Ogun Technician kills Union member: Babatunde lọ bá adari Hoteeli ṣe àjọyo, ó pade iku ọbẹ gbígbóna

Ẹni to gun eeyan pa

Oríṣun àwòrán, Ogun Police

Ọwọ Ọlọpaa ni Ìpínlẹ̀ Ogun ti tẹ arákùnrin oníṣẹ ọwọ kan, Toheeb Akanji ti o fi ọbẹ gun alejo ile ìtura kan, Damilare Babatunde Oladipupo pa ni Ìpínlẹ̀ Ogun.

Ninu atejade ti ileesẹ Ọlọpaa Ogun fi sita, Toheeb to jẹ ẹni to máa ń tún ẹ̀rọ amomitutu àti ẹ̀rọ amaratutu ṣe jẹ ẹni ọdun méjìlélọ́gbọ̀n ti ọpọ mọ si T.cash ni àdúgbò rẹ.

Àwọn Ọlọpaa fi panpẹ ofin mú u lẹyin ti wọn gba ipe ni Agọ Ọlọpaa to wa ni agbegbe Agbado ni nkan bíi ago mejila àbọ̀ oru pe Oladipupo Babatunde ti wọn mọ si "No Story" to wa si ile ìtura Blue Roof ni agbegbe Adiyan láti bá ẹni to ni ile ìtura náà ṣe àjọyọ kan ti fara gba ọbẹ to si ti gba ibẹ̀ kú.

Àkọlé fídíò, Bi mo ṣe fi Ọtí, Igbó, Sìgá mímu sílẹ̀ tí mi ò kó obìnrin tó máa ń ba ayé awọn olórin jẹ́ - J.A Adelakun tó kọ orin "Amona tete

Nígbà ti awọn Ọlọpaa de ibẹ ni wọn ṣàwárí pé ṣe ni wọn tán oloogbe naa jáde lọ sita ti afurasi ohun si gun un pa.

Bakan naa ni wọn tun rii pe oloogbe ọhun tiraka pẹlu ẹni to fẹ pa a eyi to mu ko di aṣọ otutu to wọ mu ati ọbẹ to fi gun un.

Wọn sare gbe Babatunde lọ ile iwosan amọ wọn rii pe o ti baba ku gẹgẹ bi dokita ṣe sọ.

Kọmisọnsa ọlọpaa, Lanre Bankole ti wọ tete sọ ohun to ṣẹlẹ yii fun paṣẹ lọgan pe ki wọn wa afurasi ọhun kan laarin wakati mẹrinlelogun.

Ni tir nigba ti wọn mu u tan ti wọn n fi ọrọ wa a lẹnu wo, o jẹwọ pe lootọ lo ṣẹlẹ amọ pe iṣ eṣu ni.

Alaye rẹ ni pe ọtọ ni ẹni ti oun wa lọ sib lati lọ ba ja tii ṣe eeyan kan to na ọkan lara awọn ọmọ oun amọ nigba to ni oun de ibẹ́, oloogbe ọhun dede ta si oun to si n ba oun ja loun ba fa ọb ti oun mu dani jade.

Ẹwẹ, Kọmisọna Ọlpaa ti ni ki wọn gbe ẹjọ r lọ si ka to n ṣewadii ipaniyan ki wọn si fi jofin ni kiakia.