Babcock Sex Video: Láti ìgbà tí fásitì ti lé àkẹ́kọ̀ọ́ náà ló ti dùbúlẹ̀ àìsàn amọ́ ara rẹ́ ti dá

Akekọọ

Oríṣun àwòrán, Babcock/Twitter

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Arabinrin akẹkọọ fasiti Babcock ti fidio ibalopọ rẹ pẹlu ọrẹkunrin rẹ lu sori ayelujara ni ọdun sẹyin yoo lọ kawe si ileẹkọ fasiti loke okun.

Eyi ko ṣẹyin bi ileewe giga fasiti kan ni oke okun, ṣe fun arabinrin naa ni anfaani lati kawe lai san owo ileewe.

Dokita Ola Bukola to tun jẹ oluranlọwọ rẹ ni Niajiria, lo kede bẹẹ loju opo Twitter rẹ pẹlu afikun bukata ẹkọ rẹ naa ni oke okun ti gbe.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Arabinrin naa ni Fasiti Babcock fi ọwọ oṣi juwe ile fun, nitori fọnran kan to lu ayelujara pa, nibi ti ọkunrin kan ti n ba lopọ.

Dokita Bukola ni lati igba ti iṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ ni arabinrin naa ti n gba iwosan.

Nibayii, Dokita naa ni saka ni ara rẹ da, ti o si tun ṣe daadaa ninu gbogbo idanwo ti o ṣe.

Dokita Brown ni afojusun oun fun arabinrin naa ni ki o yege, ki o si di ẹni nla ni awujọ lọjọ iwaju.

Iwe ti Babcock fi le akẹkọọ sita

Oríṣun àwòrán, Babcock

O ti kọkọ fi lede ni Osu Kẹfa wi pe gbogbo eto ti n to lati ri wi pe arabinrin naa lọ si ileewe giga lai si idẹyẹsi fun wọn.

Nigba naa, o ni aye arabinrin naa ti yipada si rere lati igba ti wọn ti le kuro ni ileewe, to si yege ni ẹkọ rẹ ati ihuwasi rẹ.

Ọpọ ọmọ Naijiria lo tako igbesẹ fasiti Babcock nigba naa, lori bi wọn ṣe fi ọwọ osi juwe ile fun akẹkọbinrin naa ti wọn n ba lopọ ninu fidio to lu ori ayelujara pa.

Fásítì Babcock lé akẹ́kọ̀ọ́bìnrin tó hàn nínú fídíò ìbálòpọ̀ lọ sílé

Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe fasiti Babcock ti fọwọ oṣi juwe ile fun akẹkọọbinrin to wa ninu fọnran to lu ayelujara pa, nibi ti ọkunrin ati obinrin kan ti ni ibalopọ.

Fasiti Babcock

Oríṣun àwòrán, Faceboo/Babcock University

Àkọlé àwòrán, Agbẹnusọ fun ile iwe Babcock to ba BBC sọrọ ṣalaye pe oṣu kẹrin ọdun yii awọn mejeeji ni ibalopọ ṣugbọn kii ṣe ninu ọgba ile iwe naa.

Agbẹnusọ fun ile iwe naa to ba BBC sọrọ ṣalaye pe, oṣu kẹrin ọdun yii awọn mejeeji ni ibalopọ ṣugbọn kii ṣe ninu ọgba ile iwe naa.

Ninu oṣu keji ọdun yii ni ile iwe naa kọkọ le ọkunrin to wa ninu fọnran lọ ile, lẹyin ti wọn fẹsun kan an pe o wu iwa to tapa sofin fasiti naa.

Obinrin to wa ninu fidio yii jẹ akẹkọọ ọlọdun kẹta ni ẹka ẹkọ imọ nipa iṣiro owo, Accountancy, ki wọn to sọ fun un pe ko lọ gbele ẹ.

Fasiti Babcock ni ọmọkunrin to ba ọ́kẹkọbinrin naa lopọ wa ni ile iwosan kan to ti n gba itọju nitori ogun oloro mimu, nibi ti akẹkọọ binrin naa ti lọ ba.

Atẹjade ti fasiti ọhun fi sita tun ṣalaye pe, nigba ti ile iwe naa wa ni isinmi ni akẹkọọbinrin naa lọ ba a nibẹ.