii.
2. Iji alaburu nla meji yoo ja lọdun yii. Ọkan lati apa ibi Atlantic ati ekeji lati apa ibi Pacific.
Fun awọn ọmọ ijọ rẹ o ni iroyin ayọ gbaa ni amọ Pasitọ ijọ kereje wọn ni ki wọn lọ ba ti yoo jiṣẹ fun wọn.
Mountain of Fire Ministries (Pasitọ D.K Olukoya)

Oríṣun àwòrán, D.K Olukoya
Ni tirẹ, Pasitọ ati oludasilẹ ijọ Mountain of Fire Ministries, Pasitọ Daniel Olukoya ya aworan awọn asọtẹlẹ rẹpẹtẹ to fi sita fun ọdun 2022 to si n lọ bii mẹtadinlogoji lonka.
Awọn asọtẹlẹ ijọ MFM pọ gidi amọ diẹ lara rẹ ni pe:
1. Ọdun 2022 jẹ ọdun ti awọn ọmọ Ọlọrun tootọ yoo lẹnu ọrọ.
2. O ni ẹ rii daju pe ẹ si Ọlọrun tọkan tọkan tori ọdun nkan tuntun to tun dara sii ni fun awọn ọmọ Ọlọrun.
3. Ọlọrun ni awọn asọtẹlẹ "bẹẹ gẹ́lẹ́ bi Oluwa ṣe sọọ yoo jade kii ṣe bii ti alakọsilẹ taa ni lakoko yii.
5. A ni lati gbadura gidi gan lodi si irin odi ati riru omi, ojo, odo ati okun lọna abami.
6.Ọdun too gbudọ mọ ohun too n ṣe pẹlu Ọlọrun ni, yanju ọrọ ara rẹ koo si ṣe aye rẹ bo ṣe tọ. Ma ṣe ba Ọlọrun ta ayo lọdun 2022.
7. A ni lati dena arun mii to tun fara jọ Covid-19 tabi iṣẹlẹ mii to jọ ọ.
8. Awọn ẹmi omi n tu awọn ẹmi apani meje sita - iwakiwa ibalopọ, ẹmi aimọ, ẹmi were, iporuru ọkan, irọ ati ẹmi aisan, ẹmi Mamonii, idamu ati aawọ.
9. Fifọ ijọ Ọlọrun mọ yoo ṣẹlẹ, iwọ too ba n wa lati fi Ọlọrun ta eyin, ṣere, ko ni ri bẹẹ lọdun yi o too ba n fi nkan ti Ọlọrun ta eyin, o n fi ẹmi rẹ wewu lọdun yii.
10. Ijọ ni lati gbadura ki Ọlọrun gbe awọn oloṣelu bii Daniẹli ati Josẹfun dide.

Oríṣun àwòrán, PAstor D.K Olukoya
Living Faith International (Biṣọọbu Oyedepo)

Oríṣun àwòrán, David Oyedepo
Ni ijọ Living Faith ti Biṣọọbu David Oyedepo jẹ adari fun, ọkan lara awọn nkan ti Pasitọ naa ni ẹmi dari wọn lati ṣe ni fifọ ẹsẹ awọn ọmọ ijọ ati ninu u pẹlu tanwẹẹli gẹgẹ bi Jesu Kristi ṣe ṣe fun awọn ọmọ ẹyin rẹ ninu bibeli.
Eyi ni wọn ṣe ninu ijọ lasiko isin aisun ọdun lasiko isin yii naa ni awọn asọtẹlẹ jade.
Awọn bii melo kan ti Biṣọọbu naa gbe jade ni:
1. Ohun ayọ ko ni dakẹ nile rẹ.
2. Ọdun yii yoo jẹ ọdun idupẹ ninu ile rẹ.
3. Gbogbo amọ to n pẹgan rẹ yoo wa laaye lati ri ogo Ọlọrun ninu aye rẹ.
4. Bi a ṣe n fọ ẹsẹ yin laṣalẹ yii, yoo ṣaami ibẹrẹ ọtun.
5. Ohun gbogbo to ba tẹle ọ wa, nipasẹ fifọ ẹsẹ yoo momi yoo ninu omi naa ni.
6. Ko ni si ọfọ ninu ile rẹ.
7. Ọlọrun yoo ṣe iyatọ laarin iwọ atawọn ẹlẹṣẹ.
8. Gbogbo obi ni yoo jẹ igbadun eso laalaa wọn.
Ọrọ apemọra ẹni laa pe temi di ire lawọn ijọ kan
Dunamis Church International: Ọdun oreofẹ ati ogo to n kun akunwọsilẹ
COZA Global Church: Gbigbe ninu eyi to dara ju ti Ọlọrun
DayStar International ni tiwọn maa n ni awọn afojusun lọdọọdun ti gbogbo ọmọ ijọ yoo rii pe wọn ṣe. Ti ọdun yii ni nini afojusun nipa irinajo ẹmi, isuna, ilera, idile tabi ọrẹ kiko, eto ẹkọ tabi iṣẹ tabi owo.
















