2023 Presidency: Mo faramọ́ kí ìjọba sún lọ si ìhà Gúúsù - Masari

Oríṣun àwòrán, Masari/ Facebook
Gomina ipinlẹ Katsina Aminu Masari Bello ti kede pe gidigba bayi ni oun duro pe ki ijọba sun lọ si iha Gúùsù orilede Naijiria.
O salaye pe, eyi yoo ran isọkan orilede Naijiria lowọ.
Masari sọ eyi di mimọ lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ ni Katsina lọjọ Isẹgun.
- BBC Africa Eye tú aṣírí ẹgbẹ òkùnkùn Black Axe ní Nàìjìríà, ìpànìyàn àti àwọn olóṣèlú tó wà lẹ́yìn wọn
- Ẹni tó gé orí olóri fi ṣe ògùn owó náá ṣán kú nínú àtìmọ́lé ọlọ́pàá l'Ondo
- A tún fẹ́ yá N12 Tiriliọ̀nù láti ilẹ́ òkèrè kí gbèsè Nàìjíríà di N50 tiriliọnu- BMO
- Ìjọba àná lo jẹ Nàìjíríà run di pòlòfo lórúkọ ìgbógun ti ìgbésùmọ̀mí - Malami
- Wàhálà bẹ́ sílẹ̀ níbi ayẹyẹ ọlọ́dọọdún ní ìpínlẹ̀ Osun
- Babatunde lọ bá adari Hoteeli ṣe àjọyo, ó pade iku ọbẹ gbígbóná
Gẹgẹ bi o ṣe sọ, iwe ofin Naijiria fi aaye gba gbogbo ọmọ orilede yii ni lati wa ni ori ipo naa " O se fun wa ni, ki se awa fun iwe ofin. Bẹẹ ni iwe ofin ko sọ pe ki wọn sun.
" Ti ẹ ba pinu lati dibo fun ẹnikẹni lati iha kankan ni Naijiria, ṣe o tunmọ si pe eniyan ti ru ofin ni?"
"Mo si ni igbagbọ gẹgẹ bi ọlọdani, gẹgẹ bi Aminu Bello Masari, gẹgẹ bi ilana temi, kii se bi ofin se sọ, a fi igba ti a ba n woye bayii ti a ni eto oselu to ni ipilẹ, mimu ipo ijọba yika gbogbo ẹkun lati igba de igba yoo ran isọkan orilede Naijiria lọwọ.
" Eyi jẹ ero ti tẹmi alara mi, ibi ti mo duro si ree, sugbọn mo ni igbagbọ nipa sisun agbara ijọba kaakiri, Gomina ọun ṣọ bẹ.
Ti ẹ o ba gbagbe ni ibẹrẹ ọdun yii ti o n sọrọ nipa bi awọn iha iwọ-oorun ati ila-oorun fun ijangbara ara ẹni.
Masari sọ pe, sisun agbara kaakiri ni orilede yii yoo mu ki gbogbo wahala to wa nilẹ yoo ni Naijiria dinku paapaa julọ awọn ti wọn sọ pe awọn ara Arewa nikan lo n dari Naijiria.
Nipa ti idibo ijọba ibilẹ Gomina Masari sọ pe idibo yoo waye ni osu mẹta akọkọ lọdun 2022.
O fi kun pe gbogbo awọn eto ati ohun ti wọn nilo fun eto idibo lo ti wa nilẹ lati rii daju pe ko si wahala kankan lasiko idibo.
















