Olofa ina: ẹ parí òwe yìí pé ìgbà tí ara bá tu ìgbẹ́ láà ri eṣú....
Baba Ọlọfa ina ló ba wa ṣide ètò fun toni pẹlu owe yii.
Ìgbà tí ara bá ìgbẹ́ làá rí Eṣú......Bí igbo bá gbẹ yan, eṣú á ya lọ.
Eyi ni owe ti Oloye Aderẹmi Adedeji, agba ọjẹ oṣere ti gbogbo eeyan mọ si Babab Olọfa ina fi ba BBC Yoruba ṣide eto tuntun to da lori atupalẹ owe ati awọn akanlo ede Yoruba
Eto yii ni BBC Yoruba gbe kalẹ ki ede Yoruba ma baa parun, ki awọn ọdọ le mọ sii nipa akoonu ede Yoruba.
Baba ọlọfa ina tumọ owe yii ni kikun pe owe ikilọ iwa ni.
O ṣalaye pe eṣu jẹ kokoro to maa n jẹ oko run ti awọn oloyinbo n pe ni 'Locust'
Ati pe irufẹ owe yii wa fun awọn olowo, ẹni to ri jajẹ lawujọ, ọlọla, oloṣelu ati ẹni to wa nipo nla ti ọpọ eeyan maa n wari fun.
O ni awọn obinrin loriṣiriṣii, ọrẹ, ará, iyekan, ero pupọ ati ojulumọ a maa yabo iru ẹni bẹẹ.
Oloye Sọbaloju ti ilu Ẹdẹ wa ṣalaye pe nigba ti owo ba tan ni irufẹ awọn eeyan yii dabi eṣú ti wọn maa n yalọ laisko ẹrun ninu oko.
O sọ lara abuda adamọ eṣú pé wọn kii da rin ati pe wọn kii si loko lasiko ọgbẹlẹ.
Baba pari atupàlẹ owe toni pe ki onikaluku ṣe pẹlẹ lasiko to ba n yẹ wọn.