Desmond Tutu: Bíṣọ̀bù àgbà Desmond Tutu jáde láyé lẹ́ni àádọ̀rún ọdún

Desmond Tutu

Oríṣun àwòrán, Reuters

Biṣobu agba, Desmond Tutu to kopa ribi ribi ninu ija ati dopin idẹyẹsi awọn alawọdu lọwọ ijọba alawọ funfun ilẹ South Africa ti jade laye.

Biṣọbu agba Tutu fi aye silẹ lẹni aadọrun un ọdun.

Aarẹ Cyril Ramphosa orilẹede Soth Africa lo kede iku rẹ ninu atẹjade kan to fi sita.