Food Poison: Oúnjẹ márùn-ún tó lè ṣekú pa'ni kíákíá

Ounjẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Gẹ́gẹ́ bí àwọn mìíran ṣe máa n dáṣà pé gbogbo ejò jíjẹ ni, ṣùgbọ́n ìwádìí ti fi hàn pé ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀, àti pé kò si òunjẹ ti kò léwu ti à o bá ṣètò rẹ̀ dáradára.

Ọ̀pọ̀ oúnjẹ lo le sàkóbá fún ara wa ti a kò bá ṣe aáyan rẹ̀ bó ti tọ àti bo ti yẹ. Yíyọ àwọn ǹkan tó le ṣe àkobá fún ara kúrò ṣe pàtàkì nítorí kìí ṣe òunjẹ ọhun gan ni kò dára bi ko ṣe awọn èròjà kan lára rẹ̀.

Àkọlé fídíò, 'Buns ni ọmọ mi jẹ tán ní ṣọ́ọ̀ṣì, ló bá di àwátì'

Tí a ò bá gbé ìgbésẹ̀ yìí ọ̀pọ̀ ounjẹ lo le di ààrun, májèlé tàbi kó já si ikú, nígbà mira a maa pa ọpọlọ lára.

Àwọ́n oúnjẹ márùn-ún tí ẹ gbọdọ yẹwò dáradára ki ẹ tó jẹ

1. Ẹ̀wà Soya ( Soya Beans)

Soya beans

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Gbogbo ènìyàn ló gba pé òunjẹ to dára ni ẹwà jẹ́ sùgbọ́n ọkàn wá ti ènìyàn ko ba sọ́ra ó le di àìsàn si ni lára.

Ẹ̀wà pupa àti soya beans ọmọ iyá kan náà ni wọ́n.

Ní apá kan wọn ni èròja afúni lẹ́jẹ̀ (protein) àti àwọn fitámìn, ẹ̀wẹ̀, ẹ̀wá ní epo kan ti wọ́n ń pè ni Phytohaemagglutinin ti ẹ̀ya ará ènìyàn ko lágbára lorí rẹ̀.

Tí ènìyàn bá jẹ ẹ jù, o lé fa inú rírùn àti ati inira.

Sùgbọ́n ayọ to wà nibẹ ni pé tí ènìyàn bá ṣee ko pẹ́ lóri iná ó máa n mú àdínkù ba ewu to wà nibẹ̀.

Bákan náà lo ni Trypsin, eyi a si maa ṣàkóba fun ǹkan to n mú ounjẹ da lára.

Sùgbọ́n oo, ti a ba le rẹ ẹ somi fún bii wákàti mejila kó to di sísè, àwọn kẹmika ara rẹ yóò pòórá.

2. Ẹja Puffer

Puffer Fish

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Eyií jẹ ẹja ti wan maa ń lo bi ìpanu ní ilẹ̀ Japan

Ẹja Puffer yiìí dàbí Májèlé, ó sì le pànìyàn.

Ẹja náà ni ǹkan ti wọ́n ń pe ni 'tetrodotoxin' eyí ti oró rẹ̀ ju ti májàlé lọ.

Bí ẹja yìí ṣe wá ni oró to ó sì jẹ́ ǹkan to wọ́pọ̀ ní àwọn orílẹ̀-èdè míràn.

Ní Japan ẹjá ti wọn máa n pe ni Fugu, wọn máá n jẹ ẹ ni tútú tàbi kí wọn dín ata si i.

Ọ̀pọ̀ àwọn àlásè máa ń gba ẹkọ fún ọ̀pọ ọdún ki wọn to le gbà wọ́n láàyè láti ṣe irú ẹja bẹ́ẹ̀.

O ṣe pàtàkì kí ènìyàn yọ gbogbo ibi ti ẹjẹ le di si, àwọn ẹyà ara bii ọpọlọ, awọ, ojú àti ikùn rẹ̀ ki ènìyàn to bẹ̀rẹ si ni jẹ ẹ.

Eja

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ọ̀pọ̀ àwọn alase lo maa n gba ẹkọ fun ọpọọdun ki wan to lasẹ láti se ẹja náà

3. Casuwi Csu Marzu

Ǹkan to mú ounjẹ èyí yàtọ ni pe ó dàbi aràn.

Eyi ṣe bi ẹni rini lára díẹ̀ sùgbọ́n àwọn ara Sardinia ni Italy nifẹ òun náà gidigidi.

Wọn a maa fi ẹ̀pa lílọ àti ata dindin, díẹ̀díẹ̀ yóò maa yọ yoo si di omí si inú abọ.

Sùgbọ́n ki ènìyàn to jẹ irú ounjẹ yìí, àwọn ìgbẹ́sẹ̀ kan se pàtàkì.

Ní àkọkọ, o gbọ̀dọ kó àwọn aran náà nítori o le fo ibuso mẹẹdogun lẹ́ẹ̀kan náà.

Caswu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Orisirisi ni bo se maa n ri lẹnu

Ikeji ni pé ó sòro láti rí, àjọ EU ko si fi ààye gbàá nítori náà kó ṣe tà si orilẹ̀-èdè míràn

Ikẹta ni pe wọ́n ti sàpejuwe rẹ bíi ọkàn lára àwọn ounjẹ to léwu jùlọ lágbàyé nítori pé o lé ni ààbọ lori iléra ẹni to ba n jẹ ẹ.

Caswu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, O jẹ okan lara ounjẹto lewu julọ lagbaye

4. Ewé Rhubarb

Ewé yìí wọ́pọ̀ láàrin àwọn ara ilẹ Gẹẹsì ti wọn maa n fi pètò ounjẹ, ọ̀pọ òunjẹ nilẹ gẹẹsi ni ewé náà wà nínú rẹ̀.

Ewe Rhubarb

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Opo òunjé ilẹ̀ Gẹẹsi lo ni ewé yìí nínú

Enìyàn ni lati sọ́ra nítori pé èyí to jẹ aláwọ ewé rẹ̀ léwu gidigidi o sì ni májèlé nínú.

Ǹkan to wà níbẹ ni pé o ni májèlé ni wan n pè ni Oxalic acid, ti ènìyàn ba wá n fi gbogbo igbe jẹ, a maa ṣeni bi èèbi osí le fá okúta ninú kídìnrín.

Ẹ̀we, ewu yiì ti di ọ̀rọ̀ ti wọ́n ń fà nitori pe asíídìì to wà nínú rẹ̀ ga púpọ̀.

Ti ènìyàn bá n jẹ ẹ púpọ̀ o le ṣe ikú pa ẹni náà, ó sàn ki ènìyàn má jẹe rárá.

5. Gaya Melon

Gaya Melon

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, O le fa ikú ti ènìyàn ba n jẹ ni gbogbo igbà

Èyí dàbi bara ègúsí ti a ri ni orílẹ̀-èdè Indonesia.

O ṣe pataki láti fi ṣe awọn ounjẹ bii bisikiti àti wàra, àwọn nkan ti wọn tún fi n se ni láti din ata si oduku, ẹràn tabi láti fi ṣe ọbẹ.

Ṣùgbọ́n ti ènìyàn bá jẹ ẹ jù ó ma ń ṣokunfa ǹkan to pọ̀: o maa n gbéni léèbì, kìí jẹ kí ènìyàn le mi dáada, o tun máa n jẹ ki ènìyàn ní janin-janin.

Bótilẹ̀ jẹ́ pé kò wọ́pọ̀ ṣùgbọ́n ti ènìyàn ba jẹ Nutmeg púpọ o le ja si ikú.

Kí wa ni idí ti ènìyàn yóò fi ma kó òòrun didun si inu ounjẹ púpọ lásiko kan náà?