Osun cow death: Iṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé kò ni dá wàhálà sílẹ̀ láàrin àwa àti àwọn Fulani.

Oba Okunoye

Oríṣun àwòrán, Okunoye facebook

Àkọlé àwòrán, Àmúwá Ọlọ́run lásán ní ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé ní Iba-Eburu Iba Oba Okunoye

Ọba Eburù ti Iba ọba Adekunle Okunoye, ti fi ìdí ìṣẹ̀lẹ̀ to wáyé ni Iba múlẹ̀ nípa àwọn màálù Fulani to n gbé inú ìlú náà.

" Àwọn ènìyàn Iba tí ń ba àwọn Fulani gbé láti ọ̀pslọpọ̀ ọdún sẹ́yìn nínú ayọ àti aláfíà, ǹkan tó si sẹlẹ̀ yìí kò ni mú ipinya wáyé láàrin àrá ìlú àti àwọn Fulani."

Ikú àwọn màálú tó jẹ́ ti Fulani to n gbé inú ilú Iba kò mú idí kankan dáni ju pé amúwá ọlọrun ni lọ, eyi wáye látàrí àrá tó sán nínú ìlú náà to si pa àwọn màálú náà. O fi kún pé, àti ilú àti àwọn fulani sa gbogbo ipá wọ́n la'ti dẹ́kun irú ìṣẹ̀lẹ̀ báyìí lọ́ja iwájú.

"Awọn ọmọ ìgbìmọ Eburu ti sọ fún ẹni to ni màálù náà láti lọ sún àwọn màálù náà ko ma ba fa àjàkálẹ̀ ààrùn.

Igbé ayé aláfia ni à n gbé pẹ̀lú gbogbo àwọn ajoji to wà ni inú ìlú wa tó fi ma àwọn Fulani"

Osun cow death: Gómìnà Oyetola ṣèlérí àtìlẹyìn ìjọba fáwọn Fúlàní tó pàdánù màlúù l'Osun

Maalu

Oríṣun àwòrán, Premium times

Gomina ipinlẹ Ọṣun Gboyega Oyetọla ti ba awọn eeyan ilu Iba kẹdun lori iṣẹlẹ ara to san pa awọn maluu ti ko din ni mẹtadinlogun to jẹ tawọn darandaran Fulani nibẹ.

Gomina Oyetọla ni iroyin pe alaafia ni ibagbeps awọn eeyan ilu naa pẹlu awọn darandaran fulani nibẹ jẹ idunnu fun ohun gẹgẹ bii iṣẹlẹ naa tun ṣe jẹ ibanujẹ ọkan fun oun.

Gomina ipinlẹ Ọṣun ti amugbalẹgbẹ rẹ lori ọrọ ọgbin ati ipese ounjẹ, Ọgbẹni Biọdun Ajiṣefini ṣoju fun ṣalaye lasiko abẹwo rẹ si ilu Iba pe 'ara wa lawọn eeyan ti adanu nla yii ṣẹ, wọn kii ṣe ajeji"

Àkọlé fídíò, 'Àfi bí mo bá sunkún mọ́ títọrọ̀ owó, tórí gbobo wa ni ìyà ń jẹ níbí'

O fi atilẹyin ijsba ipinlẹ Ọṣun da wọn loju ninu adanu wọn naa bi o tilẹ jẹ pe ko sọ ni pato ọna ti atilẹyin naa yoo gba.

Fún ìgbà kẹ́ta láàrín oṣù mẹ́ta, àrá tún sán pa àwọn màlúù Fúlàní.

Bi ẹ ko ba gba gbagbe, Ko din ni maluu mẹtadinlogun ti ara san pa ni ileto kan ti wọn n pe ni Iba ni ijọba ibilẹ Ifẹlodun ni ipinlẹ Ọṣun.

Agbegbe kan ti wọn n pe ni Gaa Eleesun nibi ti awọn darandaran Fulani n gbe ni iṣẹlẹ yii ti waye ni irọlẹ ọjọ Ẹti lẹyin ti awọn darandaran naa ti papa ijẹko de lati sinmi fun iṣẹ ọjọ naa gẹgẹ bi a ṣe gbọ.

Iroyin sọ pe, iṣẹlẹ yii ti sọ gbogbo awọn olugbe ilu Iba sinu hilahilo bayii nitori irufẹ iṣẹlẹ naa ko waye ri ati pe alaafia ni awọn olugbe ilu naa atawọn darandaran Fulani n gbe nibẹ.

Ọgbẹni Jimoh Sọliu to jẹ olori gaa Eleesun ṣalaye pe ọfọ nla ni iku awọn maluu ati aguntan naa jẹ fun wọn. O ni ere tete ni gbogbo wọn sa wọle nigba ti ara naa san, iyalẹnu nla lo si jẹ lati rii pe ara naa ti pa awọn maluu ati aguntan naa.

Eyi ni igba kẹta ti iṣẹlẹ ajalu ara sisan pa awọn maluu yoo maa waye laarin oṣu mẹta.

Àkọlé fídíò, Mo fi iṣẹ́ Banki silẹ̀ lọ bẹ̀rẹ̀ alápatà - Derin

Bi ẹ ko ba gbagbe, maluu mẹrindinlogoji ni ara kọkọ san pa ni ilu Ijarẹ ni ipinlẹ Ondo lẹyin ti awọn adari ilu naa ni ori ilẹ aiwọ ni wọn ti ri awọn maluu naa ati pe titasẹ agẹrẹ wọn lo ṣokunfa iṣẹlẹ naa. Ìlú kò mọ ohunkóhun nípa iṣẹlẹ màálù tó kú nilu Ikarẹ- Oba Olukarẹ

Ko pẹ pupọ lẹyin eyi ni ara tun san pa maluu bii mẹjọ kan ni agbegbe Oyinmọ ni ilu Ikarẹ ni ijọba ibilẹ Akoko North east ni ipinlẹ Ondo kan naa.