#6thAFRIMA: Burnaboy, 2baba, tiwa Savage àti Wizkid da ilẹ̀ rú ní AFRIMA

Stonebwoy, Tiwa Savage ati Burna boy

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Stonebwoy, Tiwa Savage ati Burna boy

Lẹyin ti wọn fi orukọ rẹ silẹ fun ami ẹyẹ Grammy, Burna Boy ti gba ami ẹyẹ AFRIMA.

Amọṣa, oun nikan kọ ni akọrin orilẹede Naijiria to tan bi itanṣan oorun nibi eto ami ẹyẹ fun awọn olorin to lamilaaka nilẹ Afirika naa.

Wizkid, Tiwa Savage, Joeboy ati DJ Spinall pẹlu gba ami ẹyẹ nibi eto naa to waye ni ọjọ Aiku ni ilu Eko.

Àkọlé fídíò, Ẹ̀mí kan náà ló n darí ìrìnàjò wa táa fi jọ kọ́lé papọ̀- Ìbejì
Burna boy

Oríṣun àwòrán, @burnaboy

Awo orin Burna Boy to pe akọle rẹ ni 'African giant' lo gba gba ami ẹyẹ fun awo orin to gbamuṣe ju lọ lọdun yii. Bakan naa lo gba ami ẹyẹ akọrin to gbamuṣe ju lọ lọkunrin ni ẹkun iwọ oorun Afirika fun orin rẹ ti akọle rẹ jẹ 'Ye' nigba ti orin Wizkid, ti oun pẹlu jẹ akọrin ọmọ Naijiria pẹlu gba ami ẹyẹ orin to gbayii ju lọ lọdun yii lori orin rẹ to pe akori rẹ ni 'Fever' ti oun pẹlu Tiwa Savage jumọ pa itu meje ninu rẹ.

Awọn akọrin Naijiria to tun gba ami ẹyẹ nibi ayẹyẹ AFRIMA tọdun yii ni Tiwa Savage to gba ami ẹyẹ akọrin to gbayi ju lọ lobinrin ni ẹkun iwọ orun Afirika lori orin to pe akori rẹ ni 'One', Joeboy gba ami ẹyẹ ẹgbẹ alakọrin meji (Duo) to pegede julọ ti DJ Spinnal si gba ami ẹyẹ DJ to gbayii ju lọ ni gbogbo ilẹ Afirika.

Àkọlé fídíò, 'Àfi bí mo bá sunkún mọ́ títọrọ̀ owó, tórí gbobo wa ni ìyà ń jẹ níbí'

Awọn oloriire miiran nibi ami ẹyẹ naa ni: