SARS Operation in Nigeria: Òṣèré tíátà ń fẹ́ kíjọba pa ẹ̀ka ọlọ́pàá tó ń gbógun ti ìdigunjalè jẹ́

Oríṣun àwòrán, Instagram/dayoamusa
Gbajugbaja oṣere-binrin, Dayo Amusa, ti pe fun fifi òpin si ẹka ọlọpaa to n gbogun ti idigunjale, SARS.
Eyi waye lẹyin ti fidio kan to ṣafihan àwọn ọlọpaa kan tó yinbọn si ọkunrin kan ati idile rẹ, gba ori ayelujara.
Ninu fidio naa, ọlọpaa kan gbé ìbọn lọwọ, ti awọn ọkunrin melo kan ti wọn jọ n ṣe ariyanjiyan si di i mu.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ayẹyẹ ìgbaniwọlé sínú ẹgbẹ́ òkùnkùn bẹ́yìn yọ, wọ́n lu ọmọ ẹgbẹ́ tuntun pa
- Akeredolu yan ọmọ Ilajẹ gẹ́gẹ́ bíi igbákejì rẹ̀ tí wọ́n yóò jọ díje dupò ní Ondo
- Ìjọba àpapọ̀ ti gba 800 bílíọ̀nù padà lọ́wọ́ àwọn tó jí owó ìlú kó, àwọn 1,400 ti wà nínú ẹ̀wọ̀n -Lai Mohammed
- Toke Makinwa ti sọ̀rọ̀; Amcon náà dá a padà fún un pé...
- Ọwọ́ tẹ́ àwọn ọkùnrin Fulani mẹ́ta tí wọ́n jí Màálù méjì kó ní Ogbomọṣọ- Àjọ NSCDC
- Ọmọ́ Yorùbá korò ojú sí Buhari bí kò ṣe fi orúkọ Obasanjo sọ ibùdókọ̀ ojú'rin
- Ọ̀nà tó fi le è mọ gbájúẹ̀ babaláwo - Ẹlẹ́buìbọn
Bo tilẹ jẹ pe nnkan to fa ariyan-jiyan naa ko han si wa, amọ o foju han pe ìbọn ba ọ̀kan lara awọn ọmọde to wa ninu ọkọ ayọkẹlẹ naa, ti awọn ọlọpaa SARS da duro.
Ariwo ẹ ma a gbe lọ sile iwosan lo gba inu fidio naa, ti obìnrin kan to ṣe e ṣe ko jẹ iya ọmọ naa, si n sunkun.
Ọpọ ọmọ Naijiria lo ti bu ẹnu ẹtẹ lu ileesẹ ọlọpaa, nitori fidio naa.
Dayo Amusa ninu fidio to gbe sita naa sọ pe, o ti di iwa ọdaran ni orilẹ-ede Naijiria lati se irun atọwọda Dàda sórí.
Bakan naa lo ni níní tabi gbigbe kọmputa agbeletan (laptop) dani, ati wiwọ aṣọ to ba igba mu, ti di ọ̀ran nla bayii nilẹ wa.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 1
"Awọn ọlọpaa to yẹ ko ma a ṣọ ẹ̀mí ati dukia wa, ti di ẹni to n yinbọn mọ àwọn ọdọ wa, ti wọn si n pa wọn bo ṣe wu wọn, nitori pe wọn ro pe gbajuẹ ni wọn.
Ki wọn ti ẹ jẹ gbajuẹ, ṣe bi ẹ le mu wọn lọ si agọ ọlọpaa..."
Amusa wa n beere pe "ṣe bi a o ṣe ma a ba lọ ni yii?"
Lati bi ọdun diẹ ni ọpọ ọmọ Naijiria ti n polongo pe, ki ijọba o fi opin si ẹka ọlọpaa SARS, nitori awọn iwakiwa to kun ọwọ wọn.
N kò lóyún, bẹ́ẹ̀ ni ń kò ní ọkọ, ẹ fi mí lọ́rùn sílẹ̀ - Dayo Amusa
Ifẹ afẹju lo maa n mu iwọ lo n se mi wa, ti ifẹ ba si ju bo se yẹ lọ, o lee fa ija.
Bi ọrọ se ri ree pẹlu ilumọọka osere tiata lobinrin kan, Dayọ Amusa, ẹni to figbe ta loju opo Instagram rẹ pe ki awọn ololufẹ oun jọwọ dakun fi oun lọrun silẹ, nitori itara wọn nipa igbesi aye oun ti pọju.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 2
Dayọ ni oun fẹ gbe ni alaafia, ki wọn si ye wa eekanna mọ oun lọrun nitori pe oun ko tii ni ọkọ tabi di oyun sinu.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Amọ sa, o wa mọriri awsn ololufẹ rẹ ọhun fun ifẹ ti wọn ni si ati ireti ohun rere ti wọn fẹ nipa rẹ, sugbọn o wa rawọ ẹbẹ si wọn pe ki wọn jọwọ fi oun lọrun silẹ lati gbe igbe aye to wu oun.
Ni kete to fi iroyin naa soju opo Instagram rẹ naa lawọn ololufẹ rẹ yii ti bẹrẹ si ni fesi pada fun, ti wọn si n ki pe ohun to sọ dara ati pe Ọlọrun yoo gbọ adura rẹ.
Sugbọn ọkan ninu awọn ololufẹ rẹ yii, John Andrew, @johnandrew1bb, lasiko to n dahun si ohun ti Dayọ Amusa kọ naa lo ni yoo dara ki osere tiata lobinrin naa tete lọ segbeyawo, ko si ni oyun sinu, bẹẹ lo n bi Dayọ pe, se ko mọ bo se sanra to ni.

Oríṣun àwòrán, Instagram/dayoamusa
Andrew wa gba Dayọ nimọran pe yoo dara ko lọ jo diẹ. O ni se ni pata rẹ maa n tobi to inuwọ ọmọde, ti oun ko si ri Dayọ ri ko wọ pata G-String lati igba to ti n fi pata nla ya fọto.
- OPC, Miyetti Allah, agbófinró yóò wà nínú ìgbìmọ̀ aláàbò nílẹ̀ Yorùbá
- Orí mi wú pé àwọn àgbà ìjòyè kọ́wọ̀rín-ìn tẹ̀lé Olúbàdàn, ìjà parí - Makinde
- "A kò ní ra ọjà South Africa mọ́, á gbẹ̀san oró tí wọn ń dá wa - Ọmọ Nàíjíríà fárígá"
- A fẹ́ gba ₦1bn lọ́wọ́ ìjọba Eko pé ó dẹ́yẹ sí wa - 123 Ọlọ́kadà Jigawa
Ọrọ ti Andrew sọ yii lo fa ibinu awọn ololufẹ awọn ololufẹ Dayọ Amusa yọ, ti gbogbo wọn si n yọ suti ete si ọkunrin naa lara pe ko wii re rara, ti ọpọ wọn si n beere pe ki lo de ti awọn eeyan kii se bọwọ fun awọn gbajumọ lawujọ.
























