Soiless Farming: Samson Ogbole ní táwọn irè oko bá fara kan ilẹ̀, ló ń kó àrùn bá wọn
Ọpọ eeyan lo maa n pa lowe pe ko si ọna abuja ni ọrun ọpẹ, tabi bi a ko ba ri ọkọ, a ko lee de Eko.
Amọ awọn imọ ijinlẹ sayẹnsi ati isẹ iwadi to n jade sita ti n fidi rẹ mulẹ pe ọpọ ọna abuja lo wa, taa fi le se ohunkohun.
Iru rẹ ni ti eto ọgbin, ti ọpọ gba pe inu erupẹ tabi ilẹ nikan ni ọgbin eweko ati ewebẹ pẹlu eso ti lee waye.
Nibayii, awari imọ ijinlẹ ti fidi rẹ mulẹ pe a le se ọgbin ohunkohun lai jẹ pe a lo erupẹ rara.
Ọkunrin kan ree, Samson Ogbole, to n sisẹ ọgbin lai pin wọn sori ilẹ eyi to pe ni Soiless farming tabi Agropolis.
Pẹlu ilana yii, Ogbole n gbin ewebẹ , eweko ati eso sinu tanki omi, ike ipọnmi, ọpa omi ọra ati bẹẹ bẹẹ lọ.
O ni ọpọ arun to maa n yọ ire oko lẹnu lo n wa latinu erupẹ amọ ti awọn ire oko yii ko fara kan ewebẹ, ko ni si aisan.
O wa n lo awọn fulufulu eepo ara irẹsi tutu ati agbado lati pin eweko dipo erupẹ.
Bakan naa lo salaye pe a ko gbọdọ maa pe awọn ewebẹ kan tabi eso pe wọn ni igba ti wọn maa n jade nnitori ilana ọgbin lai lo ajilẹ yii yoo jẹ ka maa ni gbogbo eso, ewebẹ ati eweko yika ọdun.
Àwọn ìtàn mánigbàgbé tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ìtàn ayé Henry Fajemirokun, olówó tó fi owó mọ Olúwa àti ènìyàn
- Ìtàn ayé Taiwo Oredein rèé, àgbà òṣèlú tó parí ayé rẹ̀ sọ́gbà ẹ̀wọ̀n
- Wo ìgbẹ̀yìn àwọn ọlọ̀tẹ̀ Yorùbá tó ran Fulani lọ́wọ́ láti kógun ja ìlú Osogbo
- Ìtàn ìgbé ayé Bode Thomas rèé, ó kọ́ wa láti máa kó ẹnu wa ní ìjánu
- Ṣo mọ̀ pé J.F Odunjo jẹ aṣòfin àti mínísítà nílẹ̀ yìí, yàtọ̀ sí pé ó jẹ́ òǹkọ̀wé?
- Ìtàn Àrọ̀gìdìgbà jẹ́ kí ń rò pé bàbá mi yan Yemọ̀ja ní àlè - Ọmọ Fagunwa
Koda, Samson Ogbole gan n kọ awọn agbẹ nipa ọna ti wọn fi le se amulo ilana ọgbin lai lo erupẹ rara.
Ẹ ba wa kalọ ninu fiudio yii lati mọ bi Ogbole se n sisẹ ọgbin lai lo ilẹ .
