Free Sunday Igboho: Ẹ jọ̀wọ́ ẹ bá wa gba Sunday Igboho sílẹ̀, agbẹnusọ rẹ̀ Koiki ké bòsí sí ìjọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì

Free Sunday Igboho: Ẹ jọ̀wọ́ ẹ ba wa gba Sunday Igboho silẹ, agbẹnusọ rẹ koiki ke bòsí si ìjọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì

Agbẹnusọ ajijagbara Sunday Adeyemo, ti gbogbo eniyan mọ si Sunday Igboho, Koiki ti ke gbajare pe ki ijọba orilẹede Ilẹ Gẹẹsi gba Sunday Igboho silẹ lọwọ ìjọba Naijiria ati orilẹede Benin.

O sọ eyi di mimọ ninu iwe ẹsun kan ti o kọ si ijọba orilede Gẹẹsi pe ki wọn ba orilẹede Benin sọrọ lati fi Sunday Igboho silẹ nitori kii se ọdaran.

Koiki ni lati bi oṣu marun sẹyin ti wọn ti mu sinu ahamọ lorilẹede Benin Republic wọn ko fi ẹsun kankan kan sibẹ wọn ko jẹ ki o kuro ni ahamọ.

Àkọlé fídíò, Orí Tẹlifísàn ni mo ti rí Sunday Igboho rí láyé mi, bí ìyà ṣe jẹ mi gbé láti Ibadan, dé Àtìmọ́lé DSS rèé - Ifasooto Dada

Lati jẹ ki ijọba orilede Gẹẹsi gbọ nnkan ti o n ṣọ, Koiki ni oun ti kọ iwe ẹsun ransẹ si ilẹ Gẹẹsi.

Bakan naa ni o ti fi iwe ẹsun ransẹ si awọn ọmọ Naijiria lati buwọ lu iwe ẹsun naa.

Ti ẹ o ba gbagbe ijọba Orilede Benin Republic mu Sunday Adeyemo ninu osun keje ọdun 2021 lasiko ti o fẹ gba ibẹ lọ si orilẹede Germany.

Àkọlé fídíò, '2013 lèmi àti bàbá mi kọ́ ìlé ẹ̀kọ́ yìí fáwọn ọmọ àdúgbò torí a rántí irú ìyà tó jẹ mi ní kékeré'

Lẹyin eyi ni ijọba orilede Naijiria fẹsun kan pe ọdaran ni, eyi si lo mu ki wọn gbe e lọ si ile ẹjọ lorilẹede Benin.

Ṣugbọn titi di asiko yii, ko si ẹsun kan ni pato ti ijọba orilẹede naa ti fi kan an, bẹẹ wọn ko fi silẹ ni ahamọ ọgba ẹwọn to wa.

Àkọlé fídíò, Bi mo ṣe fi Ọtí, Igbó, Sìgá mímu sílẹ̀ tí mi ò kó obìnrin tó máa ń ba ayé awọn olórin jẹ́ - J.A Adelakun tó kọ orin "Amona tete