Sunday Igboho: Ọ̀pọ̀ èèyàn jẹ́rìí pé Mùsùlùmí òdodo ni Adogan Oosa, kìí pa irun jẹ

Oríṣun àwòrán, Koiki Media
Yoruba ni iku ogun lo n pa akikanju, iku odo nii pa omuwẹ, iku werewere nii pa obukọ.
Eyi ni ọpọ ọmọ Yoruba fi n sapejuwe ọkunrin kan, Saheed Adigun, ti ọpọ eeyan n pe ni Adogan, to jade laye lasiko ikọlu ti awọn osisẹ DSS se sile Sunday Igboho.
Lẹyin gbogbo hilahilo wahala ikọlu ile ajafẹtọ ọmọniyan fun idasilẹ Yoruba Nation, Sunday Igboho to waye, awọn eeyan ti n kan sara si ọkan lara awọn to fara gbọta naa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Sunday Igboho kọ̀wé sí ìjọba àpapọ̀, o ní dandan kí wọn sàn owó gbà má bínú ₦500m
- 'Ṣọ́ọ̀bù ìyá rẹ̀ ní Jumoke wá tí ìbọn ọlọ́pàá ti pa á lásìkò ìwọ́de Yoruba Nation ní Ojota'
- Gbogbo ìpilẹ̀sẹ̀ ìṣoro Nàìjíríà ni àtúnyẹ̀wò òfin ta ń ṣe yìí yóò mójútó - Gbajabiamila
- Ọkọ̀ òfurufú ọmọ ogun já lulẹ̀ èèyàn 92 ló wà nínú rẹ̀
- Ẹ mú "Candle" wá síbi ètò ìsínkú Wòlíì TB Joshua tí yóò bẹ̀rẹ̀ lọ́la - Ìjọ Synagogue
Ẹni taa n wi yii, pupọ eeyan ni ko mọ ọ tẹlẹ ko to jade laye, bo tilẹ jẹ wi pe kii jina si ayika ibi ti Sunday Igboho ba wa.
Adogan ooṣa ni inagijẹ rẹ ṣugbọn orukọ abisọ rẹ ni Adigun Saheed.
Ta ni Adigun Saheed ati pe bawo lo ṣe di ọkan lara awọn to n tẹle Sunday Igboho Kaakiri?
BBC Yoruba fimu finlẹ nipa rẹ, diẹ ree ninu ohun ta ri loju opo ayelujara nipa oloogbe naa.

Oríṣun àwòrán, Koiki Media
Ọmọ bibi ipinlẹ Osun ni Adigun Saheed taa si gbọ pe lati igba to ti de ọdọ Sunday Igboho, gbọin gbọin lo wa lẹyin rẹ bi ike.
Ilu Osogbo nipinlẹ Osun ni Adigun ti wa, ti ọpọ awọn olubanikẹdun si ti n ya lọ sile rẹ nilu naa, lati lọ daro iku rẹ.
Ohun ta ri aridaju rẹ ni pe musulumi to mu ẹsin rẹ lọkunkundun ni Adigun Saheed.
- Kí ló dé tí DSS kó bàńtẹ́ òògùn, ba ilé Sunday Igboho jẹ́ lái fara pa?
- Ilé mi kọ́ ni àwọn DSS ti kó àwon ìbọ́n tí wọ́n pàtẹ- Sunday Igboho
- Àwọn ọmọ Yoruba lókè òkun ṣèwọ́de nílùú London torí Sunday Igboho
- "DSS, níbo ni ₦2m àti owó Euro, Dollar àti Pound Sterling tẹ kó nílé mi wà? "
- Sunday Igboho, ìsáǹsá rẹ̀ kò lé sá mọ́ wa lọ́wọ́, mímú lá mú ọ - DSS fọwọ́ gbáyà
Gẹgẹ bi ohun taa ri ka nipa rẹ, Saheed Adigun kii pa irun rẹ jẹ ti o si ni igbagbọ pe gbogbo agbara lati ọdọ Allah lo ti wa.
Iroyin kan ti ko fidi mulẹ ni Adogan Oosa wa lori irun nigba ti ikọlu si ile Sunday Igboho waye.

Oríṣun àwòrán, YORUBA NATION
Nipa iru eeyan ti Adogan Oosa jẹ, a ri fọnran fidio kan to ti n kọrin Fuji ninu ọkọ, eyi to fihan wa pe ololufẹ orin Fuji nii se nigba aye rẹ.
Gẹgẹ bi ọga rẹ, tii ṣe Sunday Igboho, Adogan Oosa naa fẹran orin Wasiu Alabi Pasuma, ti ko si fi ifẹ rẹ pamọ fun.
Ninu fidio kan ti akọrin ,Wasiu Ayinde Onilewura Omo Pasuma to fi ilu Osogbo ṣe ibujoko fi si Instagram rẹ, a ri ti Saheed Adigun n kọ orin Paso.
Olayomi Koiki to jẹ agbẹnusọ Sunday Igboho sọ pe akọni nla lawọn padanu pẹlu iku Adogan Oosa.
Loju opo ayelujara lo fi ikede iku Adigun Oosa si, to si ni ki Eledua dẹ ilẹ fun ẹni to lọ.
Ninu nkan to sọ, a ri aridaju pe Adigun Saheed ni iyawo ati ọmọ ki o to jade laye.
Diẹ ree lara awọn aworan rẹ ti Koiki fi sọwọ.

Oríṣun àwòrán, Koiki Media



















