Covid in State house: Ko sí ohùn tó burú tàwọn amugbalẹgbẹ ààrẹ bá kó àrùn COVID-19-Ilééṣẹ́ ààrẹ

Oríṣun àwòrán, Facebook/Femi Adesina
Kii ṣe ohun toju ko riri ti awọn amugbalẹgbẹ aarẹ ba lugbadi arun Covid-19.
Esi yi ni Femi Adesina to jẹ oluranlọwọ aarẹ lori ọrọ iroyin sọ ninu ifọrwerọ kan pẹlu ileeṣẹ iroyin Channels TV.
O ni ko jẹ kayeefi nitori eeyan ẹlẹran ara lawọn to n ba aarẹ ṣiṣẹ.
''Ohun ti mo fẹ sọ ni pe awọn to jẹ amugbalẹgbẹ aarẹ, eeyan lawọn naa''

Oríṣun àwòrán, OTHERS
''Wọn le ko aisan, o le rẹ wọn, aisan tabi kokoro ti wn ba ko si le lọ''
Adesina ni ko sewu loko afi gri aparo lori ibeere ti wọn bi lori eto naa pe arun Covid-19 ti n ja rain laarin awọn to rọ yika aarẹ Naijiria.
Laipẹ yi ni iroyin gbode pe awọn amugbalẹgbẹ aarẹ Buhari ti n lugbadi Covid-19 ni lemọlemọ ti wọn si ti n lọ si iyasọtọ lẹyin to fihan pe wọn kp Covid-19.

Oríṣun àwòrán, Facebook/Femi Adesina
Ṣé lóòótọ́ ni Garba Shehu, àwọn amugbalegbe Ààrẹ Buhari ti fara kásáa Covid-19?
"Irọ ni o, emi ko lugbadi Covid-19!"
Minisita eto iroyin àti àṣà, Lai Mohammed ti ni kò sohun to jọ ọ pe oun lugbadi arun Covid-19.
Lai Mohammed ti oun naa jẹ ọkan lara igbimọ Ààrẹ to n boju to ọrọ Covid-19 ni oun kopa ni ipade igbimọ alasẹ to waye ni Ọjọru ọ̀sẹ̀.
Bẹẹ lo ni oun tun kopa ninu ipade ara ọ̀tọ̀ igbimọ kan náà to tun waye ni Ọjọbọ àti eto kan ni ọjọ Ẹti nibi ti wọn ti ṣe ifilole Minisita abele fun ọ̀rọ̀ isẹ òde àti ilé gbigbe.
Eyi lo mu ko wá woye pe bawo ni wọn ṣe leè ni oun wa ni iyasọtọ ki wọn si tun gba oun laye lati máa lọ fun awọn eto yii ninu ile Ààrẹ.
- Kí ló ṣẹlẹ̀ tí a fi ń pé ọjọ́ kejì Kérésì ní 'Boxing Day'?
- Mọ̀ síi nípa àwọn Obìnrin tó wà láyé Ooni Ogunwusi ṣáájú Olòrì Naomi SilekunOla
- Ifasooto gbòmìnira lẹ́yìn oṣù mẹ́fà látìmọ́lé DSS lórí ẹ̀sùn pé ó ń ṣ'òògùn fún Sunday Igboho
- Wo ọ̀nà mẹ́fà láti dènà ìkọlù ejò afàyàfà bí o ṣe ń lo ìsinmi ọdún Kérésìmésì yìí ní abúlé rẹ
- Kà nípa ìbẹ̀rẹ̀ ìyàwó Ooni Ife, Olórí Silekunola Moronke Náómì, Wòlíì tó di Ayaba Ile Ife
Ṣaaju, Iwe iroyin Premium Times gbé iroyin sita lori ayelujara pe àrùn Covid-19 ti ń jà ranyin ninu ọgba ilé Ààrẹ ni Abuja.
Gbogbo awọn ti iwe iroyin naa ka kalẹ pe o ti lugbadi arun ọhun ni:
Minisita Lai Mohammed, ọ̀pọ̀lọpọ̀ oṣiṣẹ inú ilé Ààrẹ to fi mọ akọ̀wé àgbà ibẹ, Tijani Umar, ọga awọn isọngbe Ààrẹ, Yusuf Dodo, ọga awọn ẹṣọ, Aliyu Musa ati Oluranlowo pataki rẹ lori ìròyìn, Garba Shehu.
Ẹwẹ, Lai Mohammed ti fesi pe oun ko lugbadi Covid-19 torí òun wà ní àwọn ètò itagbangba lásìkò tí wọn ń wi yii.
Kò sohun meji ju pé ìròyìn ẹlẹjẹ ni. Yàtọ̀ fún ìyẹn, mo ti gba abẹrẹ ajẹsara méjì. Mo tun ti gba abẹrẹ amarajipepe Pfizer. Ọmọ igbimọ Ààrẹ fún arun yii ni mi. Mo si wa ni ìlera pipe tí mo si n ṣe iṣẹ́ mi takuntakun.
Ni ti Oluranlowo Ààrẹ, Garba Shehu, òun sọ pe lootọ ni oun ti lugbadi arun naa tòun si wa ni iyasọtọ.
Amọ ṣa, Shehu ni oun o le sọ nípa ti awọn oṣiṣẹ Ààrẹ to ku.
O sọ fun awọn oniroyin pe ohun to jẹ́ òótọ́ ni pé òun mọ pe oun ya ara òun sọtọ òun si n lo oogun òun àmọ́ òun kò mọ nípa ẹlòmíràn.















