Ọọ̀ni: Àwọn ọ̀daràn Fulani fẹ́ ba orúkọ rere Nàíjíríà jẹ́ ni

Oba Adeyeye Ogunwusi ati Emir ti Borgu

Oríṣun àwòrán, Oba Adeyeye Ogunwusi

Awọn ọba alaye lorilẹede Naijiria ti n wa ọna ti wọn yoo fi le eyikeyi ọdaran laarin awọn Fulani to wa nidi ọpọ iwa aifararọ eto aabo nilẹ Yoruba atawọn apa ibomiran lorilẹede yii tefetefe si ayika wa.

Arole Oodua, tii tun se Ọọni ti Ile Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ẹnitan Ogunwusi, Ọjaja Keji, lo fọwọ idaniloju yii sọya, lasikoto n ki Emir ti Borgu, Alhaji Muhammed Haliru Dantoro, Kitoro Kẹrin, kaabọ̀ si aafin rẹ.

Ọọni, ẹni to koro oju si iwa ipaniyan to n gogo lasiko yii, iwa jiji maalu ko, atawọn iwa to nii se pẹlu iwa ọdaran lorilẹede yii, paapa nilẹ Yoruba, tun salaye pe, awọn janduku apanijaye ẹda yii lo ni afojusun lati ta abawọn si orukọ rere orilẹede Naijiria.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

"Gbogbo wa la n lọgun pe awọn Fulani lo n yọ agbegbe wa lẹnu, sugbọn kii se gbogbo Fulani rara, awọn kanda kan ninu irẹsi to wa laarin wọn ni, awọn si la fẹ le jinna si sakani wa, ta si ri daju pe alaafia ati idajọ ododo jọba ni Naijiria."

Oba Adeyeye Ogunwusi ati Emir ti Borgu

Oríṣun àwòrán, Oba Adeyeye Ogunwusi

Ọba Ogunwusi fikun pe, awọn isẹlẹ kayeefi to n waye lẹnu lọọlọ yii nilẹ Yoruba jẹ ajeji si wa, a si gbọdọ sisẹ tọ ọna lati lati mu ki alaafia jọba lawujọ wa, awọn eeyan ko gbọdọ maa gbe ninu ibẹru bojo ati ifoya sugbọn wọn gbọdọ ni ominira lati ls si ibi to ba wu wọn.

Oba Adeyeye Ogunwusi ati Emir ti Borgu

Oríṣun àwòrán, Oba Adeyeye Ogunwusi

Nigba to n se ago laafin si Ọọni, Emir ti Borgu safihan imọriri rẹ fun Ọọni ati awọn ọmọ igbimọ rẹ, to si kede pe awọn ọba alaye gbọdọ wa ni isọkan fun irẹpọ orilẹede yii.

Àkọlé fídíò, Orúkọ ọmọ ni Yorùbá gbà pé ó máa ń ro ọmọ nílẹ̀ Oodua