Babcock Sex video: Ohun tó yẹ kóo mọ̀ nípa Fásitì Babcock

Oríṣun àwòrán, Image copyright@BABCOCK_UNIV TWITTER
Ọkan lara awọn ileewe giga amoke ni Naijiria ni Fasiti Babcock eyi to ti wa lati ọdun 1999.
Bi ẹ ko ba gbagbe, lọjọru ọsẹ to kogba wọle ni fasiti naa jawe maa lọle fun akẹkbinrin kan to wa ninu fidio ibalopọ kan to tan kaakiri ayelujara.
Ninu ọrọ akọsilẹ ti fasiti naa fi ṣọwọ ileeṣẹ BBC, agbẹnusọ wọn, Joshua Suleiman ni iṣẹlẹ naa ti ṣ latinu oṣu kẹrin ti kii sii ṣe inu ọgba ileewe lo ti ṣẹlẹ.
Ninu oṣu keji dun ni wọn le ọmọkunrin to wa ninu fidio naa danu tefe tefe lẹyin ti iwadi fi han wọn pe o lọwọ ninu awọn iwa wuru wuru ti ile iwe ko fọwọ si.
Bi ileewe kan ba ti se ofin pe awọn nkankan wa ti awọn ko fọwọ si, akẹkọọ to ba n kawe nibẹ ko gbudọ jẹ arufin.
Ni Babcock, awọn ohun to yẹ kẹẹ mọ niyii

Oríṣun àwòrán, Image copyright@BABCOCK_UNIV TWITTER
Gbogbo akoko isinmi ni wọn maa n mu ni pataki.
Ijọ Seventh-Day Adventist lo da fasiti naa silẹ̀ bẹẹ si ni gẹgẹ bi ọkan lara afihan iru igbagbọ wọn pe ki wọn ya ọjọ isinmi si mimọ eyi to maa n bẹrẹ lọsan ọjọ ẹti ti yoo si pari lọsan ọjọ abamẹta.
Ẹṣẹ ni aṣọ to n fi ara han ati sikẹẹti lọntínrín
Wọn ko faaye gba akẹkọ lati wọn awọn sikẹẹti to lẹ mọ ni lara pẹki pẹki tabi aṣọ to ba n ṣi ara silẹ. Ileewe ka eyi si ọna ati fi ilọkulọ ibalopọ lọ eeyan.
Oo le maa rin regberegbe iri pẹlu akọ kaakiri tabi ki obinri ṣe idakeji rẹ lasiko ti ko tun tọ - Ọrọ wahala nla ni o.
Ẹ o le wọ aṣọ olowu Jeans yala ẹwu tabi ṣokoto ninu ileewe to fi mọ ṣokoto abẹnuṣọọrọ.
Bakan naa, ẹwu tabi sikẹẹti to ba soke lori orokun kii ṣe ohun ti wọn gba laye ayafi ki sikẹẹti skale si abẹ orokun daadaa.
Ofin lodi si ẹgba ọwọ ati tọrun
Irufin ni lati wọ yẹrin eti, ti imu, ahọn, idodo, aya ati ẹgba ọrun.
Koda gbigbe irun to jọ ti were sori naa kọwọrin pẹlu awọn eleyii labẹ ofin ileewe.
Akẹkọ ko le se ounjẹ tabi ẹran jẹ
Sise irufẹ ounjẹ ninu yara awọn akẹkọ ko mu u rara o. Koda kẹẹ kan fẹ din tabi bọ ẹran ranpẹ jẹ ko ri aye.












