2021 round up bizzare stories: Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ abàmì àti Kàyéfì tó wáyé lọ́dún 2021 rèé

Àkọlé fídíò, Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ abàmì àti Kàyéfì tó wáyé lọ́dún 2021 rèé nínú fídíò

Kaakiri agbaye ni ọpọlọpọ Kayefi ti sẹlẹ lọdun 2021 to si jẹ pe wọn wọ inu iroyin ti awọn eeyan n fẹ lati ka tabi wo fidio nipa wọn kiri.

BBC Yoruba tọ awọn iroyin Kayeefi kan to ṣẹlẹ ni iha Guusu-Iwọ oorun Naijiria gẹgẹ bo ṣe jẹ pe awọn ilu yoruba lo wa nibẹ.

Eyi lo jẹ ka ṣe akojọpọ diẹ lara wọn fun iranti yin:

Itajẹsilẹ ni Ibarapa, Igangan, Soka

Ni nkan bii oṣu keje ọdun yii, ki ni kan lo ṣẹlẹ to ti fa wahala to wa laarin gbajumọ ajafẹtọ iran Yoruba, Sunday Adeyemo ti ọpọ mọ si Igboho Ooṣa, ao si muu wa si iranti yin.

Nigba ti iroyin bẹrẹ si ni gbe e pe ikọ ọtẹlẹmuye ni Naijiria (DSS) ti lọ yabo ile ẹni ti o pe rẹ ni ajijagbara fun awọn ọmọ Yoruba Sunday Adeyemo ti ọpọ mọ si Sunday Igboho.

Gẹgẹ bi iroyin ṣe sọ, Sunday Igboho moribọ lọ awọn ikọ DSS sugbọn wọn ko awọn alabaṣiṣẹ pọ rẹ mejila lasiko naa ti wọpn si ko wọn da si ahamọ awọn DSS.

Titi ti ọwọ fi tẹ Sunday Igboho ni orlẹede Cotonou to si wa ni ahamọ wọn titi di asiko ti a ko iroyin yii jọ, awọn ibeere bii eleyii lo n jẹ jade nigba naa ni:

Kilo se? kii ṣe ọdaran? Ẹ tu Sunday Igboho silẹ, sugbọ titi di asiko yii Sunday Igboho si wa ni ahamọ ẹwọn orilede Benin.

Ẹwẹ, ka daa yin pada sibi ti ọrọ ti bẹrẹ; Sunday Igboho to di ilumọọka loni ko fi bẹẹ jẹ ẹni mimọ tẹlẹ koda ko seeyan to mọ ọ kaakiri agbaye nigba naa, o yari si igbesẹ ti awọn Fulani daran-daran bẹrẹ si ni gbe ni ilẹ Yoruba nibi ti wọn ti gba wọn tọwọ tẹsẹ lati maa ba wọn gbe lataye daye amọ ti nkan yi biri ti wọn ni awọn Fulani yii bẹrẹ si ni pa awọn ọmọ Yoruba.

Loun naa ba ko awọn ọdọ jọ ti wọn si bẹrẹ si ni koju awọn Fulani ọhun. Igba to ya ni ija fun aabo yii yi to di ki wọn maa ja fun iyapa ẹya Yoruba kuro lorilẹede Naijiria eyi ti Sunday Igboho si n dari titi di oni.

Kayefi ibẹ ni aduru itajẹsilẹ to waye lawọn ilu Yoruba bii Ibarapa, Igangan to fi mọ ilu Sunday Igboho, Igboho ati ile ti o n gbe to wa ni agbegbe Sọka ni Ibadan eyi to si di rẹpẹtẹ gan laarin awọn Yoruba ati pe wọn fẹsun kan pe awọn Fulani naa n ba awọn ọmọ wọn sun.

Aṣọ funfun to n lọ bii ejo to jabọ lati oju ọrun ni Ondo to di "miracle"

Ni bii oṣu melo sẹyin ni iṣẹlẹ kan bi awada bii Kayefi dede sọ ara rẹ di iroyin to gbalẹ kan lorilẹede Naijiria paapaa julọ laarin awọn ipinlẹ Yoruba.

Nigba ti BBC Yoruba de ilu naa ni ootọ gbogbo ohun to ṣẹlẹ hande ti arabinrin aṣe gbọngan lọṣọ kan ṣalaye pe oun lo ni aṣọ ọhun to si jẹ bii aṣọ funfun ọpa ọgọfa to ni oun fọ oun si sa a si ẹyinkunle rẹ.

Amọ o ni ko ye oun bi afẹfẹ ṣe le gbe aduru aṣọ to wuwo to bẹẹ yala ni gbigbẹ tabi ni tutu.

Arabinrin naa gan gẹgẹ bi ọmọ Yoruba ati ẹlẹsin Kristẹni sọ fun BBC Yoruba pe boya o ni nkan ti Ọlọrun fẹ fi ṣe ni aye oun naa ni.

Igi Ọdan wo o tun dide pada funrarẹ ni ilu Oyo

Kayefi gidi to ṣẹlẹ korokoro tun leleyii to ṣẹlẹ ni adugbo Sabo ni ilu Oyo ti wn ni igi wo o tun dide pada lẹyin to ti pa awọn eeyna kan.

Awọn ara ilu ibẹ sọ fun akọroyin BBC Yoruba pe eeyan mẹrin lo pa.

Bo tilẹ jẹ pe awọn onimọ Sayẹnsi sọ awọn ọrọ kan lodi awọn nkan aṣa ti awọn ọmọ Yoruba n lọ mọ iṣẹlẹ yii lẹsẹ, awọn eeyan kọ lati gbagbọ pe kii ṣe Kayefi.

Igi Ọpẹ olori mẹtalelogoji lori oke nla

BBC Yoruba tun rinrinajo lọ si ori oke aramanda kan ni ilu Ilogbo Ekiti ti wọn gbagbọ pe igi alagbara ni igi to wa nibẹ tori iye ori ti ohun nikan da ni.

Awọn ara ilu naa ṣalaye fun akọroyin BBC Yoruba pe Ọpẹ Umalẹ tabi Olori yeye gẹgẹ bi wọn ṣe n pe e yi maa n gbọ adura awọn eeyan ti wọn si ni o tun ni eso kan to jẹ ara ọtọ.