Black women lives matter: Ọdún 2015 ní àwọn ọlọ́pàá pa India Kager láìní ìdí- Gina Best
India Kager n gbiyanju lati daabo bo ikoko to gbe dani ni lasiko ti awọn ọlọpaa yinbọn pa a- Gina Best
Lasiko ti awọn ọlọpaa n wa Angelo Perry to jẹ baba ọmọ ikoko to wa lọwọ India Kager ni wọn yinbọn pa obinrin naa.
Ọrọ yinyin ibọn pa awọn alawọ dudu ni orilẹ-ede America ti di nkan nla lasiko yii.
Gina Best to jẹ Iya India Kager ti wọn ni awọn agbofinro ṣeeṣi yinbọn pa ni ọdun 2015 naa ti ke gbajare sita.
O sọrọ lori owo gba-ma-binu $800,000 ti wọn fun ẹbi pe ko da ẹmi ọmọ oun pada.
Kimbele Crenshaw to jẹ ajijangbara lori awọn obinrin alawọ dudu nilẹ america naa sọrọ lori ewu nla to n koju obinrin alawọ dudu nibẹ.
Ajọ 'Say Her Name' to jẹ aladani ti kii 'se tijọba to n ran awọn ara ilu lọwọ naa n pariwo pe ki ẹmi ṣe pataki.
Gina to jẹ iya India Kager ṣafiwe ohun to ṣelẹ lẹyin iku George Flyod ni America pẹlu iku ọmọ tirẹ.
O ni oun naa n fẹ ẹsan pe ki wọn gba pe ohun ti awọn ọlọpaa ṣe ko dara si ọmọ oun naa.
- Ọmọ Yahoo tú àṣírí ara rẹ̀ fún, bí wọ́n ṣe ń ṣe é BBC Yorùbá
- Ènìyàn 27 lo ti bá iṣẹ̀lẹ̀ ọkọ̀ ofúrufú tó já rìnrìn ajò
- Pasuma kìí ṣe ọkọ mi o! Lanre Kuti ni mo fẹ́ - Jaiye Kuti
- Darandaran Fúlàní kankan kò ṣí kúrò l'Ọ́ṣun - olórí Fulani
- Eji Gbadero, ọmọ Ibadan àti jayé-jayé ọmọ ónílẹ̀ ti wọn yẹgi fun l'Eko