DR Congo: Ọ̀pọ̀ ẹmí lo ti sọ́nù ninú ìjàmbá ọkọ̀ òfurufú tó wáyé lóòní

Oríṣun àwòrán, Reuters
O kéré tan ènìyàn mẹ́tàdinlógójì ló ti jẹ́ Ọlọrun nípe lónìí nígba ti ọkọ̀ ofúrúfú kan já ni ilú Goma ni ilà-òòrun DR Congo gẹ́gẹ́ bi àwọn aláṣẹ́ ṣe sọ.
Àwọn ti iṣẹ́lẹ̀ ajálù náà kàn jùlọ ni àwọn mẹ́sàn nínú ìdílé kan ti gbogbo wọ́n kú ni àgbègbè Mapendo.
Ọkọ̀ òfurufú kékeré òun lo dédé já lulẹ ni kété to gbéra ni pápákọ̀ òfurufú ni owúrọ ọjọ aikú, ìdí ti ọkọ náà fi já lulẹ̀ kò ti yẹ ẹnikẹni titi di àsìkò yìí.
Eniyan mẹtadínlógun ní lo wà nínú ọkọ ofurufu náà
Kìí ṣe ìgbà àkọkọ rèé ti irú ǹkan bayìí yóò ṣẹlẹ̀ ni orílẹ̀-èdè DR Congo ní tori ètò ààbo tó wà nibẹ̀ kò gbópọ̀n tó àti pé ìtójú ti wọ́n ń ṣe fún àwọn ọkọ ofurufú naa kéré jọjọ. Eyí sì ló sokùnfa ìdí ti gbogbo àwọn orilẹ̀-èdè fi ni ki wọ́n maa wọ orílẹ̀-èdè àwọn mọ, pàápàá jùlọ ni àwọn ilẹ òkere alawọ funfun.
Nkan tí a mọ nípa iṣẹ̀lẹ̀ náà
Dornier-228 twin-turboprop ti ilé iṣẹ́ aládani kan Busy Bee ra ló dédé já lẹ́yìn ìṣẹ́jú kan to gbéra , èyí jẹ́ ǹkan ti ẹnikan sọ fun BBC ni pápákọ ofúrúfú Goma.
Bàálú náà yẹ ko kó èrò lọ sí Beni to jẹ kilomita ààdọtadinirinwo tó n lọ sí ìhà àríwá Goma.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Nkan to fa idi abájọ ko tii dájú títí di àsìkò yìí, sùgbọ́n àwọn kan sọ pé ẹnjini bàálù ló ni isoro ni kéte to gbéra, eyi ni akoroyin BBc Emery Makumeno sọ pe ẹnikan sọ ni Kinshasha.
Kété ni àwọn òṣìṣẹ́ pajáwìrì bọ sibẹ̀ láti gbé awọn ènìyàn to fara pa ti wọ́n sí gbé àwọn to ti kú náà kúrò.
Kó ti dáju iye ènìyàn to wà ninú ilé ti bàálù naa jálù
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post

Gómìnà Kasivita fidi rẹ̀ múlẹ̀ pé "ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ti gba ẹmi àwọn ará ilú wa" bẹ́ẹ̀ lo fi ọ̀rs ìyànjú ránṣẹ́ si àwọn ẹbi ti àjálù náà dé bá àti awọn to farapa.
Ilé Iṣẹ́ BBC ti kan si Busy Bee fun ọ̀rọ̀ lẹnu wọ́n














