Yahoo Yahoo: Dating , Construction, awọn tó ń ṣe credit card - oríṣi tó wà

Àkọlé fídíò, Ọmọ Yahoo tú àṣírí ara rẹ̀ fún, bí wọ́n ṣe ń ṣe é BBC Yorùbá

A ko lee darukọ rẹ tabi fi oju rẹ gangan han fun idi pataki.

Arakunrin ọmọ ile iwe giga fasiti kan ree lorilẹede Naijiria to sọ iriri ara rẹ bo ṣe bẹrẹ ati bi gbogbo awọn to n lu jibiti ori ayelujara ti gbogbo eeyan mọ si Yahoo Yahoo ṣe n ṣe iṣẹ wọn.

O sọ fun BBC Yoruba pe Dating , Construction, awọn tó ń ṣe credit card, wire-wire, ati oniruuru orukọ ni iṣẹ awọn n jẹ.

"Iru awọn eeyan ti o ba n ba rin ni yoo sọ iru eyi ti waa ṣe. Yahoo Yahoo oní 'Millitary Dating' lèmi ń ṣe".

O ni to ba ti jẹ ẹni to ti yo ifẹẹ rẹ, o ti di Maga niyẹn. - Gbaun!!! Gbaun!!!

Wọn a gbe ẹ lori gege koo maa fi owo ranṣẹ ni bii ọsẹ ọsẹ.

"Mo n fi owo naa ran ara mi lọwọ ni nile iwe". Arakunrin yii ni Inú oun si dùn láti sọ ọ́ pé ò ń fi owó Yahoo Yahoo ran ara oun lọ́wọ́ nílé ìwé.

"Bí Ọlọ́run bá gbọ́ àdúrà mi, tí mo parí iléèwè, tí mo rí iṣẹ́ gidi, ... Kii ṣe nkan ti mo fẹ gbe gbogbo aye mi le lori".

Ko da o tun mẹnu ba a pe awọn to n ṣe pasiparọ owo ilẹ okere gan n ba awọn ṣiṣẹ.

Iroyin ti wa ko to kẹẹ wo fọnran naa funra yin.