Itunu Babalola's autopsy rejected: Bàbá Itunu kọ èsì àyẹ̀wò òkú ọmọ rẹ̀ tí Cote d'Ivoire fi ráńṣẹ́

Itunu Babalola ati baba rẹ

"Mo ní kí n lọ dúpẹ́ lọ́wọ́ Abike Dari-Erewa ni àmọ lori esi ayẹwo ti wọn fun mi lati Cote d'Ivoire yii..."

Àwọn ìbéèrè tí Baba Itunu ń béèrè ni:

1. Wọn ni Itunu de ọdọ awọn ni ọjọ 13/11/2021, o si ku ni 14/11/2021, nibo lo wa ṣaaju ọjọ yii, to ba jẹ pe o n ṣaisan ni, nibo ni wọn gbe e lọ?

2. Ẹjẹ to n jade ni imu rẹ yatọ si ohun ti wọn n sọ bayii, ki ni nkan to ṣe e nigba naa, ko ye mi

3. Dokita ti mo mọ ni nkan ti wọn kọ pe o pa a, kii ṣe nkan to le tete pa eniyan, mo fẹ ki wọn ṣalaye nkan ti wọn kọ.

Idile oloogbe Itunu Babalola ti wọn fi si atimọle lọna aitọ to si pada ku sinu ẹwọn lorilẹede naa ti ni nkan ti wọn kọ sinu esi ayẹwo iku to pa ọmọ wọn, oun ko gba a wọle.

Baba Itunu, Ọgbẹni Abayomi Babalola ṣalaye pe lootọ daadaa ti ileeṣẹ to n boju to ọrọ awọn ọmọ Naijiria to wa nilẹ okere ati adari wọn, Abike Dabiri Erewa n ṣe.

"Gbogbo awọn nkan ti wọn ṣe nigba yẹn lo jẹ ki n lọ dupẹ lọwọ Abike Dabiri tori ti ko ba jẹ pe o da si ọrọ isinku pe ki wọn jẹ ki wọn gbe oku rẹ wa sile, ko ba ma rọrun".

Baba Itunu ṣalaye pe oun loun beere fun pe oun fẹ ki wọn gbe oku ọmọ oun wa sile ni ki wọn ma sin in si ọhun eyi ti Arabinrin Abike Dabiri si ki ara bọ ko lee di ṣiṣe.

Eyi ni Baba Itunu ni oun ba lọ si ile rẹ ti wọn fi wa fun oun ni esi ayẹwo ohun to fa iku Itunu eyi ti wọn fi ṣọwọ lati orilẹede Cote d'Ivoire.

Àkọlé fídíò, Itunu Babalọla Death:Àgbáyé ẹ gbà mí, mọ fẹ́ ìdájọ́ òdodo lórí ikú ọmọ mí! ìyà yí tí pọ̀jù

Amọ o ni ootọ ni iroyin taa gbọ pe oun kọ esi naa o si ṣalaye eredi fun BBC Yoruba.

"Nkan ti wọn kọ kò rí bẹ́ẹ̀ tori ọtọ ni nkan ti mo gbọ pe o n ṣe e ko to dagbere faye".

Ọgbẹni Abayomi ni ede Faranse gan ni wọn fi kọ esi ayẹwo ọhun tori ede ti wọn n sọ ni ilu Cote d'Ivoire niyẹn amọ oun ri eeyan to ṣalaye rẹ fun oun.

Bi ẹ ko ba gbagbe, Baba Itunu ṣalaye fun BBC Yoruba pe ko to di pe Itunu ku, oun pe e lori foonu toun si ni oun yoo lọ wo o amọ nkan yipada.

"Lẹyin ọjọ diẹ ti mo tun bẹrẹ si ni pe e ati fi ọrọ ranṣẹ ti mi o gbọ esi titi di ọjọ Aje ọsẹ keji ti mo gbọ pe o ti ku ti mo si ri i kaakiri ori ayelujara".

Àkọlé fọ́nrán ohùn, Itunu Babalọla Death:Ìjọba Nàíjìríà fèsì sí ìbéèrè Baba Itunu Babalola lórí òkú ọmọ rẹ̀!

O ṣalaye pe loju opo ayelujara kan ti awọn ri lasiko ti wọn n gbe e lọ si ile iwosan ṣafihan pe ẹjẹ n jade ni imu rẹ ti wọn si n fi aṣọ nu u.

"Nnkan ti wọn sọ pe o fa iku rẹ kii ṣe nkan to lee pa eniyan kiakia gẹgẹ bi dokita ti mo mọ ṣe ṣalaye okunfa ti wọn kọ sinu esi yẹn pe o pa a".

Baba Itunu ni nkan ti wọn kọ ni pe mimi eemi rẹ ko dara lo jẹ ko ku amọ o ni ko ri bẹẹ tori dokita ti ṣalaye fun oun ati pe kii ṣe nkan tawọn ri lori ayelujara lasiko ti wọn n gbe e kaakiri ile iwosan .

Ẹwẹ, Ọgbẹni Abayomi ni oun fẹ fi ẹhonu oun han si Arabinrin Abike Dabiri pe oun kọ esi naa ati pe lori awọn ẹgbẹ agbẹjọro kan ti wọn fẹ gbe ẹjọ yii lọ si ile ẹjọ ajọ ECOWAS lati ja fun ẹtọ ẹbi itunu, o ni oun fi ara mọ ọ gidi gan.

Bakan naa lo fi to BBC Yoruba leti wipe Arabinrin Abike Dabiri ti fọwọ sii pe ki wọn tun ayẹwo naa ṣe.

Àkọlé fídíò, Orí Tẹlifísàn ni mo ti rí Sunday Igboho rí láyé mi, bí ìyà ṣe jẹ mi gbé láti Ibadan, dé Àtìmọ́lé DSS rèé - Ifasooto Dada