Lai Mohammed: Kí ló mú Lai Mohammed pe gómìnà ìpínlẹ̀ Kwara ni amúni-búni àṣìwọ̀ ọkọ? Ẹkúnrẹ́rẹ́ rèé

Oríṣun àwòrán, others
Minisita Naijiria fun eto iroyin ati aṣa, Lai Mohammed ti sọ pe aṣiwọ ọkọ ni gomina ipinlẹ Kwara, Abdulrahman Abdulrasaq jẹ fun ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC.
Nigba to n sọrọ nibi ayẹyẹ to ti ṣi olu ile ẹgbẹ APC nilu Ilọrin, ni Lai ti sọ pe ki awsn to yan an ni gomina ni awọn ti mọ pe aṣiwọ ọkọ lo jẹ fun awọn.
Ile ẹgbẹ naa lo jẹ ti igun kan ninu ẹgbẹ naa, nitori pe igun meji ni ija oṣelu ti pin ẹgbẹ APC si ni Kwara.
Awọn kan n ṣe ti gomina, awọn kan si da wa ni stọ.
Igun to da wa yii lo ni ile ẹgbẹ ti Lai Mohammed wa a ṣi.
Ninu fidio naa, Lai sọ pe ati owo, ọkọ, to fi mọ ọkada ni ẹgbẹ pin lasiko idibo 2019, lai jẹ pe gomina fi kọbọ silẹ ninu rẹ.
Content is not available
View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.End of Facebook post
O ni amunibuni ni gomina naa.
"Kii ṣe ọmọ ẹgbẹ wa tẹlẹ, ojo si lo ko ẹyẹle pọ mọ adiyẹ.
"A ro pe eeyan ni wọn ni."
Lati asiko diẹ sẹyin ni omi alaafia ti daru ninu ẹgbẹ osẹlu APC ni Kwara.
Koda, laip yii ni igbakeji gomina Abdulrahman, Kayode Alabi, sọ nibi eto to ti ṣe ifilọlẹ iwe kan, 'O To Gẹ', pe niṣe ni awọn alaṣẹ ẹgbẹ APC , paapaa alaga ẹgbẹ naa ati Lai, fi ofin de awọn adari ẹgbẹ pe wọn ko gbọdọ ti ipolongo ibo gomina lẹyin lọdun 2019.
O ni lẹyin idibo aarẹ, ti wọn ri pe ọdọ̀ Abdulrasaq ni awọn araalu n ya si, ni wọn to darapọ mọ ipolongo rẹ.













