2021 in Retrospect: O ti Zeh, 'Lórí irọ́', E choke, Cut soap, Sapa àti àwọn àṣà míì tó mi ìgboro tìtì lọ́dún 2021

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Ko si aniani pe odun 2021 ri bakan lara ọpọ awọn ọmọ Naijiria, paapaa pẹlu awọn ipenija to koju iul naa.
Ninu wọn la ti ri abo to mẹhẹ, gbigbẹsẹle Twitter, ijinigbe, ọwọngogo oun igbayegbadun gbogbo ati bẹẹ bẹ lọ.
Ṣugbọn sibẹ, awọn ọmọ Naijiria ko ṣai wa aye kan abi omiran lati mu inu ara wọn dun.
- Ilẹ̀ ń j'ẹ̀nìyàn! Ka nÍpa àwọn Ìlúmọ̀ọ́ka tó dágbére fáyé ní 2021
- Ìròyìn BBC Yorùbá Márùn-ún tí ó mí ìgboro tìtì lọ́dún 2021
- Ẹ jọ̀wọ́ ẹ bá wa gba Sunday Igboho sílẹ̀, agbẹnusọ rẹ̀ Koiki ké bòsí sí ìjọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì
- Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ mánigbàgbé tó wáyé lọdún 2021
- Ki ní yóò sẹlẹ̀ sí Àrẹ́mọ Ooni Ile-Ife tí wọ́n bá gbé e kúrò l'Áàfin?
- Wo àwọn Sẹlẹ́bírítì fíìmù àti Olórin Yorùbá tí ọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀ wọ́n àti ìṣẹ̀lẹ̀ míì dàgboro rú lọ́dún 2021
Ninu awọn ọna ti wọn gba mu inu ara wọn dun ni awọn aṣa atigbadegba ti wọn gbe kalẹ.
Diẹ lara awọn aṣa to gbode kan lọdun 2021 ree:
Zah Zuh Zeeh (O ti Zeh)
Ko ti ju ọsẹ bii meji lọ ti aṣa kẹẹ maa dede gbọ "Zeh", "Zeh", Zah Zuh Zeh fọn saarin awọn ọdọ Naijiria ti gbogbo olorin atawọn ọdọ si ti n loo fun oniruuru ọrọ.
Amọ ibeere to n jẹ jade ju lẹnu awọn to ṣẹṣẹ n ja sii ni pe ki ni itumọ ọrọ yii gan gan?
Loju opo BBC Yoruba, ọpọ eeyan lo fi ohun ti wọn mọ tabi gbero gẹgẹ bi itumọ Zah Zuh Zeh sita.


Oríṣun àwòrán, Ebipatei Yhee Frankincense



Ẹni to si kọkọ gbe ọrọ yii jade ni Olorin tuntun ti orukọ rẹ n jẹ Portable Omolalomi ti oun ati Olamide jọ kọ orin hun ninu eyi ti ọlọkan o jọkan awọn ọ̀rọ̀ yii si n jade ninu orin hun: Zeh, Zah, Zuh, Pokotua, Bo card ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Cut Soap For Me
Oniruuru itumọ ni wọn fun 'cut soap for me' bi olukuluku ṣe fẹ lo o si.
Igbagbọ ọpọlọpọ ọmọ Naijiria ni pe awọn ọmọ yahoo-yahoo lo gbe aṣa naa jade.
Awọn kan tilẹ sọ pe ẹnu ọmọ yahoo-yahoo kan ti aajo yiwọ fun to wa yawere ni aṣa naa ti kọkọ jade to n pariwo 'cut Soap for me' kaakiri adugbo.

Oríṣun àwòrán, @Zlatan_ibile
'Cut sop for me' ko tumo si ọṣẹ babalawo, o lee tumọ si fifun eeyan ni iroyin to lee ṣina iṣẹ fun tabi fun eeyan ni anfani ati debi giga.
Nibi ti aṣa naa gbajumọ de, awọn apanilẹrin ati alawada bii Cute Abiola, ati Tolibia fi gbe orin jade ti wọn pe akori rẹ ni 'Cute soap for me'.
E Choke

Oríṣun àwòrán, Davido
Afaimọ ko maa jẹ aṣa 'E choke' yii ni ọpọ yoo mu gẹgẹ bi asa to gbajumọ julọ lọdun 2021 bi wọn ba ni ka fi si ti ibo didi.
Ọpọ maa n loo lati fi ṣe apejuwe iyalẹnu, tabi lati fi awọn eeyan ṣe yẹyẹ.
Gbajumọ olorin, Davido lo tubọ mu ki aṣa naa gbajumọ sii.
Bakan naa ni wọn tun n fi ṣe apejuwe ọrọ, ọla, aṣeyọri ati awọn ohun rere miran loju awọn ti ko ba fẹni fẹre.
Who Dey Breet?
Aṣa miran to tun rinlẹ lọdun 2021 ni 'who dey breet?'.
Aṣa yii ko ni itumọ kan ni pato. Ọna to wu olukuluku lo gba n lo.
Ọna kan ti wọn n gba loo ni lati dẹyẹsi awọn ti ko fẹni fẹ're.
Bakan naa ni wọn tun maa fi n pe akiyesi si awọn iṣẹlẹ gbankogbi
Na….. I Wan Dey Do Now
Oniruuru ọna ni aṣa yii ba de.
Apẹrẹ ni:
'Na people wey I no fit beat I wan dey fight now'', to tumọ si "awọn eeyan ti mi o le da mu ni mo fẹ maa ba ja bayii"
Aṣa yii maa n waye nigba ti awọn eeyan ba fẹ sọ pe nnkan ti apa awọn ko ka l'awọnfẹ maa rawọ le.
Ko rọrun lati tọpasẹ orisun aṣa yii ṣugbọn ara awọn aṣa to gbilẹ lọdun 2021 ni.
Wahala be Like
''Wahala be like…" ara awọn aṣa to lamilaaka lọdun 2021.
Nigba to ya lo yipo si "Wahala be like bicycle'', ''Wahala be like Noodles'', ''Wahala be like Desmond Elliot'', ati bẹẹbẹẹ lọ.
UAR
Ni oṣu kẹfa ni aṣa UAR gbode kan nigba ti iroyin jade pe ileegbimọ aṣofin apapọ Naijiria n gbero ati yi orukọ Naijiria pada si United Africans Republic, UAR.
Ni kete ti eyi jade lawọn ọmọ Naijiria ti bẹrẹ si nii gba a bi igba ọti lori ayelujara.
Koda gbajugbaja akọrin Naira Marley da si ọrọ naa

Oríṣun àwòrán, @OFFICIALNAIRAM1
Bi ere bi ere lo ba di ki awọn eeyan maa dasa ẹ jẹ ki a ta Naijiria ki a lọ si UAR ati bẹẹ lọ.
Japa
Lati inu ede Yoruba ni wọn ti mu aṣa yii jade. Japa tumọ si ki eeyan ki ere mọlẹ, ko sa asala fun ẹmi rẹ kuro ninu wahala tabi iṣoro kan.
Ju gbogbo rẹ lọ ọpọ lo n lo o fun kikuro ni Naijiria. Pupọ awọn ọdọ Naijiria lo fẹ 'japa' kuro lorileede Naijiria lọ si oke okun.
Sapa
Osi ati iṣẹ to le nlẹ ni wọn n fi Sapa da laṣa.
A le pee ni ọna kan lati faṣa pe ko si owo lọwọ eniyan.
Lori Irọ
Ajíhìnrere Ismail Badmus, ẹni ọdun ni orisun aṣa yii.
Ninu fidio kan to kariaye ti wọn ya nigba to fi jade iwaasu to n kọrin lori irọ.
Werey Dey Disguise
Aṣa miran niyi to gbe ede oyinbo alamulumala ti a mọ si pidgin ati Yoruba hanu.

Oríṣun àwòrán, Happenings in Ogun
O tumọ si ki eeyan maa dibọn tabi fi ara pamọ. Igba ti wọn maa n da aṣa yii ju ni igba tieeyan kan ba n se ohun kan to lodi bi wọn ṣe ri gan ni pato.
Wa Ti Ma Gbọ
Wa Ti Ma Gbọ jẹ aṣa to yọ jade lati inu orin Adekunle Gold to akori rẹ ni ' High' . O jẹ aṣa ti wọn maa n da lati fi sọ fawọn eeyan pe ṣe wọn ko da ohun tabi ẹni ti wọn n sọ mọ ni.
Something Hooge
Gbajumọ alawada ori ayelujara, Mr. Sabinus ti awọn kan tun mọ si Investor Sabinus lo gbe aṣa yii jade.
" something hooge" tumọ si nnkan to tobi pupọ.

Oríṣun àwòrán, Facebook/mumuskit
Wọn maa n o lati sọ nipa ohun to tobi kan ti eeyan n reti tabi poungbẹ fun.
We meuve
Ọkan lara awọn olukopa eto agbelewo Big Brother Naija, Vee lo gbe aṣa yii jade lasiko to fi n ba ololufẹ re Neo ja ninu ile kan lo fi n sọ fun un pe ko kuro lọna ki oun kọja.
Nitori ede oyinbo ẹnu rẹ mu ki 'move' dun bii "meuve" leti.
















