Israel Olagadeyo free school on the street: Ẹ̀kọ́ ilé la kọ́kọ́ fi bẹ̀rẹ̀ kó tó di báyìí mó wa lọ́wọ́

Àkọlé fídíò, '2013 lèmi àti bàbá mi kọ́ ìlé ẹ̀kọ́ yìí fáwọn ọmọ àdúgbò torí a rántí irú ìyà tó jẹ mi ní kékeré'

Paul Israel Olagadeyo ati baba to bi i lọmọ gbe ara ọtọ iranwọ yii kalẹ torii ohun ti wọn ranti ti oun funra rẹ.

O ṣalaye fun BBC yoruba pe adugbo Iyana Ilogbo ni awọn ti kọkọ bẹrẹ ile ẹkọ ọfẹ yii niba ti wọn woye bi nkan ṣe ri nibẹ.

Ọmọ ọdun mẹtadinlogun ni Arakunrin Israel gan nigba to kọkọ bẹrẹ ile ẹkọ akọkọ.

Ile ẹkọ adugbo

"Idi ni wipe mo jẹ eeyan kan to ti la oriṣiriṣi idanwo kọja nipa eto ẹkọ. Ọpọlọpọ igba lo jẹ wipe ti awọn ẹgbẹ mi ba wa ni ile ẹkọ, emi maa wa nita tori mi o ri oreọfẹ lati lọ sile ẹkọ".

O ṣalaye pe kii ṣe pe awọn obi oun ko fẹ lati ṣe amọ ko si agbara fun wọn ni.

Gbogbo akitiyan awọn obi rẹ lati jẹ ki eto ẹkọ rẹ maa lọ lai si idaduro ko yọri si rere.

Ile ẹkọ adugbo

Ọdun 2014 ti o wọ ile ẹkọ giga fasiti ni ile ẹkọ ti oun ati baba rẹ dasilẹ yiii wa gberu sii to di ile ẹkọ kikun.

Eeyan kan ni adugbo tilẹ fun wọn ni agbala ile rẹ to si tun n ba wọn ko awọn ọmọ jọ fun ile ẹkọ naa.

Nibayii ile ẹkọ adugbo naa ti di nla mọ wọn lọwọ ti pọ eeyan n ko awọn ọmọ wọn wa.