Sunday Igboho: Kìí ṣe gbogbo ohun tí DSS kó nílé mi ní wọn pàtẹ rẹ̀, níbo ní góòlù tí wọn kó wà?

Ohun ti wọn ba nile Igboho

Oríṣun àwòrán, DSS

Yoruba ni bi ogun ba jẹ lọ, ọgbọn yoo jẹ bọ.

Agbẹnusọ fun ajijagbara ọmọ Yoruba, Oloye Sunday Igboho ti salaye siwaju nipa ikọlu awọn osisẹ DSS sile ajijagbara naa.

Ninu fidio kan to se loju opo Facebook rẹ Olayomi Koiki sọrọ nipa atẹjade kan ti ileesẹ agbofinro naa fisita lalẹ ọjọbọ ti isẹlẹ naa waye.

Agbẹnusọ Igboho ni Ọlọrun lo saanu fun Sunday Igboho ninu ikọlu naa, kii kuku se pe o mọ se.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ni awọn DSS yii n wa Igboho kiri lati pa ni amọ Alọrun lo yọ.

"Koda, awọn DSS tun pa ologbo to wa nile Sunday Igboho lọ, ti wọn si ro pe Igboho lo di ologbo lati sa fun wọn, bẹẹ ni wn gbe oku ologbo naa lọ.

Ohun ti wọn ba nile Igboho

Oríṣun àwòrán, DSS

Bakan naa ni agbẹnusọ fun Igboho tun kede pe awọn ko fara mọ eroja ti ileesẹ DSS safihan rẹ pe wọn ko nile Igboho.

O ni kii se eroja perete tawọn osisẹ DSS patẹ rẹ nirọlẹ Ọjọbọ ni ọọfisi wọn nilu Abuja, pe awọn ko nile Igboho lo ri bẹẹ.

"Wọn fi ibọn han pe awọn ri AK 47, pump rifle, oogun abẹnu gọngọ, iwe irinna silẹ okeere atawọn ẹrọ ibaraẹnisọrọ ti wọn ko lọ nile Sunday Igboho.

Amọ wọn ko sọ nipa aimọye miliọnu naira ti wọn ko nile Igboho, to fi mọ awọn owo ilẹ okeere bii Pound Sterlings, dollar ati Euro.

Bakana naa ni wọn ko gbogbo ẹsọ goolu olowo iyebiye to wa nile Sunday Igboho lọ, ti wọn si se afihan rẹ mọ awọn ẹru ti wọn patẹ.

Àkọlé fídíò, Oba Gbolahan Timson Shomolu Bariga ní 'Restructuring'ti bọ́ aṣọ kò bá Omọyẹ mọ́!

Abi ẹyin foju ri awọn ẹsọ ara yii laarin awọn ẹru naa, ohun ti mo ri ni owo beba onidọla kan, haaa, tori Ọlọrun.

Agbẹnusọ fun Sunday Igboho wa n beere pe ki lo de ti awọn oriade nilẹ Yoruba ko fi sọrọ sita lati igba ti isẹlẹ ikọlu sile Sunday Igboho naa ti waye.