Yoruba Nation: Iléeṣẹ́ ọ̀lọ́pàá Eko ní olórí NURTW n‘Ibadan ń bọ̀ wá da ìwọ́de rú l‘Eko láti gbẹ̀san lára Sunday Igboho

Banji Akitoye ati Sunday Igboho

Ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti kede pe iwọde kankan ko gbọdọ waye nipinlẹ Eko labẹ bo ti wu, ko ri.

Kọmisana ọlọpaa l'Eko, Hakeem Odumosu lo fi ikilọ yi lede lasiko to n bawọn akọroyin sọrọ tun fi ewe ọmọ mọ awọn ajijagbara naa leti pe ilu ti yi, orin ti senji.

Odumosu wa n sekilọ fun Sunday Igboho ati alagba Banji Akitoye pe ki wọn ta kete sipinlẹ Eko lori iwọde Yoruba Nation ti wsn n gbero lọjọ Satide.

O ni oun n rọ wọn lati mase yọju soju popo ipinlẹ Eko nitori ifẹ ipinlẹ naa ati ti araalu, bẹẹ si ni ẹnikẹni ti ọwọ ba tẹ pe o se iwọde tabi se agbatẹru rẹ yoo jo palongo labẹ ofin.

"Ipinlẹ Eko ko lee tun foju wina eto aabo to mẹhẹ, idaluru ati idunkooko mọ alafia ilu ta ba wo isẹlẹ buruku to waye ni osu kẹwa ọdun to kọja tori iwọde Endsars.

Awọn oluwọde Endsars

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọpọ dukia ijọba ati ti araalu lo sofo danu nigba tawọn ọlọpaa fi ẹmi wọn di isẹlẹ naa lọpọlọpọ, eyi to jẹ irubọ to ga julọ.

Ọpọ agọ ọlọpaa ni wọn jo nina, to fi mọ awọn dukia to jẹ ti aladani ọlọpaa kọọkan lasiko iwọde naa, ti ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ko si ti bọ ninu iriri buruku naa.

Nitori naa ni a ko fi ni fi ọwọ ere mu awọn eeyan to n se agbatẹru iwọde naa, ti wọn n sọ pe iwọde alaafia ni awọn fẹ se.

Iru orin yii naa ni awọn oluwọde Endsars mu bọnu amọ ti ọrọ naa pada bu rẹkẹ lẹyin o rẹyin, eyi to mu ẹmi lọ, ti ọpọ dukia si bajẹ."

Ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ni nitori awọn alaye to ti se saaju yii, oun si tun n tẹnumọ pe ẹnikẹni ko gbọdọ wa se iwọde kankan nilu Eko tabi di lilọ bibọ araalu lọwọ lọna ijẹ wọn.

Odumosu ni "O ti de si etigbọ mi pe iwọde Yoruba Nation naa yoo waye ni gbagede Gani Fawehinmi ladugbo Ojota nikan.

Amọ awọn eeyan kan ti a ko mọ tun ti n gbero lati se irufẹ iwọde yii bakan naa ni ẹnu iloro Lekki Toll Gate, Ikoyi, Iyana Ipaja, Ikeja, Sururlere, Ikorodu atawọn agbegbe miran ni Eko.

Ta ba fi gba eleyi laaye, ewu nla n bẹ loko longẹ.

Àkọlé fídíò, Glorious Twins: Taiwo àti Kehinde Ekundayo ní ọ̀dọ́ ìyá àgbà ní àwọn ti ẹ̀bún orin kíkọ

Iwadi awọn osisẹ ọtẹlẹmuyẹ tun ti fidi rẹ mulẹ pe ẹnikan ti wọn n pe ni Eleweomo, to jẹ asaaju ẹgbẹ ọlọkọ ero nilu iBadan ti pari eto gbogbo lati kọlu awọn oluwọde naa.

Eyi ni wọn lo fẹ fi gbẹsan iku ọkan lara awọn ọmọ ẹyin rẹ ti igun Sunday Igboho pa lasiko irufẹ iwọde yii to waye nilu Ibadan lasiko kan.

Gbogbo akojọpọ ewu to rọ mọ iwọde naa ni ileesẹ ọlọpaa ko fi ni kawọ gbera lati gba awọn ọdaluru yii laaye pe ki wọn da alaafia ipinlẹ Eko ru."

Kọmisana ọlọpaa nipinlẹ Eko wa rọ awọn eeyan ipnilẹ naa lati maa ba isẹ oojọ wọn lọ nitori awọn ọlọpaa atawọn osisẹ agbofinro miran ti wa kaakiri lati pese aabo to peye fun tonile talejo nipinlẹ Eko.

Àkọlé fídíò, Olowo: Bí ìjọba bá ṣe àtúntò tún yẹ, Sunday Igboho yóò fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú wọn